Kí ló máwọn afurasí jàndùkú olóṣèlú ya wọ ilé Igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo tẹ́lẹ̀ n'Ibadan, ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́? Àlàyé rèé

Ọkunrin to fara ṣeṣe lori ati awọn ọkọ tawọn janduku bajẹ

Oríṣun àwòrán, The Punch

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn afurasi janduku oloṣelu ya wọ ile igbakeji gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹri, Gbolarumi Hazeem, to wa ni agbegbe Asi, Bodija, nibi ti wọn ti ba ọpọ ọkọ jẹ tawọn eeyan si tun farapa.

‎A gbọ wi pe dukia ẹgbẹlẹgbẹ milionu lawọn janduku ọhun bajẹ, ti eniyan ti ko din ni mẹwaa si fi ara pa nibi ikọlu alairotẹlẹ naa to ṣẹlẹ lanaa ọjọ Abamẹta.

Gbolarumi Hazeem lo jẹ igbakeji gomina Adebayo Alao Akala to di oloogbe ni saa akọkọ rẹ laarin ọdun 2007 si 2011 ni ipinlẹ Oyo, to si tun jẹ ogunna gbongbo ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Oyo.

BBC Yoruba ṣe aridaju wi pe ikọlu yii ṣẹlẹ nigba ti awọn igun kan ninu ẹgbẹ oṣelu naa fẹ yan awọn adari tuntun.

‎Ninu ọrọ rẹ, Alukoro fun ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, DSP Olayinka Ayanlade, ṣalaye wi pe ikọlu naa ko ni ohun kankan ṣe pẹlu ipade awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP.

‎‎O ṣe afikun pe ile-iṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ iwadi ati igbesẹ lati ṣe awari awọn to wa nidii ikọlu naa.

‎Nigba ti o n sọrọ, ọkan ninu awọn alaga igun PDP tuntun naa, Abdulrahman Akinoso, ṣalaye pe ikọlu ọhun ṣẹlẹ kaakiri ipinlẹ Oyo.

Ọgbẹni Akinoso fidi rẹ mulẹ pe ikọlu naa waye ni ijọba ibilẹ ariwa Ibadan, guusu Ogbomoso, Akinyele ati ilu igboora ni ijọba ibilẹ aarin gbungbun Ibarapa.

‎Ẹwẹ, awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo ti lodi si yiyan awọn adari fun igun miran ninu ẹgbẹ oṣelu ọhun, ti wọn si salaye wi pe, ẹyin Gomina Seyi Makinde ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa wa, jake jado ipinlẹ Oyo.