Ajínigbé kọlu ìpínlẹ̀ Oyo, jí èèyàn mẹ́rin gbé lójú ọ̀nà Igbeti sí Kishi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ti ji eeyan mẹrin gbe lọ loju ọna Igbeti si Kishi to wa lagbegbe Oke Ogun, nipinlẹ naa.
Alukoro ileeṣẹ naa ni ipinlẹ ọhun, Olayinka Ayanlade lo fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin niluu Ibadan.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, kọmiṣọna ọlọpaa ti dari DPO Kishi ati Igbeti ki wọn ran awọn akọṣẹmọṣẹ agbofinro lati tọpinpin awọn ajinigbe naa ni kankan.
O ni awọn ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ lati ṣawari awọn ti wọn ji gbe ati lati fi ṣikun ofin gbe gbogbo awọn ajinigbe naa.
Ninu ọrọ rẹ, o ni awọn ọlọpaa ti kan lu igbo to wa lagbegbe naa lati wa awọn ti wọn ji gbe.
Atẹjade ọhun sọ pe "Kọmiṣọna ọlọpaa ti dari DPO ilu Kishi ati Igbeti, pẹlu atilẹyin awọn akọṣẹmọṣẹ mii, lati ko awọn to yẹ lọ sibẹ ki wọn le ri daju pe wọn doola awọn ti wọn ji gbe ki ọwọ si tẹ awọn ajinigbe ọhun pẹlu."
Ayanlade ni awọn agbofinro ti n fi imu finlẹ lagbegbe naa lori iṣẹlẹ ọhun.
Lẹyin naa lo rọ awọn araalu ki wọn ṣe surru, ki wọn si ran ọlọpaa lọwọ pẹlu awọn iroyin to le ṣamọna bi ọwọ yoo ṣe tẹ awọn ajinigbe ọhun.
Ẹwẹ, kii ṣe igba akọkọ ti wọn yoo ji awọn eeyan gbe nipinlẹ Oyo, paapaa lagbegbe Oke Ogun lẹnu lọlọ yii ree.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro n gbiyanju, iṣẹlẹ ijinigbe ti di tọrọfọnkale lagbegbe naa.
Lara awọn ibomii ti ijinigbe ti n waye lemọlemọ ni Naijiria ni ipinlẹ Kwara, Kogi, Ondo ati pupọ awọn ipinlẹ ni ariwa Naijiria.


























