Èèyàn mẹ́rin kú níbi táwọn awakọ̀ èrò tí ń ṣe ìfẹ̀hónúhàn lórí àfikún owó epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Ko din ni eeyan mẹrin to padanu ẹmi wọn nibi tawọn awakọ ero ti n ṣe ifẹhonuhan lori bowo epo bẹntiroolu ṣe n lọ soke lorilẹede Kenya.
Igba keji ree towo epo yoo lọ soke laarin oṣu kan ni Kenya, latari ogun to n lọ lọwọ laarin Iran ati Amẹrika eyi ti ko jẹ kawọn orilẹede agbaye maa ri ọna ori omi Strait of Hormuz gba gbe epo rọbi kọja.
Igba eeyan lawọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu bayii lori isẹlẹ naa.
Ajọ to n ri si ọrọ ounjẹ ti sọ tẹlẹ pe bi owo epo ti n lọ soke yoo ṣakoba fun kiko ounjẹ wọlu tori owo ọkọ ti di gọbọi.
Gbogbo awọn awakọ ero lo daṣẹ silẹ lati le ṣe ifẹhonuhan lori bi owo epo ṣe n lọ soke loorekoore ni Kenya.
Ọpọ ero lo n fẹsẹ rin niluu Nairobi lọjọ Aje latari ifẹhonuhan to waye.
Niṣe lawọn olufẹhohuhan gbedi di oju ọna kaakiri, tawọn mii ninu wọn n si n sun taya loju titi.
Awọn ọlọpaa yin tajutaju lawọn ibikan lati tu awọn olufẹhonuhan naa ka.
Ẹwẹ, ijọba orilẹede Comoros ti fagile erongba rẹ lati ṣe afikun owo epo bẹntiroolu pẹlu ida 40% lẹyin iwọde to waye nibẹ.
Igbakeji ọga agba ajọ WFP to n ri sọrọ ounjẹ lagbaaye, Carl Skau, sọ pe nnkan to n ṣẹlẹ lẹkun Middle East n ṣakoba fun ẹkun ila oorun ilẹ Afirika.
''Nnkan to n ṣẹlẹ lẹkun Middle East lo n jẹ ki nnkan gbowo lori.
Ko si owo ti a le lo gan an lati fi ṣe iṣẹ wa, a ko le tọju awọn to yẹ ka tọju.
Eleyii to tun dabi rẹ ni pe airi ọna ori omi Strait of Hormuz gba mọ ti ṣakoba fun gbigbe ounjẹ bii irẹsi lati India fun apẹẹrẹ lọ si Somalia.''
O fikun ọrọ rẹ pe airi ajilẹ gbe kọja lori omi yoo ṣakoba fun eto ọgbin eyi ti yoo ni ipa ti ko dara lọjọ iwaju ni bii oṣu meloo kan to n bọ.




























