Ẹni tó sọ pé mò ń yin Tinubu, bàbá rẹ̀ kò lè gbàmí sílẹ̀ torí nǹkan tí mo fà ju agbára mi lọ - Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X/Sunday Igboho/Instagram
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti sọ pe alaimọkan lawọn eeyan ti wọn ni ki lo de toun fi n kọrin yin Aarẹ Bola Tinubu.
Igboho sọrọ yii nigba to gbalejo awọn ẹgbẹ ọmọ Yoruba kan ti wọn ṣabẹwo sile rẹ niluu Ibadan lopin ọsẹ yii.
Oloye Adeyemo ni nnkan toun fa to fi di pe oun di ẹni to n ṣatipo nilẹ okeere ju agbara oun lọ.
''Were to ni ki lo de ti mo ṣe n yin Tinubu, ṣe babanla baba rẹ le gbami silẹ ni?
Baba rẹ ko le gbami silẹ ẹ, nnkan ti mo fa yẹn ju agbara mi lọ.
Odidi orilẹede kan la n ba a ja, kii ṣe ijọba ibilẹ.
Bakan naa, kii ṣe ijọba ipinlẹ la n ba a ja, ijọba apapọ la n ba a ja.
Awa naa gbiyanju agbara wa wo ni,'' Igboho Ooṣa lo sọ bẹẹ.
Owo Baba Dami wa dupẹ lọwọ awọn to ṣabẹwo si i nile rẹ fun aduroti wọn.
O ni aye ọpẹ pada yọ lori gbogbo nnkan to ṣẹlẹ soun.
Igboho ni oun ko le ṣai dupẹ lọwọ Aarẹ Tinubu nitori o ṣe oun loore.
Ajijagbara fun idasilẹ Yoruba Nation naa fikun ọrọ rẹ pe ti eeyan ba ṣeeyan loore, o yẹ ki ẹni ti wọn ba ṣe loore dupẹ.
Ọgbẹni Adeyemo ni Tinubu lo jẹ koun pada wale lẹyin toun ti lo ọdun marun un lẹyin odi.
"'Wọn lọ ba baba Tinubu lori ọrọ mi, wọn si sọ fun un wi pe ọmọ rẹ ni Sunday Igboho.
Tinubu si dawọn lohun pe ki wọn sọ fun mi pe ki n maa pada bọ wale.
Ti Tinubu ba ni ki n ma wale, ko si nnkan ti mo lẹ ṣe.
Eeyan meloo ni a le baja, Ọlọrun lo n gbija wa.
Bayii ni Aarẹ Tinubu sọ pe ki n maa bọ wale, o ni mimi kan o gbọdọ mi mi.
Ṣe ẹ wa ri pe were ni ẹnikẹni to ba ni mo n yin Tinubu,'' Igboho lo sọ bẹẹ.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Ki lo n da ikede ijọba duro lori ọrọ Sunday Igboho?
Ṣaaju ni Olugbon ti Orile Igbon, Ọba Francis Olusola Alao, ti ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe loootọ ni Olubadan ti ba Aarẹ Tinubu sọrọ lori ọrọ Igboho, amọ, kabiyesi naa sọ pe oniruuru ileeṣẹ ijọba lo ni lati ṣiṣẹ lori ọrọ naa.
''Iyọkuro orukọ Sunday Igboho ninu iwe awọn ti ijọba n wa ni ṣe pẹlu eto.
Oniruuru ileeṣẹ ijọba bi ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ileeṣẹ ọlọpaa to fi mọ ọfiisi oludamọran aarẹ lori eto aabo ni wọn yoo jọ kọwe si ara wọn lori ọrọ naa.
Gbogbo eto yii lo gbọdọ waye ko to di pe ijọba yoo kede iru nnkan bayii.
Nnkan to jẹ ki Igboho maa sọrọ bayẹn ni pe o ti n pongbẹ lati gba ominira rẹ pada tipẹ.
Eyi lo jẹ ki inu rẹ dun pe Olubadan ti ba aarẹ sọrọ, aarẹ si ti gba lati yọ orukọ rẹ ninu iwe awọn ti wọn n wa.
Amọ, o dami loju wi pe ko sẹni to le fọwọ ṣinkun ofin mu Igboho mọ pe ijọba n wa a lọwọ yii.
A ni lati duro ki ijọba ṣe gbogbo eto to ba yẹ lati ṣe tan lori ọrọ naa ki wọn to kede pe Sunday Igboho ko si lara awọn ti ijọba n wa mọ,'' Olugbon ṣalaye.
Ti ẹ o ba gbagbe, lẹyin ti ajọ DSS yabo ile rẹ to wa lagbegbe Soka niluu Ibadan nibi tawọn iṣọmọgbe rẹ kan ti ku lọjọ kinni oṣu Keje ọsun 2021 ni Igboho sa kuro ni Naijiria.
Ẹsun ti wọn fi kan Igboho ni pe o n ko nnkan ija oloro pamọ sinu ile.
Lẹyin naa ni ijọba Aarẹ Muhammadu Buhari fi orukọ rẹ sinu iwe awọn ọdaran ti ijọba n wa.


























