Àlàyé rèé lórí ìdí tí Amẹrika àti Israel fi ń kọlu Iran

Oríṣun àwòrán, Airbus DS 2026
- Author, Hafsa Khalil
- Author, David Gritten
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
Adari Iran, Ayatollah Ali Khamenei ti jade laye lẹyin ti ilẹ Amẹrika ati Israel pa ọwọ pọ ju ado oloro si orilẹede naa.
Aarẹ Amẹrika, Donald Trump ti rọ awọn ọmọk ogun Iran ki wọn ju ọwọ silẹ ki awọn eeyan orilẹede naa le gbena woju ijọba wọn.
Iran naa ti fesi fun Amẹrika nipa jiju ado oloro si awọ dukia Amẹrika to wa lagbegbe Middle East bii Israel, Bahrain, Kuwait, Qatar, United Arab Emirates ati Jordan.
Lana ọjọ Aiku, Israel sọ pe oun ti bẹrẹ ikọlu si aringbungbun ilu Tehran, to jẹ olu ilu orilẹede Iran.
Ohun ti a mọ nipa ikọlu to n waye laarin awọn orilẹede naa ree.
Ki ni idi ti Amẹrika ati Israel ṣe n kọju ija si Iran?
Trump ti sọ pe eredi ikọlu naa ko ṣẹyin pe Amẹrika ko fẹ ki Iran ni ohun ija oloro 'nuclear.'
O ni "A maa gbogbo misaili wọn jẹ, a si maa sọ di ẹdun arinlẹ" ninu fidio iṣẹju mẹjọ kan to fi lede laarọ ọjọ Abamẹta.
Trump tun kilọ fun awọn ọmọ ogun Iran pe ki wọn jọwọ awọn ohun ija wọn ti wọn ba fẹ wa laaye tabi ki wọn ṣe agidi ki wọ si koju iku ojiji.
Lẹyin naa lo rọ awọn ọmọ orilẹede ọhun pe ki wọn mura lati doju ijọba orilẹede wọn to da lori ẹsin bolẹ
Ogun to n lọ lọwọ yii, ti ijọba Amẹrika pe ni 'Operation Epic Fury' lo n waye lẹyin ti Trump dunkoko pe oun yoo gbe igbesẹ alagbara ti Iran ba kọ lati tọwọ bọ awọn adehun kan lori ohun elo nuclear rẹ naa.
Amọ Iran ti sọ lọpọ igba pe lootọ loun ni ohun elo nuclear amọ kii ṣe fun jagidijagan.
Ileeṣẹ ọmọ ogun Amẹrika ni oun fẹ doju ẹka ohun ija oloro Iran bolẹ patapata lati dena ikọlu ọjọ iwaju.
Ṣaaju ni olootu ijọba Israel ti sọ pe ikọlu ti oun ati Amẹrika ṣe si Iran ko ṣeyin didena ikọlu to le waye si awọn lati ọwọ Iran lọjọ iwaju.
Ki ni esi Iran bayii?
Iran ti lo ohun ija oloro lati kọlu awọn orilẹede to wa lẹyin Amẹrika lagbegbe Gulf lati igba ti iku adari rẹ ti waye.
Awọn ọmọ ogun Revolutionary Guard sọ pe awọn ti kọlu Tel Aviv to jẹ ile agbara Israel to fi mọ awọn ibi ti awọn ologun maa n wa ni Haifa ati ila oorun Jerusalem.
O kere tan, eeyan mẹsan an lo ti ku ni Israel lati ọjọ Aiku lẹyin ti ado oloro kọlu sinagọgu kan niluu Beit Shemesh, ti eeyan bii 450 si farapa nibẹ.
Ẹwẹ, lẹyin ago mejila oru ni ibudo ologun ilẹ Gẹẹsi to wa ni Cyprus ni awọn kan kọlu.
Lati ibẹrẹ ogun yii ni aṣoju ijọba Iran silẹ okere, Abba Arahhchi ti sọ pe jẹjẹ lawọn wa ki Israel ati Amẹrika to kọlu awọn.
O ni ileeṣẹ ọmọ ogun ilẹ naa ṣetan lati koju awọn atọhunrinwa to n kọlu awọn.
Iran ti fi ado oloro ṣọwọ si Qatar, Bahrain, Jordan ati Kuwait nibi ti awọn ọmọ ogun Israel wa.
Wọn tun tun ti kọlu Oman ati Saudi Arabia.
Eeyan mẹta padanu ẹmi wọn ni UAE bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe papakọ ofurufu ati ori omi ti pa, bẹẹ naa ni wọn tun kọlui Kuwait.
Ọmọ ogun Amẹrika mẹta lo ti padanu ẹmi wọn, nigba ti awọn marun un mii farapa loju ija, gẹgẹ bi ọrọ ti Pentagon sọ.
Ṣe o le rinrinajo lọ si agbegbe naa bayii?
Ẹgbẹgbẹrun ọkọ ofurufu to yẹ ko fo ni wọn ti wọgile bayii lagbegbe naa, eyii to farajọ bi awọn baalu ko ṣe le fo loju ofurufu lasiko Covid-19.
Wizz Air ti wọgile irinajo rẹ lọ ati kuro lagbegbe ọhun titi di ọjo keje oṣu Kẹta ni Israel, Dubai ati Abu Dhabi ni UAE,to fi mọ Amman ni Jordan,
Ọkọ ofurufu British Airways ti wọgile irinajo re si Tel Aviv ni Israel ati Bahrain titi di Ọjọru ọsẹ yii.
Ileeṣẹ ọkọ ofuruf Kuwait ni tirẹ ti kede pe oun ko ni tẹ Iran titi di asiko ti oun yoo kede.
Ọkọ baalu Emirates ko lọ bẹẹ ni ko kuro ni Dubai mọ, Lufthansa, Air India, Virgin Atlantic ati Turkish Airlines naa ti kede pe awọn ko ni fo lasiko yii.
Awọn orilẹede kan ni Middle East bii Iran ati Jordan ti gbe agadagodo si ẹnu ọna papakọ ofurufu wọn.
Robert Greenall ati BBC Persian fi kun iroyin yi.

























