Báyìí ni ogún Iran ṣe ń ṣe àkóbá fún àwọn tó fẹ́ rìn ìrìnàjò ilẹ̀ mímọ

Ka'aba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti wọn ma n ṣe Umrah ni orilẹede Saudi Arabia lasiko oṣu Ramadan n koju ainidaniloju lori bawo ni ogun to n lọ laarin Israeli ati Amẹrika si Iran ṣe le ni ipa lori irin-ajo wọn.

Ogun to n lọ lọwọ ti jẹ ki ọpọ awọn alaṣẹ dena de irin-ajo oju ofurufu ni awọn apa orilẹ-ede aarin Ila-oorun, ti o si n ṣe akoba fun awọn ile-iṣẹ irin-ajo ati awọn arin ajo Umrah.

Ọpọ awọn Musulumi lo ma n kopa ninu irin-ajo Umrah ni Saudi Arabia lakoko Ramadan, ti o si le eeyan miliọnu 122 lo ṣe irinajo lọ si ilẹ mimọ ni ọdun 2025 nikan, gẹgẹ bii ẹka isiro ṣe gbe sita.

Sugbon rogbodiyan to n lo lowo ni Aarin Ila-oorun, eyi to mu ki won tii pa awon papa-ofurufu pataki ti won n lo fun awon aririn ajo, ti mu ki awon omo Naijiria ti wọn ti pinnu lati se Umrah ma ṣe iye meji.

Iran, Iraq, Israel, Syria, Kuwait, Qatar, ati United Arab Emirates ti kede pe awọn titi awọn papa ofurufu wọn pa fun igba diẹ lẹyin Amẹrika ati Israeli ṣe ifilọlẹ jiju awọn ado oloro si Iran.

Bakan naaa ni ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti ni awọn arin irinajo to fẹ lọ si orilẹede Isreal bayii ko le ni anfani lati gbe igbesẹ naa nitori ogun to n lọwọ

Ẹgbẹ to n ri si Irinajo yii fun awọn Kristẹni lorilẹede Naijiria NCPC lo kede eyi ninu atẹjade kan ti wọn sita lọjọ Isẹgun niluu Abuja, eyi ti akọwe ẹgbẹ naa, Stephen Adegbite buwọlu, to si jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa ṣe koko fun aabo awọn arin irinajo.

Adegbite tẹsiwaju pe igbesẹ ki n ṣe fun ẹka ijọba nikan, o jẹ aṣẹ ti awọn ileeṣẹ aladani gbọdọ tẹle lasiko yii.

O fikun pe ẹgbẹ n ṣe iwadii nipa ogun naa, to si rọ awọn Naijiria lati ma gba adura fun alaafia niluu Jerusalem.

N ko ti sọ ireti nu lori lilọ si Umrah

Alhaji Zaharaddeen Abubakar to jẹ ọkan lara awọn arinrin-ajo ti wọn n duro lati ṣe iṣẹ Umrah ni orilẹ-ede Saudi Arabia sọ fun BBC pe ibẹru ko bori oun rara pẹlu bii nnkan ṣe n lọ bayii pẹlu ogun Iran pẹlu Isreal ati Amẹrika.

"Eeyan ti o wa nibe (Saudi Arabia) ti pari ohun to balọ, ti yoo si pada, ti awon baalu won ba gbera." Alhaji Zaharaddeen so.

Alhaji Zaharaddeen Abubakar tun kesi awon alase ilu Saudi Arabia lati gbe igbese lati rii pe awon musulumi kaakiri agbaye ni aye lati se Umrah laisi wahala kankan.

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣaaju?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ijọba ilẹ Amẹrika ati orilẹede Israel lo pawọ pọ lati ju ado oloro si Iran.

Awọn aworan ti BBC foju ri ṣafihan bi eefin ṣe n ru laarin ilu Tehran, to jẹ olu ilu orilẹede Iran.

Lẹyin ikọlu naa ni Aarẹ Donald Trump sọ pe afojusun Washington ni lati dena ikọlu eyikeyi to le waye lati ọwọ Iran.

Minisiti eto abo Israel, Israel Katz ni tirẹ juwe ikọlu naa bii eyii to waye lati dena ikọlu ọjọ iwaju lati ọwọ Iran.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe ibugbamu meji ọtọtọ lo dun ni Teharan laarọ ọjọ Abamẹta ti eefin si n ru soke laarin ilu naa.

Ninu fidio kan to fi lede, Trump sọ pe "Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika ti bẹrẹ ikọlu si Iran.

"A maa ba gbogbo ado oloro misaili wọn jẹ, a si maa sọ ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe misailu di ẹdun arinlẹ.

"A maa pa gbogbo rẹ run patapata. A maa pa ileeṣẹ ọmọ ogun ori omi wọn run."

Trump tun sọ fun awọn ọmọ orilẹede Iran ọhun pe asiko ominira wọn ti to, o ṣi ṣeleri iku fun awọn ọmọ ogun wọn to ba n ṣe agidi, ati ileri iwalaaye fun awọn to ba ju ọwọ silẹ.