Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn dájọ́ lórí ẹ̀tọ́ Aiyedatiwa láti dupò gómìnà Ondo fún sáà míì

Oríṣun àwòrán, Lucky Aiyedatiwa/Facebook
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ìlú Abuja ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ pé gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, Lucky Aiyedatiwa kò ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà níbi ètò ìdìbò tó ń bọ̀.
Ṣáájú ni ilé ẹjọ́ gíga tó fi ibùjókòó sí ilú Akure, lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kọkànlá, ọdún 2025 ti kọ́kọ́ dájọ́ pé Aiyedatiwa kò lè dupò gómìnà ìpínlẹ̀ náà ṣùgbọ́n tí gómìnà pe ìdájọ́ náà ní ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn.
Nínú ìdájọ́ tí àwọn adájọ́ mẹ́ta fẹnukò gbé kalẹ̀ sọ pé ilé ẹjọ́ gíga náà ṣe ohun tó tọ́ nípa fífi ààyè gba Akindele Egbuwalot ó pe ẹjọ́ láàyè láti ṣe àtúnṣe sí ẹjọ́ tó pè.
Adájọ́ Uchechukwu Onyemenam tó ka ìdájọ́ náà síta sọ pé Aiyedatiwa kò fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ẹjọ́ tó pè pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga jẹ́ títẹ ẹ̀tọ́ ohun mọ́lẹ̀ tàbí pé wọn kò fààyè gba òun láti ṣàlàyé ara òun.
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà wá da ẹjọ́ náà nù, tí wọ́n sì ní kí gómìnà san owó ìtanràn mílíọ̀nù méjì náírà fún ilé ẹjọ́ lórí ẹjọ́ tó gbé síwájú àwọn.
Ṣáájú ni ilé ẹjọ́ náà ti kọ́kọ́ da ẹjọ́ tí Gómìnà Aiyedatiwa pè láti láti da àṣẹ ti ilé ẹjọ́ náà pa lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní pè kí gbogbo ìgbẹ́jọ́ tó wà ní ilé ẹjọ́ gíga ìjọba àpapọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà jẹ́ ìdádúró fún ìgbà kan ná.
Ilé ẹjọ́ ní àṣẹ náà jẹ́ ohun tó tọ́ lábẹ́ òfin fún wọn láti ṣe láti dá ààbò bo àwọn ìgbẹ́jọ́ tó wà níwájú rẹ̀.
Wọ́n wòye pé àsìkò tí àṣẹ náà fi máa jáde, wọ́n ti ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ti Aiyedatiwa pè, tí wọ́n sì ṣe ohun tó tọ́ láti rip é ìgbẹ́jọ́ tó wà níwájú wọn kò di ohun àtẹ̀mẹ́rẹ̀.
Ilé ẹjọ́ ní bí Aiyedatiwa ṣe ni kí àwọn da àṣẹ tí àwọn pa lọ́jọ́ Kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kìíní náà nù túmọ̀ sí pé ó ní kí àwọn kó ọ̀rọ̀ àwọn jẹ ni.
Wọ́nn ní ìgbésẹ̀ tó yẹ fún Aiyedatiwa láti gbé ni kó pe ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà, ìyẹn Supreme Court.
Bákan náà ni wọ́n tún ní kó san owó ìtanràn mílíọ̀nù kan náírà fún bí ó ṣe ní kí àwọn gbé ìdájọ́ tí àwọn ti gbé sílẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan.

























