Fashola on Rising Debt: Ọ̀kan lẹ́ẹ fọwọ́ mú o, nínú ká jẹ gbèsè tàbí ká fi kún owó orí tẹ́ẹ̀ ń san - Fashola
Minisita feto akanṣe iṣẹ ati ile igbe ni Naijiria Babatunde Raji Fashola ti ṣalaye idi ti gbese ti ijọba Naijiria jẹ fi n pọ sii.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba Minisista sọ pe eto ni ijba n fi owo gbese yi ṣe kalẹ fun awọn to n bọ lẹyin wa ọla ki igbe aye le dẹrun fun wọn.
Fashola ni o di igba ti ijọba aarẹ Buhari ba lọ tan ki awọn gbesẹ tawọn n jẹ to yọ nipa ohun ti wọn fi ṣe.
O ṣalaye pe o di dandan ki awọn jẹ gbese yi bi bẹẹ kọ ohun to ku tawọn yoo ṣe ni ki wọn fowo kun owo ori eyi ti ọpọ ọmọ Naijiria ko ni fẹ faramọ.
Kaka bẹẹ o ni ohun ti awọn ki ba ṣe ni pe ki awọn ṣe awọn akanṣe iṣẹ kan ki awọn si pa awọn miran ti.
- SERAP gbé Fashola lọ sílé ẹjọ́ nítorí owó iná
- Fashola fi orúkọ àwọn ilé isẹ́ tó jẹ́ àjẹbánu síta.
- Wo ohun tí Fashola rí níbi ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate tó ń fa ariwo lórí ayélujara
- Àwọn fíìmù Nollywood ń mú kí òògùn owó àti ìjínigbé gbilẹ̀ síi - Fashola
- Tùẹ̀, èsì yín ò jẹ wá! Ohun mẹ́rin tuntun táa ń bèrè lọ́wọ́ Òṣèré Odunlade àti TAMPAN rèé bí bẹ́ẹ̀ kọ́ - THURIST
''Gbogbo nkan taa joko le ni isinyii ko to waa lo mọ. Papakọ ofurufu Eko nigba ti wọn kọ ni 1975,ero to n ṣeto fun kere ṣugbọn loni o ti le ni miliọnu mẹjọ lọdun to n lo papakọ ofurufu naa''.
Fashola ṣalaye pe Aarẹ Buhari kọ lo n ya owo gbese bi kii ṣe pe ijọba lo n ya owo lorukọ orileede Naijiria.
Nipa awọn oju ọna ti ijọba ko ti pari iṣẹ lori rẹ bi ti marose Ilorin-Ogbomoso-Oyo,Fashola ni owo ni ko lati fi pari wọn.

Oríṣun àwòrán, Google
O ni ibi ti awọn gbiyanju de naa ni iṣẹ le de nitori ipa ko ka sisan owo fawọn agbaṣẹṣe loju ọna naa.
Lori eto idibo to n bọ lọna Fashola ni ere ẹni ti yoo jẹ Gomina ti yoo mu anfaani ba ipinlẹ lo yẹ ki awọn eeyan maa sa dipo ẹni ti yoo jẹ aarẹ.
O ṣalaye pe ti gbogbo ipinlẹ ba ṣe nkan bo ṣe yẹ ki wọn maa ṣe ''ti ẹyẹ n ke bi ẹyẹ ti eku si n ke bi eku,gbogbo ariwo yi o dami loju pe o ma walẹ''.
- Òkóbó ni mí àmọ́ ìyàwó mi gbà láti fẹ́ mi lẹ́yìn tí mo sọ fun un - Pásítọ̀ Olumide Oni
- Mi ò gbá ẹ mú nígbà tóo dákú níbí ìsìnkú Mama Nkechi tórí ... - Toyin Abraham
- Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi
- Ìdí rèé tí Oluwo ìlú Ìwo kò fi tíì gbé ìyàwó míìràn gẹ́gẹ́ bí Olórí láàfin















