Sunday Igboho: Kódà kó jẹ́ pé ẹranko lẹ dé mọ́lẹ̀, yóò ṣe àìsàn ká tó wa sọ ọmọ èèyàn - Alhaji Ajikobi
Laipẹ yii ni ọrọ ipo ilera ti adari awọn ajafẹtọ Yoruba Nation, oloye Sunday Adeyemọ bẹrẹ si ni kọ awọn ololufẹ rẹ lominu.
Bẹẹ si ni oriṣiriṣi iroyin lo ti n jade nipa rẹ amọ ninu ifọrọwanilẹnu BBC yoruba pẹlu Alhaji Yussuf Ajikobi, ọkan lara awọn to sunmọ Sunday Igboho bi eti to si n ṣe agbatẹru rẹ pẹlu awọn ọpọlọpọ mii to darukọ.
"Ẹlọmii, ọjọ to gbọ pe wọn mu oloye Sunday Igboho ni aarẹ ti bẹrẹ si ni ṣe oun naa".
Alhaji Ajikobi jẹ ko di mimọ pe nibi ti ọrọ de duro bayii, awọn lọba lọba Yoruba gbudọ dide lati kopa ninu wiwa itusilẹ Oloye Sunday Igboho kuro lẹwọn to wa ni orilẹede Benin Republic.
Ajikobi ni lojoojumọ ni ilera Sunday Igboho n mẹhẹ sii to si nilo amojuto kanmọ kanmọ.
O fi kun un pe koda o ṣeeṣe pe iru itọju ti wọ́n n fun un latimọle gan lo n dakun aisan to n ṣee.