Wọ́n bá òkú ọmọbìnrin kan lẹ́nu ọ̀nà ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Obìnrin kan tó dúró, kọ ẹ̀gbẹ́ sí ayàwòrán, aṣọ kan wà nílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti ṣàwárí òkú ọmọbìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Precious Mogaji ní ẹnu ọ̀nà ilé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ní agbègbè Ojoo, ìjọba ìbílẹ̀ Akinyele, ìpínlẹ̀ náà.

Ìròyìn ní wọ́n fura pé ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ọ̀hún, ẹni tó tin a pápá bora báyìí ló ṣekúpa Precious.

Agbẹnusọ ọlapàá Oyo, Ayanlade Olayinka nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde sọ pé Quadri Mohammed ni orúkọ ọ̀rẹ́kùnrin tí wọ́n fura pé ó ṣekúpa Precious.

Ó fi kun pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣokùnfà ikú ọmọbìnrin náà.

Ó ṣàlàyé pé èèyàn kan tó rí òkú ọmọbìnrin náà ní ẹnu ọ̀nà ilé ọ̀rẹ́kùnrin obìnrin náà ló lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá létí.

Àtẹ̀jáde náà ní Quadri Mohammed ni ìgbàgbọ́ wà pé ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nígbà tí Preciou Mogaji sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n.

Ó ní ìwádìí fi hàn pé nǹkan bíi aago márùn-ún ni ará àdúgbò kan tó rí òkú Precious lẹ́nu ọ̀nà ké gbàǹjarè lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.

Ó fi kun pé lòdì sí ìròyìn tó gba orí ayélujára pé ní agbègbè Akobo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé àti pé ọkọ kan ń gbìyànjú láti gbé òkú ìyàwó rẹ̀ sẹ́yìn ọkọ̀ kan, ó ní agbègbè Oguntula bí Ojoo, Ibadan ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé kìí ṣe Akobo.

Ayanlade sọ pé ó pọn dandan láti ṣe àfọ́mọ́ ọ̀rọ̀ náà, tí àwọn ọlọ́pàá sì tètè lọ síbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní kété tí ìròyìn náà tit ó wọn létí.

"Nígbà tí àwọn ọlọ́pàá débi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n bá òkú Precious nílẹ̀ níbi ẹnu ọ̀nà afurasí náà. A bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò lórí òkú rẹ̀, tí a sì ti ṣe àkọ́lẹ̀ gbogbo àwọn nǹkan tí a rí gẹ́gẹ́ bí òfin ṣe là á kalẹ̀."

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí mọ́ṣúári fún àyẹ̀wò láti mọ ohun tó pa á gangan.

Ó fi kun pé ìwádìí ti ń lọ láti fi poro òfin gbé Quadri lẹ́yìn tó ti fẹsẹ̀ fẹ.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá wá rọ ẹnikẹ́ni tó bá ní ìmọ̀ lórí ohun tó le ṣe ìrànwọ́ fún ìwádìí wón lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láti kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá tó bá sún mọ́ wọn tàbí kí wọ́n lọ sí oríko iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo.

Bákan náà ló sọ àrídájú rẹ̀ pé gbogbo bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà bá ṣe ń lọ lórí ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni àwọn yóò máa fi tó àwọn aráàlú létí, tó sì gba àwọn aráàlú lámọ̀ràn láti yé tẹ̀lé àwọn ìròyìn òfégè tó ń lọ lórí ayélujára.