Sunday Igboho linked with Boko Haram Sponsor: Malami sọ̀rọ̀ sókè pé Sunday Igboho ń gbowó ìgbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ agbódegbà Boko Haram

Oríṣun àwòrán, Sunday Adeyemo/instagram
Ijọba apapọ ti gbe e sita pe awọn ti kẹẹfin ajọṣepọ laarin eekan ajafun idasilẹ orilẹede Yoruba, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ati ọkan lara awọn agbodegba fun awọn agbebọn Boko Haram.
Amofin agba fun orilẹede Naijiria, Abubakar Malami (SAN) salaye lasiko to n ka abajade igbimọ tẹẹkoto ti aarẹ gbe kalẹ lati tu iṣu de isalẹ ikoko ọrọ Sunday Igboho ati aṣiwaju ẹgbẹ IpoB, Nnamdi Kanu.
O ni ijọba apapọ ti ri aridaju ajọṣepọ laarin Surajo Muhammad ti wọn ran lọ sẹwọn gbere laipẹ yii lorilẹede United Arab Emirates lori ẹsun ṣiṣe atilẹyin fun igbesumọmi ati Sunday Igboho.
Ẹwẹ, ẹgbẹ Ilana ọmọ Oodua ti fi esi ranṣẹ si ijọba pe Àwàdà kẹrí-kẹrì ni ẹ̀sùn ìgbésùnmọ̀mí tí Malami fi kan Sunday Igboho - Ilana omo Oodua.
- Àwọn agbébọn ya wọ ọgbà ẹ̀wọ̀n ní Oyo, wọ́n tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀
- Kéére o! Ìjọba tú òbìnrin kan ṣoṣo amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ Sunday Igboho tó kù láhàmọ́ DSS silẹ̀
- Àwọn aṣòfin ti fòǹtẹ̀ lu ṣíṣẹ́ oyún tí kò í pé oṣù mẹ́ta ní ìlú yìí
- Òṣèré Tíátà ṣèèṣì yìnbọn lórí ìtàgé, arábìnrin kan ti forí la ikú, òmìí farapa
- Ẹ fi ọkàn balẹ̀, a o ṣàfihàn gbogbo àbájáde ìwádìí ìgbìmọ̀ Endsars - Babajide Sanwo-Olu
- Gbẹgẹdẹ fẹ́ gbiná láàrín Oluwo àtàwọn ìgbìmọ̀ Ìmáàmù àti Àlfáà ilẹ̀ Yorùbá, wọ́n ní Oluwo ń kọjá àyè rẹ̀
- Ọ́ọ́físà tó lu Clement awakọ̀ Uber níbi EndSARS gba ìwé máa lọ ilé ná
Bakan naa lo fi kun un pe laarin ọdun 2013 si 2020, Igboho gba owo to to miliọnu mẹtadinlaadoje naira, (N127m) latọdọ awọn agbodegba kan ninu eyi ti aṣofin apapọ orilẹede Naijiria kan wa.
Malami ṣalaye pe, "Iwadii naa fihan pe Sunday Igboho jẹ ọkan lara awọn alaṣẹ ileeṣẹ Adesun International Concept Limited ti wọn da silẹ lọjọ kẹtalelogun oṣu kẹrin ọdun 2010. O ni Oladele Oyetunji ati Aderọpo Adeyẹmọ gẹgẹbi adari pẹlu. Aṣuwọn owo banki mẹtalelogoji ni Sunday Igboho nii ṣe pẹlu lawọn banki mẹsan ọtọọtọ."
O fi kun un pe ọkan gboogi lara awọn agbodegba awọn ajafun ipinya Naijiria naa lawọn rii pe o jẹ aṣofin apapọ kan. "Miliọnu mẹtadinlaadoje o le ẹgbẹrun marundin laadọjọ Naira (N127, 145,000 ni Sunday Igboho gba laarin ọjọ kejilelogun oṣu kẹwaa ọdun 2013 ati ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹsan ọdun 2020 lati ipasẹ aṣuwọn ifowopamọsi ileeṣẹ Adesun International Concept ltd".
O ni ọrinlelugba o din meje miliọnu naira ati ẹgbẹrun lọna aadọwa o le mẹjọ, o le ẹgbẹrun igba o le mẹtamiliọnu (N273, 198, 200) ni owo to wọ aṣuwọn ifowopamọsi Sunday Igboho laarin ọjọ karundinlogun oṣu kẹta ọdun 2013 si ọjọ kọkanla oṣu kẹta ọdun 2021. Iwadi si fihan pe ileeṣẹ Adesun International Concept ltd (to jẹ ileeṣẹ Igboho gẹgẹ bi ijọba ṣe sọ) fi miliọnu mejila ati ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwaa naira ranṣẹ si ileeṣẹ AbbalBako & Sons.
Amofin agba orilẹede Naijiria, Abubakar Malami tun fi kun pe ileeṣẹ Abbal Bako ati Abdullahi Usman to jẹ agbodegba rẹ wa lara awọn afurasi lori iwadii ẹsun gbigbe owo kalẹ fun igbesunmọmi.
O ni Abdullahi Usman yii n ba Surajo Ababubakar Muhammad ti wọn ran lọ ẹwọn gbere lorilẹede UAE fun ṣiṣe agbodegba igbesumọmi ni ajọṣepọ owo ati pe iwadii ijọba ti fihan pe ajọṣepọ n wa laarin awọn to n ja fun idasilẹ orilẹede ẹya wọn, iwa igbodedegba fawọn agbesunmọmi ati dida omi alaafia ru lorilẹede Naijiria.
O wa fi kun un pe ijọba apapọ yoo gbe igbesẹ gbogbo to ba yẹ labẹ ofin lati rii daju pe amojuto to tọna waye ki wọn si fi gbogbo awọn taje rẹ ba ṣi mọ lori jofin.















