Àwọn ajínigbé jí àwọn tó ń ṣa kóró kaṣú àtàwọn tó ń la igi lóko gbé lọ ní Kwara, wọ́n ń béèrè fún N10m

Oríṣun àwòrán, Others
Ko din ni eeyan meje ti awọn ajinigbe tun ti ji gbe lọ ni awọn ilu kan ti wọn wa ni agbegbe Oro-Agọ ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun ni Ipinlẹ Kwara.
Awọn ilu mẹta ọtọọtọ ni awọn ajinigbe ti sọsẹ ninu ọsẹ to kọja yii.
Awọn ilu yii ni, Ahun, Oke-Ọyan ati Oyatẹ, ti wọn wa labẹ Oro-Ago ni ijọba ibilẹ Ifelodun ni Ipinlẹ naa.
Ohun to n kọ awọn eeyan lominu lori awọn iṣẹlẹ yii ni pe lọna tabi lẹnu isẹ ounjẹ oojọ awọn eniyan ti wọn ji gbe ni wọn wa ti wọn fi ji wọn gbe lọ.
Ohun ti a gbọ ni pe bi wọn ṣe n gbe awọn nnkan ninu oko nibi ti wọn ti n sa koro kasu, bẹẹ ni ni wọn gbe awọn mii nibi ti wọn ti n la igi.
Ọkan lara awọn araalu to ba BBC Yoruba sọrọ lori ago, Ọgbẹni Hakeem, salaye pe eeyan mẹrin ni wọn gbe ni ilu Ahun ki meji ninu wọn to sa mọ wọn lọwọ.
"Ni bii ọjọ marun-un sẹyin, awọn mẹrin kan ni wọn n lọ lagi loko n'iluu Ahun, oju ọna ni wọn ti ka wọn mọ, wọn si gbe awọn mẹrẹẹrin wọ igbo lọ.
"Igba to ya a gburo meji ninu wọn, wọn ni ibi ti wọn so awọn mọ lawọn ti dọgbọn tu okun ti wọn fi de awọn ti awọn si sa mọ wọn lọwọ.
"Ni ilu Ọyatẹ, awọn meji ni wọn gbe ninu oko kasu.
"Ni Oke-Ọyan bakan naa, awọn mẹta ni wọn jọ n sa koro kasu, bi wọn ṣe ya bo wọn ni awọn meji ti wọn jẹ ọkunrin fẹsẹ fẹ, amọ obinrin aarin wọn ti ko ni okun to lati sare ni wọn mu, ti wọn si gbee lọ.
"Ninu awọn meje ti wọn gbe lọ, awọn marun-un ni a n wa bayii lẹyin ti awọn meji ti sa.
"Lori awọn meji ti wọn gbe ni Ahun, awọn ajinigbe naa ti pe, wọn si n bere fun owo millionu mẹwaa naira (N10m) gẹgẹ bii owo itusilẹ.
"Owo naa ni gbogbo ilu n wa bayii,'' Ọgbẹni Hakeem ṣalaye.
Ìjínigbé ti di bárakú ní Oro-Ago
Arakunrin Hakeem sọ pe, ijinigbe ni agbegbe Oro-Ago ko jẹ tuntun, pe koda wọn maa n ja ilẹkun mọ awọn eeyan lori, ti wọn a si maa gbe wọn lọ.
O ni agbegbe awọn tobi ju iye ẹsọ asọgbo ti wọn gbe wa lọ, ati pe bii asọgbo marun-un lo wa ni agbegbe naa to si jẹ pe mẹta ninu wọn ni wọn gbe ibọn fun.
O wa parọwa si alaga ijọba ibilẹ naa lati ranti awọn ni gbogbo igba ti wọn ba n pin awọn asọgbo mii.
Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori iṣẹlẹ naa?
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ọga agba ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara, Adekimi Ojo, sọ pe, botilẹ jẹ pe wọn o ti mu ọrọ iṣẹlẹ yii to ọlọpaa leti, awọn ọlọpaa ti ṣe aseyọri to pọ ni agbegbe Oro-Agọ.
CP Ojo ni aseyọri yii lo jasi bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹwaa ti awọn si tun gba alupupu mẹwaa.
O salaye pe awọn ti gbọ pe awọn ajinigbe yoo ko ọkada wọn wa fun titun ṣe lati le pada lo wọn lati kọlu awọn agbegbe naa.
Kọmiṣọna ọlọpaa ni "eyi lo faa ti a fi gbaradi, ọwọ ti tẹ eeyan mẹwaa to fi mọ mẹkaniki kan ati eeyan kan ti a fura si pe oun loun lọ gbe epo fun awọn ajinigbe ninu igbo.''



























