Endsars Anniversary:''Sójà yìnbọn fún ní ìwọdé EndSars lọ́dun tó kọ̀ja, àmọ́ máà tún darapọ̀ mọ́ ìwóde láti ṣèrántí àwọn tó kú''

Oríṣun àwòrán, Alamy
Ọkan lara awọn oluwode Endsars ni agbegbe Lekki Tollgate, Nicholas Okpe ti sọ iriri re lasiko iwọde Endsars to waye ni ọdun to kọja.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin, Okpe ni nkan to ṣẹlẹ lasiko iwode ọdun to kọja naa kọja afarada nitori oun jẹ ọkan lara awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa.
Okpe to jẹ awakọ ni ohun to jẹ ki oun darapọ mọ iwọde Endsars lọdun to kọja ni pe ifiyajẹni awọn ọlọpaa buru jai, ti oun ri si iwọde naa jẹ gẹgẹ bi ọna lati ja fun ẹtọ awọn ọmọ Naijiria.
''Iyalẹnu lo jẹ fun wa nigba ti a gbọ̀ pe awọn soja n bọ, lootọ ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn''
''Amọ a joko, ti a si bẹrẹ si ni kọ orin asia orilẹede Naijiria, ẹnu rẹ lawa lọwọ ti wọn fi bẹrẹ si ni yinbọn.''
''Ibọn ba mi ni aya, ti wọn si sare gbe mi lọ si ileewosan, wọn yọ ọta ibọn naa lẹyin ti ileewosan bi mẹta kọ mi''
''Osu kan ni mo lo ni ileewosan amọ mi o ri ẹni ranmilọwọ fun iwosan to peye.''
''O ṣeeni laanu pe titi di asiko yii, ko si ẹni ti ijọba fun ni owo gba mabinu lati ọdun to kọja nitori mo lọ si iwadii ti ijọba gbe kalẹ, amọ awọn ti ọlọpaa ti fi iya jẹ tẹlẹ ni wọn fun ni owo gba mabinu.
- Sunday Igboho: Kódà kó jẹ́ pé ẹranko lẹ dé mọ́lẹ̀, yóò ṣe àìsàn ká tó wa sọ ọmọ èèyàn - Alhaji Ajikobi
- Ka nípa nkán tí Iyabo Ojo àti àwọn èèkàn amúlúdùn sọ lórí 'sex tape' Tiwa Savage
- Ìdí tí Ooni Ogunwusi fi gbé ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ṣe ọjọ́ ìbí 28 sáyé àti bó ṣe tọ́ ọ dàgbà
- Fídíò ìbálòpọ̀ tó lu jáde nípa olórin Tiwa Savage, èsì ọlọ́rọ̀ gangan rèé
- Sanwo-Olu ti gba àwòrán rẹ̀ lọ́wọ́ Boda Taiye Oniyakuya
Nicholas Okpe ni ajọ iwadii naa ni awọn soja kọ lati yu si ajọ iwadii naa eleyii to mu ki iwadii dopin lori ifẹhonuhan Endsars.
Okpe bere iranwọ lati gba itọju to peye nitori pe iho ti ibọn gba wọ aya oun ṣi wa ni bẹ, ti ohun ko si le e ṣiṣẹ agbara kankan.

Oríṣun àwòrán, Others
O fikun pe awọn mọlẹbi ati ọrẹ lo n ran oun lọwọ pẹlu ati ri ounjẹ oojọ jẹ.
Amọ Okpe ni oun yoo darapọ mọ awọn afẹhonuhan loni lati ṣedaro awọn ẹmi to sọnu lasiko iwọde naa ati lati beere fun ẹtọ wọn.












