Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìjà ńlá tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Oyo

Ọkọ̀ tí gíláàsì ẹ̀yìn rẹ̀ ti fọ́
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ija ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo tun ti gba ọna miran yọ pẹlu bii awọn afurasi janduku ṣe kọju ija si awọn alatilẹyin igun minisita fun oluilu orile-ede Naijiria iyẹn Nyesom Wike eyi ti ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Oyo, Amofin Gbolarunmi Hazeem ko sodi nipinlẹ Oyo.

‎‎Ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Keje, oṣu Kẹta ọdun 2026 ni awọn afurasi janduku oloṣelu yawọ ile igbakeji gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ ri naa to wa ni agbegbe Asi, Bodija, nibi ti wọn ti ba ọpọ ọkọ jẹ tawọn eeyan si tun farapa.

Igbesẹ yii lo n waye bi awọn igun Wike ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fẹ yan awọn adari tuntun fun ẹgbẹ naa.

‎BBC News Yoruba ri gbo wi pe awọn dukia ẹgbẹlẹgbẹ milionu lawọn janduku ọhun bajẹ, ti eniyan ti ko din ni mẹwaa si fi ara pa nibi ikọlu ọhun.

'Àwọn ọmọ òní moto àti àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ ní wọn lo láti bàa eto wá jẹ́'

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Gbolarunmi ṣalaye wi pe, lootọ igun meji lọ wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP sugbọn igun ti ohun n ṣoju ni ijọba apapọ ati ajọ INEC damo gẹgẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ ogidi.

‎‎O sọ pe atunto ti ajọ INEC rọ ẹgbẹ oṣelu PDP lati ṣe ni awọn gunle lati yan awọn adari ẹgbẹ oṣelu naa fun awọn ijọba ibilẹ mẹtalelọgbon to wa ni Ipinlẹ Oyo ki ikọlu naa to waye.

‎‎Gbolarunmi tesiwaju wi pe "ko pẹ ko jina ni mo n gba ipe wi pe wọn ti gbe aṣoju wa ni ijọba ibilẹ Ariwa Ogbomoso wọn lọ de mọlẹ, bakan naa ni mo tun gba ipe lati Ariwa Ibarapa, aarin gungun Ibarapa, Igangan, Ijọba ibilẹ Kajola, ijoba ibilẹ Itesiwaju ati bẹẹ bẹẹ lọ, koda wọn ṣa awọn kan lada ni Igangan, ti awọn afurasi janduku tun fi nnkan ija oloro lewọn kiri.

‎"Ṣadede ni awọn kan tiwọn gbe ọkọ elero to to marundinlogun ile mi ti wọn si ba ọpọ dukia jẹ gbogbo fanran wọn la ni lọwọ."

O fẹsun kan pe oun ni gbagbọ pe awọn igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Gomina Ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde n ko sodi lọ ran awọn janduku naa.

O ni oun gbagbọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu ikọlu naa lo maa foju wina ofin nigba awọn agbofinro ba bẹrẹ iṣẹ wọn ti ọwọ si tẹ awọn to ṣiṣẹ laabi naa.

"Emi ro wi pe oṣelu kii ṣe bo o ba o pa, bo o ba ko bu u lẹsẹ, gẹgẹ bi amofin mo mọ ohun to yẹ ki n ṣe, mi o fẹ ki a da ilu ru ki awọn ara ilu ma sọ wa lorukọ, sugbọn o ku wọn o ku Ọlọrun.

‎‎"Ija igboro laisan Ibadan loooto sugbọn igbese ti Makinde gbe yii ko tọna, ti Makinde ba jẹ ọmọ bibi Ibadan loootọ ko yẹ ko gbe igbese ti wọn gbe yẹn, mọ mọ wi pe Ọlọrun yoo mu wọn."

Ìwé tí igun Wike wọ́n fi kéde láti ṣe ìpàdé àti ètò ìdìbò ní ìpínlẹ̀ Oyo

'Wọ́n dúnkokò mọ́ mi, kódà wọ́n lérí láti pa mí'

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Ọmọọba Diran Odeyemi, ẹni ti o dari ibo abẹlẹ igun kan ti ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ọrọ tirẹ sọ pe gbogbo awọn ẹsọ alaabo ilu ni awọn kọwe si ati ajọ INEC ṣaaju ki awọn to ṣeto lati yan awọn adari tuntun fun ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo.

‎‎Odeyemi to ti figba kan ri jẹ igbakeji agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP lorilẹ ede Naijiria ṣalaye pe awọn ṣe eto idibo ẹgbẹ oṣelu naa bo tilẹ jẹ pe awọn kan gbiyanju lati daaru.

‎"Eto idibo ta a ṣe lọ wọrọwọ, ko pe ko jina lagbọ wi pe awọn afurasi janduku kan to to igba yabo ile Gbolarunmi ti wọn si ba awọn dukia rẹ jẹ.

‎‎"Awa marun-un ni wọn fun laṣẹ lati dari eto idibo náà, koda wọn lọ kaakiri awọn hoteli to wa ni agbegbe Bodija nipinlẹ Oyo lati wa awọn akegbe mii ti wọn wa lati ṣe amojuto eto naa, ti wọn si leri lati ṣe wọn leṣe ti ọwọ ba tẹwọn sugbọn Ọlọrun ko jẹ ki wọn rí wọn.

‎‎"Mọ tun ṣe akiyesi awọn ọkọ ayọkele meji kan tí wọn tẹlemi, mọ ti ní nomba wọn lọwọ ma si fi to awọn agbofinro leti, koda wọn pemi lori ẹrọ ibanisọrọ mi won ni awọn maa pa olodi wọn laise emi, sugbọn Ọlọrun ko fi ẹ̀mí mi le wọn lọwọ."

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti kan sawọn ẹṣọ aabo lati da aabo bo awọn ọmọ ẹgbẹ wọn.

Àwa ò mọ ohunkóhu nípa rẹ̀, àwọn tí wọ́n kọ̀ làti fún lowo lo ba dúkìá wón jẹ́

Micheal Ogunsina wọ aṣọ olomi aro, o n sọrọ

‎Ẹwẹ, agbẹnusọ igun ẹgbẹ oṣelu PDP ti Seyi Makinde nipinlẹ Oyo, Micheal Ogunsina ti wa sọ afọmọ rẹ pe awọn lọwọ ninu ikọlu to waye sawọn igun keji naa.

Ogunsina ṣalaye wi pe irọ to jina si ootọ ni pe awọn ran awọn janduku lati lọ da eto kankan ru.

‎O woye pe ẹgbẹ oṣelu PDP ko pin si igun kankan nitori pe Wike kii ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa mọ.

‎‎Micheal tẹmpẹlẹmọ pe iru iṣẹlẹ yii ko waye ri lati odun 2019 ti Gomina Makinde ti di gomina ipinlẹ Oyo nitori oṣelu Ipinlẹ Oyo ti fopin si iwa bo o ba o pa, bo o ba ko bu lẹsẹ, oṣelu ipinlẹ Oyo ti gba alaafia laaye ati pe Seyi Makinde ko ni janduku tabi odaran kankan ti o n tẹle.

‎‎"Nigba ti a gbọ pe wahala sẹlẹ, a ṣe iwadii a si ri wi pe ẹnikan to ti di ipo oṣelu mu ninu ẹgbẹ wa lo pe awọn kan si ipade, awọn ti wọn kọ lati fun ni owo ni wọn lẹ okuta mọ ile wọn.

‎"Ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ko mọ nnkankan nipa iṣẹlẹ naa, ẹnikan to ran awọn eniyan niṣẹ ti ko san owo wọn lọ fa iṣẹlẹ naa.

‎"Eeyan daadaa ni Gomina Seyi Makinde, nitori ko ni nkankan ṣe pẹlu awọn iṣẹlẹ naa, awọn agbofinro ti n ṣe iṣẹ wọn lori iṣẹlẹ naa, awọn to ba si jẹbi ni wọn maa fi imu wọn danri."