Akire tí ìlú Ikire ní ìpínlẹ̀ Osun, Ọba Olatunde Falabi wàjà

Oríṣun àwòrán, Aafin Akire
Akire ti ilu Ikire, Oba Olatunde Falabi, ti waja.
Ọjọ Kejidinlọgbọn oṣu keji ọdun 2026 ni iroyin pe ori ade naa waja jade sita.
Ọdun mọkanlelaadọrun ni Ọba Falabi lo loke epẹ ko to lọ ree darapọ mọ awọn alalẹ ilu rẹ.
Ọpọ awọn araalu lo ti bọ sori ayelujara lati ba ara wọn kẹdun lori iku olori ilu wọn.
Ogunjọ oṣu kini ọdun 2026 ni ori ade naa ṣe ọjọbi rẹ, ọdun mọkandinlọgbọn ati Ọgbọn ọdun to ti lo lori ipo Ọba ti ilu Ikire.
Ohun to yẹ ko mọ nipa Oba Olatunde Falabi
Wọn bi Ọba Ọlatunde Falabi ni ogunjọ oṣu kinni ọdun 1935 si idile Ọmọọba Saliu Omoboyede ati iaafin Ajibola Falabi.
Ṣaaju ko to di ọba, Ọba Falabi jẹ onimọ nipa oogun oyinbo, to si kawe gbaoye ni fasiti ti ilẹ Ibadan.
Yatọ si pe o jẹ onimọ nipa oogun oyinbo, Ọba Falabi jẹ olusọ aguntan ni ijọ RCCG, to si tun jẹ oniṣowo ati agbẹ.
Ko to waja, Ọba Falabi alaga, Oba Falabi Foundation (NGO), Ọga agba, Oba Falabi (Nig.) Ltd ati mọnija fun, ROCHE (Nig.) Limited niluu Eko.

























