Ṣé lóòótọ́ ni ọlọ́pàá ti fọwọ́ òfin mú ọ̀dọ́binrin tó ní ọkùnrin kan fipá bóun lò pọ̀? Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, DSP Oluseyi Babaseyi/X
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, ti sọ pe irọ to jinna si oootọ ni iroyin kan to sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fọwọ ofin mu ọdọbinrin to mu ẹjọ lọ sọdọ awọn ọlọpaa pe ọkunrin kan fipa boun lopọ.,
DSP Babaseyi ni iṣẹ iwadii si n lọ lori ọrọ ti ọdọbinrin naa sọ pe ọkunrin kan fipa boun lopọ.
''Ileeṣẹ ọlọpaa ko mu ọmọbinrin naa, oun lo mu ẹjọ wa si agọ ọlọpaa.
Ileeṣẹ ọlọpaa si n ba iṣẹ iwadii lọ lori ọrọ naa.
Iroyin ofege lawọn eeyan n gbe kaakiri lori itakun ayelujara wi pe ọlọpaa ti mu obinrin naa.
Iwadii n lọ lọwọ lori ọrọ naa, a o si fi abọ iwadii wa to araalu leti ti a ba ti pari,'' DSP Babaseyi lo sọ bẹẹ.
DSP Babaseyi sọ pe l'Ọjọru ọjọ kejidinlogun oṣu yii ni Mirabel mu ẹjọ naa wa si agọ ọlọpaa to wa ni Ibafo.
O ni nibẹ lo ti sọ fawọn ọlọpaa wi pe lagbegbe Ogijo ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe wọn kọkọ gbe ọmọbinrin naa lọ si ile iwosan fun oriṣiiriṣii ayẹwo, ki wọn to da a pada si agọ ọlọpaa to wa ni Ogijo nibi to ni iṣẹlẹ naa waye.
Agbẹnusọ ọlọpaa ni ọdọkunrin ko le roni daadaa nigba to kọkọ de agọ ọlọpaa Ogijo, ki wọn to tun sọ pe ko lọ ṣe awọn ayẹwo mii sii.
DSP Babaseyi ni ko si igba kankan ti ileeṣẹ ọlọpaa fọwọ ofin mu omobirin naa.
O wa rọ araalu wi pe ki wọn maa ṣe iwadii iroyin ti wọn ba fẹ gbe jade ki wọn to maa gbe iru iroyin bẹẹ sori ayelujara.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí obìnrin tó ní ọkùnrin kan fipá bá òun lò pọ̀ nítorí òun kọ̀ láti fẹ́ ẹ
Pẹlu omije loju ati ibẹru ọkan ni arabinrin kan to pe orukọ rẹ ni Mirabel fi ṣalaye ohun ti oju rẹ ri nigba ti ọkunrin ojoji kan wa ka mọle, to si fipa ba lopọ.
Ninu fidio kan ti Mirabel gbe sori ayelujara Tiktok, o ṣalaye pẹlu omije, to si ni iṣẹlẹ ọhun waye ni ọjọ Kẹdogun oṣu Keji ọdun 2025.
O tẹsiwaju pe iṣẹlẹ ọhun ti fa ọpọ aisan si ago ara rẹ, ti oun si nilo lati mu ọti tabi lo oogun ko to le ri orun ṣun.
Mirabel ni owurọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ko ko ko ni ẹnu ọna oun lo ji oun , ti oun si ro pe awọn ti awọn jọ n gbe papọ ni.
O ni ohun iyalẹnu lo jẹ nigba ti oun ri pe ojoji ni eeyan naa, to si fi tipatipa ja ilẹkun wọ ile oun.
Mirabel ni oun dakun nigba ti arakunrin naa ti oun ṣubu, to si jẹ pe nigba to pada laju, ọkunrin naa wa ni ọna lati fipa ba oun lopọ.
O ni lẹyin iṣẹlẹ naa ni ẹjẹ bẹrẹ si ni ya sita ni ara oun, ti oun si kọkọ ro pe nnkan oṣu lo de.
Ọdọmọbinrin ni oun gba atẹjisẹ kan lati ori opo ayelujara Instagram pẹlu orukọ kan to n jẹ "Priston".
Priston yii lo ni o jẹwọ pe oun lo fipa ba lopọ nitori o gbiyanju lati bẹ ọdọmọbirin naa ni ọpọ igba ṣugbọn o kọ jalẹ, eyi lo si fa a to fi gbe igbesẹ naa.
Afurasi ni Mirable tun sọ pe o sọrọ pẹlu igboya pe oun wa lati idile olowo, ti oun si le dabaru iwadii ileeṣẹ ọlọpaa.
Mirabel tun gbe fọnran mii sita nibi to ti ṣalaye pe oun gbinyaju lati gba ẹmi ara oun pẹlu majele.
O ni ọrẹ oun kan lo doola ẹmi oun, to si gbe oun lọ si ile iwosan.
"O rẹmi, n ko fesi si atẹjisẹ. Mo ma fesi nigba ti ara mi ba ya , mo dupẹ," o kọ sita.
Fidio yii lo ti lọ kaakiri oju opo ayelujara, ti ọpọ si ti kan awọn ileeṣẹ ọlọpaa lati bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.


























