2027: Bàbá mi yóò dìbò fún mi, olùdíje tó kájú ẹ̀ ni mí-Iyabo Obasanjo

Aworan Iyabo Obasanjo ati baba rẹ, Olusegun Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Sẹnẹtọ Iyabo Obasanjo- Bello ti ogun ara rẹ gbari pe eto idibo gomina to n bọ lọdun 2027 nipinlẹ Ogun, oun jẹ ọkan ninu awọn oludije pataki ti yoo ma gbe apoti ibo.

Obasanjo- Bello sọ eyi lasiko to n kopa ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ momaworan Channels TV.

Nibẹ lo ti sọrọ nipa ipadabọ rẹ sinu oṣelu, erongba lati di gomina ipinlẹ Ogun ati atilẹyin to n reti lati ọdọ ẹbi rẹ.

Ẹni ọdun mọkandinlọgọta naa lo ṣẹṣẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP bọ sinu ẹgbẹ oṣelu APC ṣaaju eto idibo ọdun 2027, to si ni o da oun loju pe oun yoo ri bo gba lati ọdọ awọn obi oun, to fi mọ baba rẹ, iyun Aarẹ nigba kan ri, Olusegun Obasanjo.

"Mo ti fẹ pe Ọgọta ọdu; mo ro pe pẹlu ọjọ ori mi yii, awọn ọrẹ mi diẹ lo jẹ pe wọn si ni awọn obi wọn laye, fun idi eyi mo ki ara mi ku orire pe baba ati iya mi wa laaye.

"N ko ro pe pẹlu ọjọ ori mi yii, o yẹ ki lọ ma ba wọn ṣaaju ki i to ṣe nnkan ti mo fẹ nigba igbesi aye mi. Ohun ti mo sọ ni pe baba mi, mo mọ ati iya mi yoo dibo fun mi. Ohun ti mo fẹ lọwọ wọn niyẹn. Ti n ko ba beere lọwọ wọn gan, wọn yoo dibo fu mi, iyẹn da mi loju," o sọ.

Ọmọ ile igbimọ aṣofin tẹlẹ fikun pe irin ajo bi oun ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lo jẹ pataki si oun ṣugbọn o da oun loju pe baba oun yoo dibo fun oun.

Bakan naa ni Obasanjo- Bello ni o da oun loju pe oun ni gbogbo nnkan ti oun nilo lati di gomina ipinlẹ Ogun.

"Mo ro pe oludije to kaju ẹ ni mi nitori awọn aṣeyọri mi , fun idi eyi, mo ma lọ fun eyi.

"Gbogbo ohun ti awọn ọkunrin ni le mi naa ni ṣugbọn mo tun ro pe mo da ju ọpọ wọn lọ, ti ma si bori."

Obasanjo tun sọrọ nipa aye rẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

O ni ẹgbẹ oṣelu APC ti faye gba onikaluku lati bẹrẹ igbaradi fun eto odibo.

"APC faye gba wa. Oṣu meji ti eto idibo abẹle yoo waye, o ti sumọ ṣugbọn ẹgbẹ oṣelu ko ni sọ pe iwọ ni tabi iwọ kọ,

"Gbogbo ohun ti awọn yooku ni anfani si ni e mi naa ni anfani si, ẹ jẹ ka ma wo.

" ko ki n ṣe pe wọn ti sọ fun mi pe wọn yoo fun mi ni tikẹẹti o, rara o. N ko ro pe ẹnikẹni le sọ pe oun ni oun yoo gba tikẹẹti ," o sọ.