PDP kò tí ì kọ́gbọ́n rárá, ẹ̀yìn Tinubu ni mo ṣì wà fún 2027-Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, Others
Minisita fun olu ilu Abuja, Nyesom Wike ni ẹgbẹ oṣelu oun, iyun Peoples Democratic Party ko ti kọgbọn rara ati pe oun yoo tẹsiwaju lati ma ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu ati awọn eeyan to ni ajọsepọ pẹlu Aarẹ.
Wike sọ eyi nigba to n ba awọn akọroyin niluu Abuja, to si jẹ ko di mimọ pe igbesẹ rẹ lati ṣe atilẹyin fun aarẹ Tinubu ki n ṣe tuntun, ti oun si kede ni igbangba ni ọdun 2023.
"Mo sọ fun yin ni ọdun 2023, pe gẹgẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, mo ma ṣiṣẹ fun Aarẹ. Eyi ni nnkan ti mo ṣe nitori mo gbagbọ ninu rẹ, pe awọn ẹgbẹ oṣelu yooku ko fa oludije to ka oju oṣuwọn silẹ," o sọ.
Bakan naa ni Wike ni iha ti oun kọ si ẹgbẹ oṣelu oun ko yii pada rara.
Bẹẹ ba gbagbe, Wike ni o wa ninu ija pẹlu ẹgbẹ oṣelu rẹ, to si ni o ti han gbangba pe wọn ko kọgbọn rara ninu awọn iṣẹlẹ to ti waye tẹlẹ.
"Mo ti sọ fun ọpọ igba, ẹgbẹ oṣelu mi ko ti kọgbọn rara. Idi ree ti mo fi pinnu pe mo ma ṣe atilẹyin fun aarẹ fun igba keji," o sọ.
Wike tun bu ẹnu atẹlu bii ẹgbẹ oṣelu PDP sẹ kuna lati kesi nipa yiyan oludije.
"Gẹgẹ bii minisita, ẹgbẹ oṣelu mi ko kan si mi nipa awọn oludije ti wọn fẹ faa kalẹ fun eto idibo abẹle," o fikun.
Minisita tẹsiwaju pe oun setan lati ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu to ba ti ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu.
"Mo ti sọ pe mo ma ṣe atilẹyin fun oludije to ba ti ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu, n ko fẹ mọ ẹgbẹ oṣelu to ti wa"

























