INEC gbé orúkọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú tí yóò díje ìbò gómìnà Osun jáde, PDP àti Labour kò sí níbẹ̀

Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun

Oríṣun àwòrán, ademola adeleke

Àkọlé àwòrán, Gomina Ademọla Adeleke ti ipinlẹ Ọṣun ti kuro lẹgbẹ PDP lati lọ ree dije lẹgbẹ oṣelu Accord.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ti kede orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ọṣun ti yoo waye loṣu kẹjọ ọdun yii.

Bakan naa ni INEC tun kede awọn oludije ẹgbẹ oṣelu kọọkan plẹlu.

Amọṣa orukọ ẹgbẹ oṣelu jankanjankan meji ko si ninu orukọ ẹgbẹ oṣelu ti INEC kede pe yoo kopa ninu eto idibo naa.

Gẹgẹbi atẹjade kan ti alukoro ajọ naa ni ipinlẹ Ọṣun, Musa Olurode fi sita, ẹgbẹ oṣelu mẹrinla ni ajọ INEC ti yẹwo finifini lati kopa ninu eto idibo naa.

Awọn ẹgbẹ oṣelu naa ni Accord, Action Alliance(AA), African Action Congress (AAC), African Democratic Congress (ADC), Action Democratic Party (ADP), All Progressives Grand Alliance (APGA), All Progressives Congress (APC), Allied Peoples Movement (APM), Action Peoples Party, Boot Party, New Nigeria Peoples Party, Peoples Redemption Party, Young Progressive Party, ati Zenith Labour Party.

Ẹgbẹ oṣelu People' s Democratic Party (PDP) ati Labour Party (LP) ni ko si lori iwe orukọ ti INEC fi sita naa.

Eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ọṣun yoo waye lọjọ karundinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2026 lati mọ boya gomina ipinlẹ Ọṣun Ademọla Adeleke yoo tẹsiwaju fun saa ọdun mẹrin miran tabi boya ẹlomiran ni yoo gba ijoko ile ijọba Abeere lọwọ rẹ.