Kwara Abduction: Taiwo àti Kehinde pẹlú awakọ̀, ọlọ́pàá àti ọmọ ọ̀dọ̀ oríàdé bọ́ sọ́wọ́ ajínigbé

Awọn gende agbebọn

Oríṣun àwòrán, NPF

Gende agbebọn ti ji eeyan marun to jẹ ẹbi ati osisẹ ọba alaye kan, Olobbo tilu Obbo-Aiyegunlẹ to wa nipinlẹ Kwara.

Lara awọn eeyan marun ti wọn ji gbe naa la ti ri ibeji kabiyesi, Taiwo ati Kehinde ti wọn jẹ ọmọ ọdun mẹfa pẹlu osisẹ alaabo ọba alaye naa to n jẹ Lawrence Abiodun.

Bakan naa ni wọn tun gbe awakọ Kabiyesi lọ to n jẹ Kunle ati ọmọ ọdọ oriade naa, ti wọn pe orukọ rẹ ni Bukunmi Akanbi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n fidi isẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara,Okasami Ajayi sọ fun iwe iroyin Daily Post pe awọn eeyan naa lo n rinrin ajo bọ lati ilu Osi pada lọ si Obbo-Aiyegunle.

Owalobo funra rẹ, Oba Samuel Adelodun, gan gan si lo funra rẹ lo fi isẹlẹ naa, to waye ni deede aago mẹfa abọ irọlẹ ọjọbọ to awọn ọlọpaa leti.

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

Okasanmi ni ọkọ Toyota Sienna oriade naa, ti wọn kọ Owalobo tilu Obbo-Aiyegunle si lara, to n gbe awọn eeyan naa pada bọ sile, ni wọn ri lẹba ọna nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

"Ni kete ti iroyin naa tẹ wa lọwọ ni Kọmisana ọlọpa nipinlẹ Kwara, Amienbo Tuesday Assayomo, fọn awọn osisẹ ọlọpaa to n dena ijinigbe atawọn ọdẹ ibilẹ lọ si agbegbe naa.

Awọn eeyan yii lo pasẹ fun lati se awari awọn ajinigbe naa, ki wọn si doola ẹmi awọn eeyan ti wọn ji gbe pẹlu."

Kọmisana ọlọpaa naa tun wa rọ awọn araalu to ba kofiri awọn ajinigbe naa tabi mọ ohunkohun nipa wọn lati tete fi to ọlọpaa leti.

O si tun rọ awọn araalu lati maa da nikan rin ni awọn oju popo to da ni asalẹ.

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan