Sex Tape: Small Doctor, Salawa Abeni, Toke Makinwa wà lára àwọn Gbajúmọ̀ tí fídíò ìbálòpọ̀ wọn ti bọ́ sí orí ayélujára ...

Tiwa Savage, Small Doctor and Salawa Abwni

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọpọlọpọ eniyan lo ti jade lati fi atilẹyin wọn han fun gbajugbaja olorin takasufe, Tiwa Savage ti fidio ibalopọ rẹ jade si ori ẹrọ ayelujara.

Oṣẹ to kọja ni Tiwa Savage fun ara rẹ fi lede pe ẹnikan n dunkoko mọ oun nitori o ni fidio ibalopọ oun lọwọ, to si n bere owo.

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'

Iṣẹlẹ yii ti mu ki ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ma a fi ero wọn han lori awọn gbajumọ lawujọ ti iroyin fidio ibalopọ wọn ti jade si ori ẹrọ ayelujara.

Small Doctor, Salawa Abeni, Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, Others

Lara awọn gbajugbaja ilumọọka miran ti aworan ihoho wọn ti bọ si ori ẹrọ ayelujara ni;Small Doctor, Salawa Abeni, Toke Makinwa ati awọn miran.

Salawu Abeni

Salawa Abeni

Oríṣun àwòrán, Instagram/@officialsalawaabeni

Osu Kẹrin, ọdun to kọja ni akọrin Waka lorilẹede Naijiria, Salawu Abeni fi lede pe ẹni kan n dun koko mọ oun lati fi aworan ihoho oun lede ti oun ko ba fun ni owo.

Loju opo Instagram rẹ lo ti fi atẹjade ti eni naa fi ranṣẹ si si oju ọpọ ayelujara fun ara rẹ.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ninu atẹjade naa lo ti fi lede pe oun ko ni jẹ ki ẹnikẹni dunkoko mọ oun.

Lẹyin naa ni ileeṣẹ ọlọpaa fi panpẹ ọba mu ẹni to n dunkoko mọ Salawu abẹni, ẹni ọdun mọkandinlogun.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi

Small Doctor

Small Doctor

Oríṣun àwòrán, Instagram/@smalldoctor

Ọdun 2017 ni fidio jade nibi ti gbajugbaja olorin takasufẹ ti n fi ọwọ kan ara rẹ ninu fidio ti wọn fi si ori Snapchat.

Amọ lẹyin naa ni iroyin jade pe awọn gbajuẹ ayelujara ni wọn gba ọna ẹburu lati wọ ori foonu rẹ, ti wọn si fi fidio naa lede.

Toke Makinwa

Toke Makinwa

Oríṣun àwòrán, Instagram/Toke Makinwa

Osu Kẹrin, ọdun 2020 ni gbajugbaja oniroyin, Toke Makinwa fi lede pe awọn kan ni ti oun ko ba san owo wọn yoo fi aworan ihọhọ rẹ si gbagba.

Lẹyin naa lo fi aworan ihoho ara rẹ si sita fun ara rẹ, to si ni pe ayederu ni eleyii ti o wa ni ọwọ ẹni to n dunkoko mọ wọn.

Tiwa Savage video: Iyabo Ojo àti àwọn gbajumọ míràn dá sí ọ̀rọ̀ sex tape Tiwá Savage wo òhun tí wọ́n sọ

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Instagram/Tiwa Savage

Ninu ọrọ tawọn eeyan n mu bẹnu loju opo ayelujara ni Naijiria, oke tente leleyi to ni ṣe pẹlu fidio ibalopo Tiwa Savage to lu sita wa.

Ọkẹ aimọye awọneeyan lo n wa fidio naa bi ẹni n wa owo ti awọn si n sọ iriwisi ọtọọtọ nipa rẹ.

Laipẹ yi ni akọrin takasufẹ naa pariwo sita pe eeyan kan fẹ fi fọnran yi gba owo lọwọ oun to si niboun ko ba san owo oun yoo lu sita.

Àkọlé fídíò, Irú omi àti oúnjẹ tí wọ́n ń fún Sunday Igboho, a ó mọ̀ọ́, à ń fura sí ohun tó ń lọ lọ́wọ́ látìmọ́lé Cotonou

Fidio naa ti wa lu sita bayi ti awọn gbajumọ ori ayelujara ati awọn mii si ti n sọ ero wn nipa rẹ.

Die ree ninu awọn to da si ọrọ yi ati nkan ti wn ni lati sọ.

Iyabo Ojo-Ko si ẹni ti ko lẹru lẹbọ, ko si giri

Gbajugbaja oṣere tiata Yoruba Iyabo Ojo wa lara awọn to ni ki Tiwa Savage ma ṣe foya lori fidio naa to lu sita.

Loju opo rẹ ni Instagram@iyaboojofespris, niṣe lo fi fidio orin Tiwa Savage kan sibẹ to si ni ko si ẹni ti kii gbẹsẹ, ki Tiwa Savage maa bori lọ.

Ọrọ yi to ko ko pọ ṣugbọn labẹ rẹ awọn eeyan mii naa tun da si ti ọp n fi atilẹyin wn han si Tiwa Savage pe ko ma ṣe foya.

Tiwa Savage

Oríṣun àwòrán, Tiwa Savage

Fun apẹrẹ, @am_tolufatokiladega n beere pe kini Tiwa Savage ṣe to buru?O ni igboya rẹ lati koju ẹni to fẹ fi fidio naa gba owo lọwọ rẹ jẹ iwuri.

O ni bi Tiwa Savage ko ba kọ lati san owo fun ẹni naa ni, ki ba ma gbadun owo mẹnumọ to fẹ gba lori nkan to ṣe.

Asiko to yẹ ki ẹyin ololufẹ Tiwa fi ifẹ han ree-Daddy Freeze

Ilumọọka sọrọsọrọ Daddy Freeze ti dari ọrọ sọdọ awọn to pe ara wọn lololufẹ Tiwa Savage

Gbajugbaja sọrọsọrọ yi niasiko tawn obinrin yoo gbaruku ti ara wọn lo de yi

Oríṣun àwòrán, Daddy Freeze

"Nkan to ṣe,gbogbo eeyan lo n ṣe.Iyatọ to wa ni pe o kan gbe kamẹra lọ sibẹ ni."

O ṣalaye pe 'fọnran ibalopọ' rẹ yi yoo tabuku awọn obinrin ni ko si ni da ko ribẹ

O fi kun pe asiko rẹ kawọn obinrin gbaruku ti kan lara wọn ki wn si sinmi lati maa fi ṣe yẹyẹ.

"Ẹni tẹ n wo fi ṣe awokọṣe ree,aayo yin tabi ki lorukọ tẹ n pe.Asiko lo de yi lati gbaruku ti,''

''Ko nilo owo yintabi nkan mii,ifẹ lo nilo ki fi han an."

Oṣere Nollywood nii,Susan Peters naa da si ọrọ yi

Susan Peters

Oríṣun àwòrán, Instagram/Susan Peters

Loju opo r ni Instagram, niṣe lo beere pe ki lo de ti eeyan yoo fiya fidio obinrin ti ko ni fi oju ara rẹ si.

"Ki lo de ti wa tiẹ fi lọ ya fnran fidio gan alara?

O fi kun pe ''Ohun kohun to ba ṣe,wa gbẹsan rẹ...gboingboin la wa lẹyin rẹ''

Susan Peters

Oríṣun àwòrán, Instagram/Susan Peters

Ọrọ ti Mercy Aigbe naa sọ ko fi taratara yatọ si eleyi ti Iyabo Ojo sọ.

Mercy Aigbe

Oríṣun àwòrán, Instagram/Mercy Aigbe

Ninu fnran fidio kan ti oun ṣe oṣerebinrin Gorgina Onuoha sọ pe ''ọkunrin to ba nifẹ r ko ni ya fidio ibalopọ yin''

O gba awọn obinrin lamọran pe ki wọn ma ṣe fi gbogbo ọkan tan ọkunrin toun ti bi ifẹ ba ṣe n pa wn bi ọti to.

"Ma fi ọkan tan eeyan tan, koda to fi mọ ọkọ rẹ.''

Kini Tiwa Savage s nipa fidio yi?

Ninu ọrọ to fi sita loju opo ayelujara, o ni awọn to wa nidi ki wọn ba orukọ oun jẹ pẹlu fidio naa n binu oun tori pe oun fi ọr naa ṣe awada loju agbo.

O ni pẹlu boun ti ṣe logun sita lori fidio naa, oun ti ribi ka wn lọwọ ko.

Laiko to n kọrin loju agbo, Tiwa sọ pe ko ni si ni ti yoo ri fọnran fidio yi amọ o jọ pe awọn to n halẹ mọ ti pada fi sita faraye.