Governor Sanwo-Olu and Taye Oniyakuya: Sanwo-Olu ti gba àwòrán apanilẹ́rín tí Boda Taiye Oniyakuya yà nípa rẹ̀

Oríṣun àwòrán, other
Aṣe ori to maa gbeni ko alawoore ko di dandan ko tobi tuulutuulu. Aworan to gbe Bọda Taiye Oniyakuya ko gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu kii ṣe eyi to fi gbogbo ara gbadun.
Amọṣa, Gomina Babajide Sanwo-Olu ti tẹwọ gba aworan apanilẹrin nipa rẹ ti Taiwo Osinọwọ, ọdọmọdekunrin oniṣẹ ọna aworan yiyan kan ti ọpọ mọ si Bọda Taiye Oniyakuya ya.
Ọdọmọde ayaworan naa bọ si gbangba ode lẹyin to fi aworan aworẹrin nipa Gomina Sanwo-Olu lori ayelujara.
- Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ UI méjì fórí kó ọta ìbọn lọ́jọ́ kan ṣoṣo, wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn lọ́jọ́ kan náà
- Ìdí tí Ooni Ogunwusi fi gbé ọmọ rẹ̀ obìnrin tó ṣe ọjọ́ ìbí 28 sáyé àti bó ṣe tọ́ ọ dàgbà
- ₦500 tí màá fi ra 'Data' láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa
- Ìgbìmọ̀ tí ìjọba ìpínlẹ̀ Eko gbé kalẹ̀ lórí #ENDSARS ti parí ìṣẹ́, àbọ̀ rèé
- Nkán mẹ́rin tó yẹ kóo mọ̀ nípa àjọ̀dún Maolud Nabiyy tàwọn Mùsùlùmí ń ṣé
O sọọ lori ayelujara pe oun ya aworan Gomina Sanwo-Olu. "Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aṣeyọri iṣẹ yii. Mo si mọ pe gomina yoo fẹran rẹ. Emi ṣi ni ayaworan to gbayi julọ ni UAR."
Aworan naa kan gomina Sanwo-Olu lara, loun naa baa daa lohun pe:
"Se emi naa lo ya bayii? Mo lero pe waa nifẹ lati gbe e lemi lọwọ abi? O daa, wa gbe e fun mi ni ọfiisi mi. Hmmmm..."
Gomina Sanwo-Olu pe ayaworan naa si ori pepele ibi to ti n sọrọ lati kii to si fi daa loju pe ko si eera kan ti yoo rin in.
Ṣaaju ni Bọda Taye Oniyakuya ti sọ fun gomina ipinlẹ Eko pe awọn eeyan kan ti gba oun ni amọran pe ki oun maṣe yọju sii nitori pe gomina naa lee fi panpẹ ofin mu nitori aworan iyakuya to ya nipa rẹ.
O ni awọn kan tilẹ sọ fun oun pe ọgba ẹwọn kirikiri ko jina si ile gomina ti oun ti fẹ lọ yọju sii.
Amọṣa gominaSanwo-Olu ni oun ṣetan lati sanwo fun aworan naa gẹgẹ bi ẹmi imọriri iṣẹ ọna ọhun.













