Mo máa fi gbogbo ayé mi tẹ̀lé Tinubu ni, òun ló yọ okùn tí Buhari fi sí mi lọ́rùn kúrò - Sunday Igboho

Sunday Igboho wọ buba pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sunday 'Igboho' Adeyemo ti sọ pe ko si ẹni to le ni ki oun ma ṣatilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu nitori Tinubu lo gba oun silẹ lẹyin ti ijọba Aarẹ ana, Muhammadu Buhari sọ oun di ọdaran ti wọn n wa.

Nigba to n sọrọ nibi eto kan pẹlu awọn alatilẹyin rẹ, Igboho ni Tinubu lo tu oun silẹ ninu iwe awọn ọdaran, pẹlu atilẹyin awọn ori ade kan nilẹ Yoruba.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ohun ti oun ṣe lasiko naa ko buru to ki wọn gbiyanju lati gbẹmi oun nitori ẹtọ oun gẹgẹ bii ọmọ Yoruba loun n bere fun lasiko naa.

"Ohun ti mo ṣe ko buru ju; mi o paayan, mi o ki n ṣe ọdaran"

Ajijagbara naa sọ pe "Ki ni ẹṣẹ mi? Ṣe mo ni ki Yoruba ma ri ni? Taa ni mo pa?

"Mo ni ẹyin Fulani agbesunmọmi, ẹ ma pa wa mọ, ẹ kuro lori ilẹ wa.

"Iwọ Buhari ti o jẹ Aarẹ, ti o ko ba ti le ṣe dede, ẹ pin Naijiria! Ohun ti mo sọ niyẹn. Ko tii pọ ju ọrọ ti mo le sọ lọ.

"Ẹtọ wa ni mo bere, o wa ni ki wọn pa wa. Wọn pa Adogan, wọn pa iya Fatai, iya mi ku le lori rẹ, wọn pa awọn kan l'Eko lori irinajo yẹn. Gbogbo ohun ti a le ṣe la ṣe a o ri ominira."

Igboho sọ pe ọrun oun nikan ni bukata gbogbo awọn ẹmẹwa oun to ba iṣẹlẹ naa lọ wa bayii.

"Tinubu lo yọ okun lọrun mi"

Igboho sọ pe awọn ori ade kan nilẹ Yoruba lo dide, ti wọn ba oun lọ ba Tinubu ko yọ okun ti Buhari fi si oun lọrun kuro, Tinubu si ṣe bẹẹ.

Lẹyin naa lo ni oun ko ni dẹyin ninu atilẹyin oun fun Tinubu, koda o gbe gbogbo awọn to n tako oun pe oun ti Tinubu lẹyin ṣepe.

O ni "Maa fi gbogbo aye mi tẹle baba Tinubu ni, yoo si wọle saa keji.

"Ẹni to ba wa nifẹ mi tọkantọkan, o ni lati ṣatilẹyin fun ohun ti mo n ti lẹyin.

O sọ siwaju si pe awọn ọba alade kan ni awọn yoo ba oun ba Tinubu sọrọ ki oun le maa ṣakoso eto abo ilẹ Yoruba, iyẹn ti oun ba le ri ọdọ bii 50,000 ti yoo kin oun lẹyin.

O fikun pe Tinubu ti ṣeleri atilẹyin fun oun lati maa koju awọn agbẹsunmọmi to n da omi alaafia ilẹ Yoruba ru.

Igboho pari ọrọ rẹ pe gbogbo awọn ọba ilẹ Yoruba lo wa lẹyin oun fun iṣẹ naa.