Ẹ tú ọmọ Naijiria 42 tí ẹ jù sátìmọ́lé sílẹ̀ ní Mozambique, Dabiri-Erewa ké gbàjarè

Oríṣun àwòrán, NIDCOM/X
Alaga ajọ NIDCOM to n ri si ọrọ awọn ọmo Naijiria to wa nilẹ okeere, Abike Dabiri-Erewa, ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn agbofinro ṣe fọwọ ofin mu ọmọ Naijiria mejilelogoji lorilẹede Mozambique.
Arabinrin Dabiri-Erewa ṣapejuwe bi wọn ṣe ju awọn ọmọ Naijiria naa si atimọle gẹgẹ bi nnkan to n kọ oun lominu.
Dabiri-Erewa wa kepe awọn alaṣẹ orilẹede Mozambique lati tu awọn ọmọ Naijiria naa silẹ ni kiakia.
''Bi wọn ṣe mawọn ọmọ Naijiria mejilelogoji ni Mozambique lai fẹsun kankan kan wọn n kọ mi lominu.
Mo wa fi asiko yii kepe awọn alaṣẹ orilẹede Mozambique wi pe ki wọn paṣẹ itusilẹ awọn ọmọ Naijiria naa, tabi ki wọn gbe wọn lọ sile ẹjọ ni ibamu pẹlu ofin ilẹ naa.
Gẹgẹ bi atẹjade ti ajọ NIDCOM fi sita ṣe ṣalaye, ninu ọja ni wọn ti mawọn ọmọ Naijiria mejilelogoji naa ni Mozambique lai sọ nnkan ti wọn ṣe ti wọn fi dero atimọle.
Ninu ọja ti wọn ti n ta ẹya ara ọkọ ni wọn ti mawọn ọmọ Naijiria ọhun tawọn kan sọ pe ọna aitọ ni wọn fi n gbe ni Mozambique.
Ajọ NIDCOM ko darukọ awọn ọmọ Naijiria mejilelogoji naa ati ọja ti wọn ti mu wọn.
Ajọ naa sọ pe iroyin to tẹ awọn lọwọ fidi rẹ mulẹ pe wọn fiya jẹ awọn ọmọ Naijiria naa, wọn si tun ji awọn nnkan gbe.
Bakan naa ni NIDCOM ni ara wọn ko ya, wọn si nilo ki wọn lọ si ile iwosan.
Dabiri-Erewa sọ pe bi wọn ṣe mawọn ọmọ Naijiria naa tumọ si pe wọn yan wọn ṣọju lorilẹede Mozambique.
Alaga NIDCOM ni ''ẹ gbe wọn lọ si ile ẹjọ, ti wọn ba tapa sofin lọna kan tabi omiran.
Mo rọ awọn alaṣẹ Mozambique lati ri pe idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ yii.
Awọn ọmọ Naijiria nilo ki wọn fi ọwọ wọ wọn nibi kibi ti wọn ba wa.''
Ajọ NIDCOM koro oju si isẹlẹ naa tori pe wọn ni ṣe lo dabi ẹni pe wọn yan awọn ọmọ Naijiria nikan ṣọju ninu ọja tawọn ọmọ orilẹede mii naa wa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post



























