Kongsberg Bow and Arrow Attack: èèyàn márún ún gbẹ́mì mì nínú ìkọlu ófà àti ọrún

Armed police on the streets of Kongsberg after an attacker opened fire on people with a bow and arrow

Oríṣun àwòrán, Hakon Mosvold/NTB/via Reuters

Àkọlé àwòrán, Police have cordoned off large parts of the town

O kere tan ẹmi obinrin mẹrin ati ọkunrin kan ti ba iṣẹlẹ ikọlu ọrun ati ọfa lọ ni orilẹede Norway.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni nkan bi ọwọ irọlẹ ni agbegbe Kongsberg, ni orilẹede naa.

Gẹgẹ bi ọrọ awọn ọlọpaa arakunrin naa wa lati iha North Germany, ti ọjọ ori rẹ ko si ju ẹni ọdun metadinlogoji lọ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni inu ọja ti awọn eniyan ti n ra nkan ni iṣẹlẹ naa ti waye, ti ọlọpaa si pẹlu awọn meji to farapa ninu iṣẹlẹ naa.

Ẹnikan to wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ naa ni oun ri ti rogbodiyan bẹ silẹ, ti obinrin kan sapamọ, ti ọkunrin kan si duro si ẹgbẹ kan pẹlu ọrun si ejika rẹ, to si gbe ọfa si ọwọ rẹ.

Lẹyin naa ni wọn ri awọn eniyan ti wọn bẹrẹ si ni sa asala fun ẹmi wọn, to fi mọ arabinrin kan to gbe ọmọ kekere dani, to si n sa asala fun ẹmi rẹ.

Wọn fikun pe arakunrin afurasi naa lo awọn ohun elo ija miran yatọ si ọfa ati ọrun, amọ awọn ọlọpaa ko sọ ju bẹẹ lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti kọkọ mu ọkunrin naa fun ifọrọwanilẹnuwo lẹyin to darapọ mọ ẹsin Islam.

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

Bakan naa ni wọn fikun pe awọn ti wọn ku ninu ikọlu naa jẹ eni aadọta si aadọrin ọdun.

Ọpọlọpọ eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa to fi mọ Olotu Ijọba orilẹede naa ti yoo fi ipo silẹ laipẹ, ti olori eto idajọ miran yoo si tun gba ipọ bakan naa.

Agbẹjọro afurasi apaniyan naa ni o wa ni panpẹ ọlọpaa, ti wọn si ti bẹrẹ ifọrọwanilẹnuwo lori iṣẹlẹ naa, lati le fi idi rẹ mulẹ boya iṣe igbesunmọmi ni.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni afurasi naa lọ si agbegbe to pọ, ti wọn si ti ya awọn agbegbe naa sọtọ pẹlu aṣẹ ki awọn eniyan joko si ile titi iwadii yoo fi pari.

Igba ti iṣẹlẹ igbesunmọmi iru rẹ ti ṣẹlẹ ri ni ọdun 2011, lẹyin ti ọkunrin alakatakiti kan pa eniyan mẹtadinlọgọrin, ti ọpọlọpọ si jẹ ọmọde nibi ti wọn ti n ṣe ayẹyẹ ni agbegbe Uloya, lorilẹede naa.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́