Sunday Igboho: Mi ò bẹ ẹnikẹ́ni tó sún mọ́ mi láti bèrè owó lọ́wọ́ yín fún ìtọ́jú mi o

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Gbajugbaja ajafẹtọ Yoruba Nation, Sunday Adeyemo Igboho ti ni oun ko tọrọ fun owo lọwọ ẹnikẹni lati lo fun ilera rẹ.
Ọrọ yii jade latọwọ ọkan lara awọn agbẹnusọ rẹ, Olayomi Koiki to fi soju opo ayelujara pe:
"Iroyin kanmọ kanmọ kan ree lorukọ ajijagbara Sunday Adeyemọ ti ọpọ mọ si Sunday Igboho pe oun ko ran eeyan kankan tabi awọn to n ba oun ṣiṣẹ yala ẹṣọ ni tabi ọrẹ rẹ lati beere owo fun itju ara rẹ ni orilẹede Benin Republic".
Fidio atẹjiṣẹ yii bọ sita ni ọjọ Kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa ọdun 2021 ninu eyi ti agbẹnusọ rẹ ti n sọ pe lati ọwọ agbẹjọro rẹ kan ni o ti fi ọrọ naa ṣọwọ.
O ni Oloye Sunday Adeyemo Igboho ko beere fun owo lati tọju ara rẹ ni ilu Benin Republic to wa.
Wọn gbọ iroyin pe ọpọ awọn to n ba a ṣiṣẹ to n lo anfani ipo to wa lọwọ lati bere owo fun itọju Igboho, amọ wọ́n ni irọ gbaa ni wọn n pa.
- "Ẹ tètè gbé Sunday Igboho lọ fún ìtọ̀jú lókè òkun, kó tó pẹ́ jù"
- Ìgbésẹ̀ tà ń gbé rèé lórí ìlera Sunday Igboho àti ìtúsílẹ̀ rẹ̀ - Ilana Ọmọ Oodua
- Ṣé lóòtọ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè Benin ti gba ibọ̀dè lórí ẹjọ́ Sunday Igboho?
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tí Sunday Igboho gbàlejò Fani-Kayode
- ₦500 tí màá fi ra 'Data' láti fí ṣé Yahoo-yahoo ló mú mí yín ọlọ́kadà lọrùn pa
"Baba wa ti ni ki n sọ fun gbogbo ẹyin ti ẹ jẹ ololufẹ wọn pe ki ẹ ṣọra gidi gan fun awọn ọlọdani tabi to ba n dibọn bii pe oun ran wọn niṣẹ ti wọn si ti n gba owo fun itọju ara oun tori oun ko sọ bẹẹ ko si ran wọn niṣẹ".
Koiki ni lootọ ni o rẹ Oloye Igboho gẹgẹ bi ẹ ti ṣe n gbọ tẹlẹ amọ ko ran ẹnikẹni lati gba owo fun itọju ara oun.
O fi kun un wipe bi ẹnikẹni ba ri eeyan to n beere owo lọwọ rẹ lorukọ Sunday Igboho ki wọn fi to wọn leti ki wọn lee gbe igbesẹ lori rẹ.


















