Nigerian army: Agbésùmọ̀mí 13,000 ló jọ̀wọ́ ara wọn fún ìjọba láàrín ọ̀sẹ̀ méjí

Nigerian Army

Oríṣun àwòrán, HQ Nigerian Army

Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun mẹtala ọmọ ẹgbẹ agbesumọmi to ti jọwọ ara wọn fun ijọba apapọ laarin ọsẹ meji sẹyin.

Aṣoju alukoro ileeṣẹ ọmọ ogun, Bernard Onyeuko lo fi ọrọ naa lede nibi to ti sọ pe awọn mọlẹbi awọn agbesunmọmi naa wa lara awọn eeyan ọhun, to fi mọ awọn iyawo atawọ ọmọ wọn.

O ni awọn ṣekupa mọkandinlọgbọn lara awọn agbesumọmi naa, nigba ti wọn fi ṣikun ofin mu mẹtala ninu wọn.

Onyeuko ni "Akitiyan awọn ọmọ ogun ori ilẹ ati oju ofurufu ni iha Ariwa ila-oorun Naijiria ti so eso rere, adinkun si ti ba bi awọn agbesunmọ ni ṣe n kọlu awọn Naijiria."

"Laarin asiko ti a n sọrọ rẹ yii, pupọ ninu awọn agbesumọmi naa ni a ti ran lọ si ọrun aremabọ, ti a si ti fi ṣikun ofin mu ọpọ, to fi mo awọn to n ṣe agbodega fun wọn."

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

Ileeṣẹ ọmọ ogun sọ siwaju si pe eredi ree ti ọpọ ninu awọn eeyan ọhun ṣe n jọwọ ara wọn fun ijọba apapọ.

O ni "Eyi lo fa ti wọn fi jọwọ ara wọn fun ijọba ti wọn si n ko awọn ohun ija wọn silẹ tawọn ti ẹbi wọn lẹyin ti wọn ri pe ija naa kii ṣe eyii ti wọn le bori.

Lẹyin naa lo ke si awọn ọmọ Naijiria lati ṣatilẹyin fun ileeṣẹ ọmọ ogun ki ọrọ igbesumọmi le di ohun igbagbe ni Naijiria.