Ohun táwọn oníṣẹ̀ṣe sọ fún àjọ INEC lórí ìdìbò àti pàtàkì ọdún Ọ̀ṣun Osogbo tí wọ́n fi yí ọjọ́ ìdìbò gómìnà padà

Àkọlé fídíò, Wo ohun táwọn oníṣẹ̀ṣe sọ fún àjọ INEC lórí ìdìbò àti pàtàkì ọdún Ọ̀ṣun Osogbo tí wọ́n fi yí ọjọ́ ìdìbò gómìnà padà
Ohun táwọn oníṣẹ̀ṣe sọ fún àjọ INEC lórí ìdìbò àti pàtàkì ọdún Ọ̀ṣun Osogbo tí wọ́n fi yí ọjọ́ ìdìbò gómìnà padà

Lọdun to kọja ni alaga INEC tẹlẹ, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu kede pe ogunjọ, oṣu Kẹfa ati ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo ipinlẹ Ekiti ati Osun yoo waye.

Amọṣa, Awọn ẹlẹṣin ibilẹ ẹka ti ipinlẹ Ọṣun ti ke si ajọ eleto idibo INEC lati sun ọjọ idibo sipo gomina ipinlẹ Ọṣun siwaju.

Ohun ti Araba ilu Osogbo, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbuibọn ṣ lalaye fun BBC News Yoruba ni pe, ọdun ọṣun Osogbo ti wa nilẹ ṣaaju ki wọn to kede idibo, nitori naa ibo ni yoo yẹba.

Bakan naa ni Dokita Oluṣeyi Atanda to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn ẹlẹsin ibilẹ ni ipinlẹ Ọṣun pẹlu ṣalaye pe awọn ti kan si gbogbo awọn to yẹ titi kan ajọ INEC lati wa nnkan ṣe sii.

Gẹgẹbi wọn ṣe sọọ si, ajọ INEC gbọ si wọn lẹnu to si ti kede isunsiwaju idibo naa pẹlu ọsẹ kan.