Afurasí tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì ìlú Owo ṣàlàyé bí ọwọ́ DSS ṣe tẹ̀ ẹ́

Ile ijọsin St. Francis Catholic Church, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo
Àkọlé àwòrán, ile ijọsin St. Francis Catholic Church, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo ti iṣẹlẹnaa ti waye
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn afurasi marun un ti ọwọ tẹ lori ifẹmiṣofo ile ijọsin St. Francis Catholic Church, to wa niluu Owo, nipinlẹ Ondo, Abdulmalik Omeiza, ti ṣalaye bi ọwọ ajọ DSS ṣe tẹ ẹ.

Nnkan bii eeyan mọkanlelogoji ni wọn padanu ẹmi wọn ninu ikọlu naa to waye lọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lasiko ti eeyan bii 140 ti n jọsin.

Ṣaaju ni DSS ti ke si ẹlẹri mọkanla lati fidi ẹjọ to pe awọn afurasi naa mulẹ eyii to bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025.

Ile ẹjọ naa gba ẹri ẹnu awọn afurasi ọhun ninu igbẹjọ to waye ninu igbẹjọ lati le fidi rẹ mulẹ pe kii ṣe ipa ni awọn ẹlẹri fi wa jẹri niwaju rẹ.

Awọn afurasi naa ti ọjọ oro wọn jẹ lati ogun ọdun si ọdun mẹtadinlaadọta ni Idris Abdulmalik Omeiza, Al Qasim Idris, Jamiu Abdulmalik, Abdulhaleem Idris ati Momoh Otuho Abubakar.

Nigba ti Omeiza n sọrọ, o ni nọọsi abẹ ile loun ṣaaju iṣẹlẹ naa.

Afurasi ọhun to sọrọ ni ede Ebira sọ fun ile ẹjọ pe ọjọ kinni, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 ni ọwọ tẹ oun ati ọdọkunrin meji mii, Hauwa ati Yusuf ninu ile kan naa.

O ni "Loru ọjọ ti wọn mu mi, mo maa n ji ni afẹmọju lati ka iwe mi. Nigba ti mo ji ti mo n kawe, mo wo aago, o si jẹ ogun iṣẹju kọja aago meji oru."

Ninu alaye rẹ to gun gbọọrọ, o ni ọọfisi DSS to wa niluu Lokoja, nipinlẹ Kogi loun ti pade afurasi karun un, Momoh Otuho Abubakar, ti DSS mu tẹlẹ.

Afurasi naa ṣalaye pe inu ahamọ kan ni wọn ko awọn mẹrin si ninu ọgba DSS Lokoja, nibẹ si ni wọn ti gba gbogbo alaye nipa wọn.

O ni ọjọ keji loun yan lati jẹ ki wọn gba ohun oun silẹ lori iṣẹlẹ naa ti oun si wa ni ahamọ titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 ti oun fi mọ pe wọn tun mu ẹgbọn oun pẹlu.

O sọ fun ile ẹjọ naa siwaju si pe lọjọ ti wọn ko awọn lọ si ipinlẹ Ondo, DSS ko sọ nnkankan nipa ikọlu ilu Owo, jijẹ ọmọ ẹgbẹ ISWAP tabi ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi mii.

Nigba ti wọn de ọgba DSS ipinlẹ Ondo, o ni inu yara kan naa ni wọn ti oun ati ẹgbọn oun mọ ti wọn si n fi ọrọ wa awọn mejeji lẹnu wo nipa ikọlu ilu Owo.

Wayi o, ile ẹjọ ti sun igbẹjọ naa si ọla, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 2025 fun itẹsiwaju rẹ.