Ṣé lóòótọ́ ní ìjọba Naijiria san ₦2bn fún Boko Haram fún ìtúsílẹ̀ akẹ́kọ̀ọ́ 230 tí wọ́n jí gbé? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ajuwe ile ẹkọ St Mary's Catholic ati aworan dudu awọn agbesunmọmi

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti sọ pe irọ to jinna si oootọ ni iroyin to ti tan kalẹ pe ijọba san biliọnu meji naira fun ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram fun itusilẹ akẹkọọ 230 ile ẹkọ St Mary's Catholic school ni aaringbungbun ipinlẹ Niger nipari ọdun 2025.

Minisita fun eto iroyin, Mohammed Idris, ṣapejuwe iroyin naa ti iileeṣẹ iroyin AFP gbe sita gẹgẹ bii iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ rara.

Idris duro lori ẹsẹ rẹ pe ijọba ko san owo itusilẹ kankan fun Boko Haram lati le tu awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe silẹ.

Minisita eto iroyin sọ pe iroyin ti AFP gbe jade naa tako ọrọ ti oludamọran aarẹ lori ọrọ eto aabo, Nuhu Ribadu, sọ ṣaaju pe ijọba ko san owo itusilẹ kankan fawọn agbesunmọmi.

O ni ko si otitọ kankan ninu iroyin to sọ pe baalu ẹlikopita ni ijọba fi gbowo lọ fun Boko Haram nipinlẹ Borno.

Ileeṣẹ iroyin AFP sọ pe awọn oṣiṣẹ ọtẹlẹmuyẹ kan lo fidi rẹ mulẹ pe ijọba apapọ san miliọnu owo dọla fawọn agbesunmọmi, wọn si tun tu ọga Boko Haram meji silẹ lati le gba ominira fawọn akẹkọọ atawọn osiṣẹ ile ẹkọ Papiri to le lugba to wa lakata awọn agbesunmọmi.

Ẹnikan sọ fun AFP wi pe owo ti ko din ni ogoji miliọnu naira ni ijọba san, nigba ti ẹlomiran sọ pe biliọnu meji naira lowo ọhun.

Iroyin naa tun sọ pe nibi ti Boko Haram n sapamọ si ni Gwoza ni ijọba ti fi baalu gbe owo naa lọ bawọn.

Amọ, ijọba ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin ọhun.

Awọn onwoye sọ pe owo itusilẹ tawọn ẹbi ati ijọba n san lo n jẹ ki iṣẹlẹ ijinigbe naa maa pọ si

Bo tilẹ jẹ oludamọran aarẹ lori eto aabo, Ribadu, ko tii fesi sọrọ naa, ọfiisi rẹ ti sọ ṣaaju pe ijọba ko san kọbọ ki wọn to ri awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe gba pada.

Ijọba ti maa n kilọ ṣaaju wi pe kawọn ileeṣẹ iroyin maa ṣe iwadii daadaa ki wọn to gbe iroyin jade, ki wọn ma ba gbe iroyin to le ṣakoba fun eto aabo Naijiria jade.

Orilẹede Naijiria ti n koju iṣoro ijinigbe fun bi ọdun mẹwaa bayii, eyi to jẹ pe awọn agbesunmọmi n fi i pawo.

Awọn onwoye sọ pe owo itusilẹ tawọn ẹbi ati ijọba n san lo n jẹ ki iṣẹlẹ ijinigbe naa maa pọ si.

Lọdun 2022 ni ijọba ṣofin kan wi pe o ti di iwa ọdaran lati maa san owo itusilẹ fawọn ajinigbe.

Ṣugbọn ofin naa ko mulẹ daadaa pẹlu bawọn ẹbi awọn eeyan ti won ba ji gbe ṣe maa n wa owo lati san fun itusilẹ ẹbi wọn.

Ariyanjiyan yii n waye lasiko ti ijọba Aarẹ Donald Trump Amẹrika n fẹsun kan ijọba Naijiria wi pe ko maa daabo bawọn kristẹni ni Naijiria to.