Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí ọ̀daràn 99 ní ìpínlẹ̀ Ondo

Àwọn agbébọn tó gbé ìbọn kọrun

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Agbarijọpọ awọn esọ aabo nipinlẹ Ondo ti fi panpẹ ọba mu awọn afurasi mọkandinlọgọrun-un (99) ti wọn lọwọ ninu awọn okan-o-jọkan iwa ọdaran kaakiri ipinlẹ naa.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh fi lede ni ilu Akure ti n ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo sọ pe Ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹta ọdun 2026 ni awọn ẹṣọ aabo ṣe iṣẹ naa lati daabo bo dukia ati ẹmi awọn ara ilu.

Jimoh sọ pe agbarijọpọ awọn ẹṣọ aabo to fi mọ ileeṣẹ ọlọpaa, awọn ologun, ajọ aabo ara ẹni laabo ilu, awọn otelemuye ati ajọ Amọtẹkun ni wọn jọ ṣe iṣẹ naa.

O sọ pe iṣẹ iwadii ati itọpinpin lo ṣagbatẹru bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi ọdaran naa, bi wọn ṣe lọ sawọn oriko ti wọn n fara pamọ si kaakiri ipinlẹ Ondo lati fi poro ofin gbe wọn.

O fi kun pe awọn 99 tí wọn mu naa lọwọ ninu awọn iwa ọdaran to fi mọ idigunjale, ṣiṣe ẹgbẹ okunkun, ile fifọ ati awọn iwa miran tó tako ofin.

Agbẹnusọ ọlọpaa tun sọ pe wọn ri ọpọ dukia gba pada eyi to jẹ awọn ẹru ti wọn ji lọwọ awọn eniyan, ati awọn ohun elo tí wọn fi ń sọsẹ naa.

O tẹsiwaju pe iwadii n lọwọ lori awọn ti wọn mu naa, ti wọn yoo si foju bale ẹjọ ni kete ti iwadii wọn ba ti pari.

Kọmiṣanna Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Adebowale Lawal gboriyin fun gbogbo awọn esọ aabo to kopa ninu ikọlu si awọn oriko ti awọn afurasi naa fara pamọ si.

O sọ pe iru ibaṣepọ yii yoo ko ipa to lapere ninu gbigbogun ti iwa ọdaran nipinlẹ Ondo.

Lawal fi da gbogbo olugbe Ipinlẹ Ondo loju pe, gbogbo awọn esọ aabo yoo ri daju pe alaafia jọba nipinlẹ naa, ti gbogbo ijinigbe ati iwa ọdaran yoo si di ohun igbagbe.

O tun kilọ fawọn ọdaran lati so ewe agbejẹ mọwọ nitori ilu o ni fararọ fun wọn mọ bí awọn esọ aabo yoo ṣe bẹrẹ si ni ṣe ikọlu si wọn loorekoore lati le fopin si iṣẹ wọn, ki awọn ara ilu le gbe igbe aye wọn lai si ibẹru.

O wa rọ awọn ara ilu lati maa fi iroyin ohun to n ṣẹlẹ ni ayika wọn to awọn agbofinro leti loorekoore nitori ifọwọsowọpọ wọn yoo ṣe iranwọ lati fopin si iwa ọdaran.