Ṣé ogun tí Amẹrika àti Israel ń bá Iran jà bá òfin mu?

Awọn eeyan n daro ni Iran lasiko eto isinkin ti ogun naa ṣokunfa

Oríṣun àwòrán, Amirhossein Khorgooei/ISNA/West Asia News Agency via Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn eeyan n daro ni Iran lasiko eto isinkin ti ogun naa ṣokunfa
    • Author, Luis Barrucho
    • Role, WSL Global Journalism
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọ araalu lo ti jade laye lẹyin ti Amẹrika ati Israel bẹrẹ si n ju ado oloro si Iran lati ọjọ Aiku.

Akọwe ajọ iṣọkan agbaye, António Guterres ti bu ẹnu atẹ lu ogun naa pẹlu imọran pe ki gbogbo igun to n ja ogun ọhun bọwọ fun ofin agbaye.

Amọ ṣa, igun mejeji to n ja ogun lo ti sọ pe awọn ko jẹbi, ṣugbọn lati fidi rẹ mulẹ boya ikọlu akọkọ si Iran ba ofin mu, a gbọdọ wo ofin agbaye ti ọpọ orilẹede tọwọ bọ lẹyin ogun agbaye keji.

Lẹyin ti Amẹrika ati Israel ju ado oloro si Iran lọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji, Aarẹ Donald Trump fẹsun kan Tehran pe o n ko ohun ija oloro pamọ, eyii to lewu fun Amẹrika atawọn orilẹede mii to n ba dọrẹ.

Amọ ṣa, akọwe ijọba Marco Rubio sọ lọjọ keji oṣu Kẹta pe Amẹrika ni lati lọ kogun ja Iran nitori awọn mọ pe Israel funra rẹ n mura lati kọlu Iran.

Asiko ti ijọba Iran n sin oku ọpọ eeyan lẹyin ti ado oloro Amẹrika ati Israel kọlu ile ẹkọ kan niluu Minab, ni Iran

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Asiko ti ijọba Iran n sin oku ọpọ eeyan lẹyin ti ado oloro Amẹrika ati Israel kọlu ile ẹkọ kan niluu Minab, ni Iran

Ẹwẹ, Aarẹ Israel, Isaac Herzog, sọ fun BBC pe igbiyanju Iran lati ṣeto ohun ija oloro nuclear ti to lati kọlu u.

Iran naa fesi pẹlu kikọlu awọn orilẹede mii lagbegbe rẹ ti awọn ologun Amẹrika wa.

Lọwọ yii, eeyan bii 780 lo jade laye ni Iran.

Ni apa keji, ọmọ ogun Amẹrika mẹfa lo ti jade laye.

Njẹ awọn ikọlu yii ba ofin mu?

Awọn amofin ti BBC ba sọrọ sọ pe gbedeke to yẹ ko waye ki Amẹrika ati Israel to ju ado oloro si Iran ko tii to, bẹẹ naa ni o ṣeeṣe ki Iran ti lu ofin agbaye bo ṣe da pada fun wọn.

Labẹ ofin agbaye, orilẹede kan ko lẹtọ lati kọlu orilẹede mii ayafi:

  • Abala 2{4} ofin naa: Ko faye gba idunkoko tabi lilo ipa pẹlu oriolẹede mii.
  • Abala 51 sọ pe: Wọn le da pada ti orilẹede kan ba kokọ kọlu wọn tabi ti wọn ba ri ikọlu to n bọ kankan.
Agbegbe ti ikọlu Israel ti ṣọṣẹ ni Lebanon

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Agbegbe ti ikọlu Israel ti ṣọṣẹ ni Lebanon

Ibere to ṣe pataki bayii ni pe ṣe ewu wa fun Amẹrika ati Israel lati ọwọ Iran lasiko yii.

Susan Breau to jẹ onimọ nipa ofin agbaye sọ orilẹede kan le daabo bo ara rẹ ti o ba ṣakiyesi ewu to n bọ lọna amọ oun ko ri ewu kankan lọwọ yi.

Sir Geoffrey Nice to jẹ ajafẹtọọmọniyan naa gba pẹlu amofin ọhun.

Nice sọ pe ko si ẹri kankan to n tumọ si pe o lodi si ofin bi Amẹrika ati Israel ṣe kọkọ kọlu Iran.

Nilẹ Amẹrika, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democrat nibẹ n sọ pe ko tọ bi Amẹrika ṣe bẹrẹ ogun naa nitori pe ile igbimọ aṣofin nikan lo le kede ibẹrẹ ogun nilẹ ọhun.

Amọ ṣa, Aarẹ Amẹrika, gẹgẹ bii adari ileeṣẹ ọmọ ogun le gbe awọn igbesẹ kan lai kọkọ gbaṣẹ lọwo ile aṣofin.

Ṣe ewu n bọ lati ọwọ Iran ṣaaju ibẹrẹ ogun naa?

Ile to n jo ni Bahrain lẹyin ti ado oloro Iran kọlu u

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Ile to n jo ni Bahrain lẹyin ti ado oloro Iran kọlu u

Aarẹ Trump ni Amẹrika ti gbiyanju lati jiroro pẹlu Iran ṣaaju amọ Tehran ko gbogbo anfani lati juwọ silẹ lori ohun ija oloro nuclear naa danu.

O ni Iran n gbiyanju lati kọ ohun elo nuclear to le rinrinajo de ibi ro jina ree bii ilẹ Amẹrika.

Amọ ninu oṣu Karun un ọdun 2025, ajọ US Defense Intelligence Agency (DIA) sọ pe yoo gba Iran ni ọpọ ọdun ko to le ṣe ohun ija nuclear ti yoo le rin jina rere de Amẹrika.

Awọn onimọ kan sọ pe ọrọ ti Trump sọ pe Israel ti ba ohun elo Iran jẹ lasiko ogun ọlọjọ mejila wọn lọdun to kọja tako ọrọ pe Iran jẹ ewu nla fun Amẹrika lasiko yii.

Eefin loju ọna ileeṣẹ ifọpo Ras Tanura, ni Saudi Arabia lẹyin ado oloro Iran lọjọ Aje

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Eefin loju ọna ileeṣẹ ifọpo Ras Tanura, ni Saudi Arabia lẹyin ado oloro Iran lọjọ Aje

Nnkankan to n fa ariyanjiyan lagbaye ni itumọ ewu 'to n bọ kankan.'

Marc Weller, onimọ ofin ni fasiti Cambridge sọ pe on tumọ si asiko kekere ti eeyan ni lati dena ikọlu ti yoo ṣẹlẹ si agbegbe rẹ.

Awọn ọkọ to n jo lẹyin ti Iran ju ado oloro so Tel Aviv, ni Israel

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Awọn ọkọ to n jo lẹyin ti Iran ju ado oloro so Tel Aviv, ni Israel

Ṣe esi Iran ba ofin mu?

Ọpọ awọn onimọ lo gbagbọ pe esi Iran si ikọlu Amẹrika ati Israel le ma ba ofin mu.

Wọn ni ko tọ bi Iran ṣe n sọ ado oloro lemọlemọ si awọn orilẹede Gulf to wa lagbegbe rẹ.

Sir Nice ni lootọ niṣe ni Iran n daabo bo ara rẹ, o ni o yẹ ki wọn ro ti awọn alaiṣẹ ti yoo faragba ninu ikọlu ti oun naa n ṣe.

Wọn ni irufẹ nnkan ti Amẹrika n kọlu, bii ileeṣẹ tabi ibudo ologun lo yẹ ki Iran naa kọlu, kii ṣe awọn ile tabi ibi ti awọn araalu ti ko ṣe n gbe bii ọja tabi awọn ibomii bii tirẹ.

Ewu n bẹm loko Longẹ

Iran: Eyii ni asiko ti awọn adoola ẹmi n yọ awọn eeyan ile ẹko to dawo lẹyin ado oloro Israle niluu Minab

Oríṣun àwòrán, West Asia News Agency via Reuters

Àkọlé àwòrán, Iran: Eyii ni asiko ti awọn adoola ẹmi n yọ awọn eeyan ile ẹko to dawo lẹyin ado oloro Israle niluu Minab

Awọn onimọ ti kilọ pe ewu n bẹ loko Longẹ ti awọn orilẹede ko ba tete ṣe iyatọ si igba ti wọn le koju ija orilẹede mii.

Wọn ni awọn orilẹede mii bii China le lo ipa pẹlu awọn orilẹede bii Taiwan to yapa kuro lara rẹ.

Alagba Rice ni ko si ohun to buru to ki awọn orilẹede fọwọ si lilo ipa pẹlu orilẹede mii lọna ti ko ba ofin mu.