Ọmọ bàbá onílé gún ayálégbé pa lórí èdè àyedè owó ilé

Aworan obinrin to dorikodo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ baba onile kan Kazeem Awe ti lu iya ọlọmọ kan, to jẹ ayalegbe Baba rẹ pa lori edeaiyede owo ile.

Arabinrin naa Deborah Adeleye ni ọgbẹni Awe gun yanayana to si jẹ ipe Ẹlẹdaa ki wọn to gbe de ile iwosan

Ọkọ obinrin naa, Matthew Adeleye ati ọmọ rẹ, Tunrayo Adeleye farapa ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si n gba itọju lọwọ.

Iṣẹlẹ naa to waye ni ilu Ore, nijọba ibilẹ Odigbo sọ gbogbo agbegbe naa sinu iyọnu nla.

Ki lo sẹlẹ gan?

Lasiko to n salaye bi iṣẹlẹ naa se waye, ọkọ obinrin ti wọn gun pa naa, Matthew Adeleye ẹni to wa lori idubulẹ ni ile iwosan salaye pe wọn fun ohun ati awọn ayalegbe miran ni iwe lati ko kuro ni ile naa.

O ni wọn mu iwe naa wa fun wọn pẹlu pe ko ti to akoko ti owo ile wọn yoo tan.

Gege bi Adeleye ṣe sọ, ọjọ kerinlelogun oṣu kẹta ọdun yi ni owo ile rẹ yoo pari, ti o si ti bẹrẹ igbesẹ lati ko kuro ni ile naa.

Adeleye sọ pe wọn ti ri ile miran ti wọn si ti n gbe igbesẹ lati ko lọ ile naa.

‎O salaye pe ni owurọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ọmọ baba onile naa kan ilẹkun ile wọn, ti ohun si n se igbọnsẹ lasiko náà, sugbọn ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbe ile si ilẹkun fun ọmọ baba onile naa.

Adeleye sọ pe kete ti okunrin naa wọ ile, lo bẹrẹ si ni lu iyawo ohun ni alubami, O salaye pe iyawo rẹ ke pe ọmọ baba onile naa ti fi ọbẹ gun ohun.

O salaye pe kete ti ohun wọle, ohun gbiyanju lati gba iyawo rẹ lọwọ okunrin naa, sugbọn o gun ohun naa lọbẹ lọwọ, ẹsẹ ati ẹyin. Bakanna ni ọmọ baba onile naa tun gun akọbi wọn Tunrayo Adeleye ni ọbẹ ni ọrun ọwọ.

Adeleye sọ pe awọn aladugbo lo gbe ohun, aya ati ọmọ lọ ile iwosan sugbọn awọn Dokita sọ pe iyawo ìyẹn Deborah Adeleye ti jẹ ipe Ẹlẹdaa ki wọn to gbe de ile iwosan.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ nipa iṣẹlẹ naa?

Ileeṣẹ Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo sọ pe wọn ti fi panpẹ ọba mu ọmọ baba onile naa, Kazeem Awe lẹyin to gun ayalegbe ile baba rẹ ni ọbẹ pa.

Alukoro Ọlọpaa Ipinlẹ Ondo Jimoh Abayomi ẹni to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ salaye pe afunrasi naa se ikọlu si awọn mẹta ti wọn jẹ ayalegbe ni ile baba rẹ, ti o si gun wọn ni ọbẹ yanayana.

Abayomi sọ pe Deborah Adeleye ẹni ọgbọn ọdun to jẹ iya ọlọmọ ni wọn kede pe o ti jẹ ipe Ẹlẹda kete ti wọn gbe de ile iwosan, ti ọkọ rẹ ati ọmọ rẹ si n gba iwosan lọwọ ni ile iwosan gbogbogboo tilu Ore.

Ileeṣẹ Ọlọpaa sọ pe iṣẹlẹ naa waye nitori edeaiyede laarin onile naa ati awọn ayalegbe. Wọn wa rọ awọn onile ati awọn ayalegbe lati maa yan alaafia laayo lasiko ti edeaiyede ba ti waye.

Ogbeni Jimoh Abayomi sọ pe ileeṣẹ Ọlọpaa yoo ri daju pe wọn gbe igbese to yẹ lẹyin ti wọn ba pari iwadi wọn.