Impotency: Pásítọ̀ Olumide Oni sọ ìrírí bó ṣe rí ìwòsàn ìyanu lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó fi jẹ́ òkóbó

Oríṣun àwòrán, Others
Ọkan lara awọn Pasitọ ijọ Mountain of Fire and Miracle Ministries, MFM, Pasitọ Olumide Oni ti sọ iriri rẹ bi o ṣe ri iwosan gba lẹyin ti o ti jẹ okobo lati kekere wa.
Pasitọ Oni sọ iriri rẹ lasiko to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu akọroyin ileeṣẹ Punch nipa bi o ṣe bẹrẹ iṣẹ Oluwa, igbeyawo rẹ to fi mọ ipenija okobo to jẹ lati kekere.
Pasitọ Oni ni iya-iya oun to tọ oun dagba lo kọkọ sọ fun oun nipa ipe ti Oluwa pe oun si iṣẹ Oluwa ati bi oun 'se jẹ eniyan ara ọtọ ni Ọlọrun fi jẹ ki oun jẹ okobo.
- 'Olóyè Sunday Igboho fi ọ̀rọ̀ kánmọ́ kánmọ́ ráńṣẹ́ láti Cotonou nípà owó ìtọ́jú ìlera rẹ̀'
- Tùẹ̀, èsì yín ò jẹ wá! Ohun mẹ́rin tuntun táa ń bèrè lọ́wọ́ Òṣèré Odunlade àti TAMPAN rèé bí bẹ́ẹ̀ kọ́ - THURIST
- Ọ̀kan lẹ́ẹ fọwọ́ mú o, nínú ká jẹ gbèsè tàbí ká fi kún owó orí tẹ́ẹ̀ ń san - Fashola
- Nkechi Blessing: Mi ò gbá ẹ mú nígbà tóo dákú níbí ìsìnkú Mama Nkechi tórí ... - Toyin Abraham
- Àwọn obìnrin ń ṣe igbéyàwó pẹ̀lú igi láti ṣààmì ètò ìdàgbàsókè ìlú wọn
- ''Ìrírí mí rèé lóri bí mo ṣe fún ìbejì mí lóyún tó sì tún bí ọmọ méjì fún mi''
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọṣẹ ìfọyín àti omi gbígbóná ṣe ìtọ́jú okùn tó so olúbi pọ̀ mọ́ ìyá ọmọ
- Báyìí ni mo ṣe san nínú oore Ọlọ́run tó fi Kábíyèsì Ooni ti Ile Ife ta èmi Silekunola lọ́rẹ - Olorì Wòlíì Naomi
O ni iya-iya oun sọ fun oun bẹẹ ni ọmọ ọdun mejila, bi o tilẹ jẹ pe oun ti mọ fun ara oun ki o to di asiko yii.
Iya Agba naa to jẹ woli sọ fun oun pe idi ti oun fi jẹ okobo ni lati lo ara oun fun iṣẹ Oluwa lai ṣe agbere tabi pansaga.
Pasitọ Ijọ MFM naa ni lẹyin ti iya agba ku, ni ohun gbogbo daru fun oun, ki oun to ranti asọtẹlẹ ti iya agba sọ fun nipa iṣẹ Oluwa.
''Lẹyin naa ni mo bẹrẹ iṣẹ Oluwa, ti mo si ri ore-ofẹ ati aanu loju baba mi ninu Oluwa, D. K. Olukoya to si gba mi gẹgẹ bi iranṣẹ Oluwa.''
''Lati igba naa ni mo ti bẹrẹ iṣẹ Oluwa , ti oun gbogbo si dara fun mi, to fi mọ awọn ijọ ti mo ti ṣe pasitọ ti gbogbo awọn ori ijọ yii si ni idagbasoke.''
Bi mo se ri iwosan gba lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti mo fi jẹ okobo ni yii...
Pasitọ Olumide Oni ni lẹyin ti iya agba sọ fun oun idi ti oun fi jẹ okobo, ti nkan ọmọ ọkunrin rẹ ko le gberi ni oun ti gba kan mu.
''Lasiko ti mo jẹ pasitọ ni awọn ọmọ iya meji kan wa si ile ijọsin naa fun adura itusilẹ, amọ bi wọn ṣe wọn n lọ ni mo gbọ ohun pe iyawo mi ni ọkan lara awọn obinrin meji naa.''
''Lẹyin eyi ni mo darapọ mọ ẹka ijọ ti wọn ki n le kọnu ifẹ sii nitori eniyan o kan le dede lọ ba obinrin ninu ijọ nitori pe o gbọ ohun.''

Oríṣun àwòrán, Others
''Lẹyin ti iyawo mi pari ẹkọ rẹ, ti a fẹ ṣe igbeyawo ni mo sọ fun un pe okobo ni mi, ti mo si le ma bimọ ni aye.''
''Iyawo mi ni oun ni igbagbọ pe ọkọ oun ni mi, ti Olorun yan fun un nitori naa oun ko ni tako igbeyawo wa nitori mo jẹ okobo''
''Inu mi dun nitori iyawo mi gba lati duro ti mi pẹlu ipenija ti mo n koju yii.''
''Amọ iyanu ṣẹlẹ ni ọjọ igbeyawo mi nitori ọjọ naa ni mo ri iwosan gba ni ọna ara.''
''Lati asiko ti ẹsin igbeyawo mi bẹrẹ ni ọjọ naa ni inu rirun bẹrẹ si ni damu mi, pasitọ to so wa pọ ni lati ṣe kanmọ kanmọ nitori inu rirun naa ti poju.''
- Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí fídíò tó sàfihan ọlọ́pàá tó fí ìyà jẹ aráàlú kan tórí N25,000 - Iléeṣẹ́ Ọlọpàá
- "Ìbejì ní wá ṣùgbọ́n àyẹwò DNA ní baba ọtọ́ọ̀tọ̀ ló bí wà"
- Mà á dupò Ààrẹ tí Ọlọ́run àti ọmọ Naijiria bá gbà fún mí - Tunde Bakare
- Obesere sàlàyé ipa rere tí Dudu Heritage kó nínú ìgbé ayé rẹ̀ àti bó ṣe di èèyàn
- Èrò tó bá jáde wo Buhari wá fi irú ìyà tó ń jẹ wọ́n hàn-án ni, kìí ṣe ti ìfẹ́ - Afenifere, Ohaneze
- "Mo ti pa ọmọdé mẹ́wàá, mo sì ń mu ẹ̀jẹ̀ wọn"
''Inu rirun naa ko jẹ ki n le lọ si ayẹyẹ igbeyawo mi nibi ti ọpọ ero pejọ si lati jẹun.''
''Bi mo se n wọ ile ti a gba lati ma a gbe gẹgẹ bi lọkọ-laya ni mo ri pe nkan ọmọ ọkunrin mi dide, ti iriri mi gẹgẹ bi okobo si pari.''
''Lọwọlọwọ bayii mo ti di ẹni to bi ọpọlọpọ ọmọ nitori mo ri iyanu, ti mo si dupẹ lọwọ iyawo mi to duro ti mi.''












