Alec Baldwin: Ohun táa mọ̀ nípà òṣèré tó ṣèèṣì yìnbọn pààyàn lórí ìtàgé rèé

Awọn to n yinbọn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Taa ba n rin ta n wa ohun taa jẹ ka ma ṣe pade ohun ti yoo jẹ wa ni ọpọ maa n gba ladura amọ nidi wiwa ijẹ lawn kan ti kagbako aburu yii.

Arabinrin kan ti fori la iku ti ọkunrin kan naa si farapa lẹyin ti gbajugbaja oṣere Alec Baldwin ṣina ibọn ti o mu dani lori itage bolẹ.

Ọlọpaa ilẹ Amẹrika ti ni Ọgbẹni Baldwin yin ibọn ọhun nibi ti wọn ti n ya fiimu kan ti akọle rẹ n jẹ "Rust" ni Mexico.

Arabirnin naa to gba ibẹ ku ni wọn sare gbe lọ sileewosan ṣugbọn ẹpa o boro mọ, bo ṣe farapa jinnu tori naa o ti dagbere faye.

Agbẹnusọ kan fun Ọgbni Baldwin sọ fun ileeṣẹ iroyin AP pe iṣẹlẹ mọọmọ waye ni tori ibọn ti wọn fi n ṣere lo wa lọwọ rẹ.

Àkọlé fídíò, Ogogo wá sí iléèwé wa, mo kéwì fún un ló sọ mi di èèyàn ńlá lórí ayélujára - Akinwumi Akewi
Àkọlé fídíò, Àwọn abirùn ọmọ tí òbí wọn tì mọ́lé ni mo lọ ń kó jáde láti máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ iléèwè - Sekinat Ahmed

Arabinrin to ku, Hutchins to jẹ ẹni ọdun mejilelogoji lo n ṣiṣẹ gẹgẹ bii adari aworan lori itage naa nigba ti Ọgbẹni Souza to fara pa jẹ ẹni ọdun mejidinlaadọta.

Awọn ọlọpaa n ṣe iwadii iṣẹlẹ naa lọwọlọwọ amọ ko tii si ẹnikni ti wọn fi ẹsun kan. Iroyin kan ni Baldwin ti ba awọn Ọlọpaa sọrọ.

"Funra rẹ lo wa si agọ wa to si pada lọ funra rẹ lẹyin taa fi ọrọ waa lẹnu wo tan". Agbẹnusọ Ọlọpaa lo sọ bẹẹ.

Loju opo ti arabinrin to ku ọhun ni funrarẹ, o kọọ sib pe iwe iroyin igba de igba ti ilẹ Amẹrika kan, "the American Cinematographer" pe oun ni "irawọ to n dide" lọdun 2019.

"Ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ ko tii hande bayii ṣugbọn a n ṣiṣẹ lati mọ sii a si fọwọ si iwadii ijinlẹ lori iṣẹlẹ aburu yii".

Àkọlé fídíò, 'Mi ò yàtọ sí Krìstẹni tàbí Mùsùlùmí tóun náà da ẹsìn rẹ pọ mọ jíjẹ Dokita, Babaláwo Dókítà l'èmi'

Ọlọpaa ni nkan bii ago kan abọ ni ikọ awọn lọ si ibi ti wọn ti n ṣe fiimu naa lẹyin ti wọn gba ipe pajawiri nipa iyinbọn naa.

Iru iṣẹlẹ bayii to waye lori itage fiimu Rust ṣọwọn gidi amọ kii ṣe ohun ti eti ko gbọ ri.

Ibọn gidi ni wọn maa n saba lo ninu awọn fiimu wọn ni orilede yii ti wọn yoo si ki i ni ọta ti yoo kan ṣa ina ti yoo si dun gbamu amọ ti nkankan ko ni jade nibẹ.

Iru nkan bayii naa ti ṣẹlẹ ri ninu fiimu kan lọdun 1993 tori wọn ṣewadii wn si rii pe ko pẹ ti wọn fi ibọn yẹn yin ọta gidi to si ti farasin sinu ile ọta rẹ. Nigba ti wn wa n yin awọn ọta ofifo ni iyẹn naa ba fo jade.