Àwọn agbébọn jí Ìmáàmù àti àwọn mẹ́rin míì gbé ní Kwara.

Aworan ọwọn kan ni ilu Babanla ni ipinlẹ Kwara.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn agbebọnja tun so ro bi agbọn lanaa ni ilu Babanla ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara gẹgẹ bi wọn ṣe ji Ìmámù ilu Babanla ati awọn mẹrin mii gbe lọ.

Iṣẹlẹ naa sẹlẹ lanaa ọjọ Aiku ọjọ kẹsan Osu Kẹta Ọdun yii ni nnkan bi ago mẹfa irọlẹ.

Ọkan lara awọn mọlẹbi awọn ti wọn ji gbe ọgbẹni Wasiu Suleiman sọ pe, awọn eeyan naa rin irin ajo lati ilu Oke Ọdẹ lọ si ilu Babanla lasiko ti iṣẹlẹ naa waye.

O fikun pe, awọn agbebọnja naa da wọn lọna ti wọn si ko gbogbo wọn wọ inu igbo lọ.

O salaye pe, lara awọn ti wọn ji gbe ni, Imamu agba ilu Babanla Alhaji Sarafadeen Abdulraheem, oṣiṣẹ eleto aabo kan ati ọmọ rẹ ọkunrin.

Lasiko toun ba aṣoju kọroyin ile iṣẹ wa BBC Yorùbá sọrọ laarọ oni ọjọ Aje, ọkan lara awọn ọmọ bibi ilu naa Arabinrin Jẹmilat Abdulkadir sọ pe, lootọ ni iṣẹlẹ naa.

O tẹsiwaju pe, ori Ọkada ni gbogbo wọn wa lasiko ti awọn agbebọnja da wọn lọna.

O ni wọn ti kọja Oke Ọdẹ ki iṣẹlẹ naa to ṣẹlẹ, pẹlu alaye pe awọn ẹṣọ aṣọgbo ma n duro ni oju ọna tẹlẹ, ṣugbọn wọn ni wọn o ri wọn lana

Kinni ohun to ṣẹlẹ tẹlẹ?

Agbegbe Babanla ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara jẹ ibi ti akọlu awọn agbebọnja ti n waye julọ ni ipinlẹ Kwara.

Ọpọ eeyan lawọn agbebọnja ti ji gbe lagbegbe naa.

Agbegbe yii lo kan awọn ilu bi Adanla, Agbeku, Ààfin ilere, Oreke ati bẹẹ bẹẹ lọ ti gbogbo rẹ wa ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ipinlẹ Kwara.

Lati bi ọdun melo kan sẹyin ni awọn eeyan agbegbe naa ti n foju wina akọlu awọn agbebọnja.

Ọpọ awọn agbẹ ni wọn o le lọ oko mọ, nitori iṣẹlẹ akọlu ati ijinigbe.

Lọdun to kọja ọpọ awọn eeyan agbegbe naa ni wọn sa kuro ni ilu naa latari bawọn ajinigbe ṣe n ṣe wọn bi ọsẹ se n soju.

Lọsẹ to kọja eeyan mẹrin ni wọn ji gbe ninu oko lasiko ti wọn wa ẹgẹ ti wọn o si ti yọnda wọn titi di asiko yii.

Igbesẹ wo ni ijọba ti gbe

Aworan agbebọn kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ Kwara ti gbe ọpọlọpọ igbesẹ lori iṣẹlẹ awọn agbebọnja naa.

Laipẹ yii ni ijọba ipinlẹ Kwara gba awọn ẹṣọ aṣọgbo to si pin wọn káàkiri lẹyin ti wọn pari idanilekọọ .

Bakan naa ijọba apapọ fi awọn ọmọ ogun sọwọ si ipinlẹ Kwara laipẹ yii ti awọn ọmọ ogun naa si kọlu ibuba awọn agbesunmọmi ni Baba Sango ijọba ibilẹ Ifẹlodun.

Awọn ara ilu naa ni inu ibẹrubojo lawọn wa lagbegbe naa bayi pẹlu arọwa si ijọba lati ran wọn lọwọ.

Titi ti aṣoju kọroyin ile iṣẹ wa fi ko iroyin yii jọ alukoro ajọ ọlọpaa ipinlẹ Kwara,Ejirẹ Adeyemi Toun ko ti sọrọ lori iṣẹlẹ naa.