Dudu Heritage Burial: Dudu Heritage ló jẹ kí n dí ènìyàn láyé nínú iṣẹ́ orin kíkọ

Dudu Heritage

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin iku gbajugbaja to n gbe awọn olorin jade, Ola Ibironke ti ọpọ eniyan mọ si Dudu Heritage ṣi n mi ilu titi lẹyin to jade laye.

Ọpọlọpọ awọn gbajumọ ni agbo ere oṣere lo ti jade lati wa sọ ọrọ iwuri nipa Dudu Heritage ati ipa ribiribi to ko ni igbesi aye wọn.

Lara wọn ni gbajugbaja olorin Fuji, Dudu Heritage to sọ nipa eniyan nla ti Dudu Heritage jẹ, ati bi awọn ṣe pade titi to fi da oloogbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obesere ni iroyin iku Dudu Heritage to jẹ ọrẹ oun fun bi ọgbọn ọdun bayii ati oṣiṣẹ kan naa ninu agbo oṣere.

O ni oun ko le gbagbe ipa ribiribi to ko ninu aye oun, ti awọn si jẹ ọrẹ timọtimọ titi di ọjọ iku rẹ.

Bakan naa ni ọpọ eniyan ko mọ wipe Dudu Heritage lo gbe awo orin Obesere, ''Overflow'' jade, eleyii to sọ ọ di ilumọọka.

Àkọlé fídíò, 2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Obesere salaye bi Dudu Heritage ṣe dagbere fun aye

Obesere to salaye pe iku Dudu Heritage ba oun ni ojiji to si jẹ ibanujẹ ọkan fun oun.

O ni ti ẹnikẹni ba sọ fun oun pe Dudu Heritage ko ni lo ogun ọdun tabi ọgbọn ọdun si ni oke ilẹ, oun yoo sọ pe irọ ni.

''Dudu Heritage ko ni ipenija ara nitori oun ṣe ere idaraya loore-koore, ti gbogbo eniyan si mọ pe o ma n gba ere idaraya Golf.

''O ti lẹ ṣẹṣẹ gba Golf tan lo ni ki wọn ba oun mu suya , ko to di pe o fo sanlẹ ku.''

''Mo tilẹ gbọ wi pe o kesi iyawo rẹ keji , Bimbo Oshin wa si ile ere idaraya Golf lati wa pade rẹ, amọ o ni ki Bimbo ma ṣeyọnu nitori oun ni ipade pẹlu ẹnikan ni aago mẹjọ.''

''Ibẹ lo wa ti o ti daku, to si gba ibẹ lọ amọ ki la fẹ ba Ọlọrun fa''

''O ti le ni ọdun mẹrindinlọgbọn ti emi ati Dudu Heritage ti jẹ ọrẹ fun ọdun mẹrindinlọgbọn. ''

''Orilẹede Amẹrika ni a ti pade, lati igba naa ni o si ti jẹ ibatan rere si mi, ti a si ọrọ nipa iṣẹ orin kikọ mi, ti oun naa si sọ pe oun yoo bẹrẹ si ni gbe awo orin jade.''

Bakan naa lo sọ wi pe oun yoo ma ṣeranwọ fun awọn oṣere ti wọn ṣẹṣẹ bẹrẹ ni agbo oṣere.

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

''Dudu Heritage ni o gbe awo orin Sola Allyson jade, to si ni igbagbọ ninu rẹ''

Oberese ni igba ti mo pade rẹ ni mo gbe awo orin mi jade, Overflow, ti awo naa si ta kaakiri agbaye lati ọdun 1999 titi di oni.

''Lẹyin naa ni mo gbe aawo orin American Faaji 1&2, ti ko si si igba kankan ti ko fẹran mi denu denu.''

Obesere fikun un pe Dudu Heritage fẹran rẹ dẹnudẹnu to si ri pe oun jẹ eniyan laye.

O ni ninu aawo orin tuntun ti oun ṣe lọwọ, ni oun yoo ti sọrọ ribiribi nipa igbeaye Dudu Heritage.

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan