Ìròyìn tó sọ pé alásè kan fi májèlé sínú oúnjẹ́ fún Ààrẹ Tinubu; ohun tí a mọ̀ nìyí

Aarẹ Tinubu joko nibi ase kan.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Presidency

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ileeṣẹ aarẹ orilẹede Naijiria ti jade sita lati pariwo pe irọ lasan ni iroyin kan to kaakiri lori ayelujara pe ọkan lara awọn alase to n ṣiṣẹ ni ile aarẹ Aso rock gbiyanju lati fi majele sinu ounjẹ fun Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti alase naa si ti wa ni ahamọ awọn agbofinro.

Ileeṣẹ aarẹ Naijiria ṣe apejuwe iroyin naa gẹgẹbi irọ to nla.

Eyi n waye lẹyin ti ọpọ oju opo ayelujara gbe fidio kan atawọn iroyin kan ninu eyi ti wọn ti ni oṣiṣẹ ile idana ni ile aarẹ Naijiria, eyi ti ọpọ maa n pe ni Aso Rock Villa ti wa ni ahamọ lori ẹsun pe o gbiyanju lati fun Aarẹ Naijiria ni majele jẹ.

Ninu atẹjade kan to fi sita loju opo ayelujara rẹ lọjọ Aiku, Ọgbẹni Bayọ Ọnanuga to jẹ olubadamọran pataki fun aarẹ lori ọrọ iroyin fi ẹyin ọwọ da iroyin naa danu.

"Ko si oṣiṣẹ ile idana Aso Rock kankan ti awọn agbofinro mu o. Ko si si alase ile idana Aso rock kankan to gbiyanju lati fun Aarẹ Tinubu ni majele jẹ. Ẹ jọwọ ẹ bu omi pa fidio iroyin afege yii."

Yatọ si atẹjade ileeṣẹ aarẹ yii, ko tii si ileeṣẹ aarẹ kankan to tii gbe iroyin jade lori rẹ

Eyi si kọ ni igba akọkọ ti iroyin to nii ṣe pẹlu igbiyanju lati ṣe ẹmi aarẹ ni suta yoo maa jade sigboro. Loṣu keje ọdun to kọja lawọn agbofinro ileeṣẹ ọ̀tẹlẹmuyẹ DSS fi panpẹ ofin gbe sọrọsọrọ ori ayelujara kan lori ẹsun pe o gbe iroyin pe wọn ti fun aarẹ ni majele jẹ, o si ti ku.