Àwọn agbébọn tún ṣekú pa èèyàn méjì ní Kwara, èèyàn kan f'arapa

Oríṣun àwòrán, Others
Awọn agbebọn ko tii dẹkun isẹ ọwọ wọn ni Ipinlẹ Kwara o, ṣe ni wọn tun sọsẹ lanaa ni ilu Koro to wa ni ijọba ibilẹ Ekiti ni Ipinlẹ naa.
Ko din ni eeyan meji ti ẹmi wọn lọ si ikọlu naa ti eeyan kan si wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun bayii.
Ṣe ẹ ranti pe ni ilu Koro yii kan naa ni wọn ti pa ẹsọ asọgbo kan ni ọjọ kẹjọ osu keji ọdun yii.
Àwọn agbébọn ti gbà'jọba igbó tó wà láàárín Koro sí Egbe
BBC Yoruba kan si olugbe ilu Koro kan ti a forukọ bo lasiri, o ni igbo to jasi ilu Egbe ni Ipinlẹ Kogi lati Koro ni awọn agbebọn naa wa, wọn si ti gba ijọba igbo naa bayii.
O sọ pe awọn ti wọn ba n kọja lọ si Ẹgbẹ ni awọn agbebọn yii maa n da duro, ti wọn si maa n ran wọn nisẹ.
O ni ti wọn ba pe meji si mẹta, "wọn yoo gba wọn sọdọ, wọn o wa ran eeyan ko lọ ra awọn nnkan bii tramadol, igbo ati orisirisi awọn nnkan wa.
"Igba ti o ba ra a de ni wọn yoo jọwọ awọn eniyan rẹ fun-un.
"Ohun ti wọn maa n se ni yii fun awọn eniyan, ẹni ti ko ba si se bi wọn ṣe fẹ, wọn yoo pa awọn eniyan rẹ ti wọn gba kalẹ.
"Lori awọn ti wọn pa lanaa, nnkan to sẹlẹ ni pe, ni bi ago mẹfa anaa ọjọ Aje, ni awọn mẹta yii n kọja lọ, awọn agbebọn si ko wọn, gẹgẹ bii isẹ wọn, wọn fun eeyan kan lanfaani lati lọ ra awọn nnkan ti wọn nilo wa, pe to ba de, awọn o yọnda awọn yooku.
"Eleyi ni awọn mẹtẹta yii koro oju sii, wọn si gbena woju awọn agbebọn.
"Sugbọn latari pe wọn o pọ to wọn, wọn lu awọn mẹtẹta lalubami. Eeyan kan ku loju ẹsẹ, wọn gbe awọn meji yoku lọ si ile iwosan ni ilu Egbe, sugbọn agbọ pe ikan ti ku ninu awọn meji naa, ikan yoku si wa lọwọ Olorun.
"Ọrọ naa ti wa kuro ni kekere bayii, tori ori rẹ ni ẹsọ asọgbo ti wọn pa ni ilu Koro lọjọ kẹjọ osu yii ku le lori.
"Igbo yii kan naa ni awọn ẹsọ asọgbo yii lọ lati lọ koju wọn sugbọn ọrọ o ri bi wọn se ro o.
"A padanu ẹsọ kan ninu wọn, ibọn ti wọn gbe lọwọ ju tawọn ẹsọ wa lọ, eyi lo faa ti awọn agbebọn fi bori.
"A wa n rọ ijọba ki wọn ṣàánú wa+, ki wọn ba wa wa nnkan ṣe si.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn agbébọn ya wọ ìlú láìpẹ́
Okunrin naa wa see lalaye pe, ti nnkan ba n lọ bayii, ti ijọba o gbe igbesẹ lori igbo ti wọn wa, wọn yoo ya wọ inu ilu lọjọ kan, wọn si ji awọn eeyan gbe.
O fi kun un pe, "lotitọ awọn ọmọ ogun wa ni inu ilu, sugbọn inu igbo nkọ?, inu igbo yii ko jina sinu ilu rara, wọn si lee gba ibi to ba wu wọn wọle.
"A o le lọ soko, a o le se nnkankan ninu awọn igbo wa mọ nitori awọn agbebọn ti gbajọba, awọn si ni wọn n se isakoso.
"Iro ibọn o tilẹ jọ wa loju mọ, a o mọ iyatọ ninu iro ibọn ti awọn ajinigbe ati ti awọn soja.
"Awọn soja kan n yinbọn lati le wọn pada sinu igbo ni, wọn o sa lọ kuro nibẹ rara.

























