NPLF gbé ìdájọ́ kalẹ̀ fún Kwara United lẹ́yìn tí àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lu rẹfirí àti ikọ̀ Rivers United lálùbami

Asiko rogbodiyan naa niluu Ilorin
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ajọ to n ri si iṣakoso bọọlu awọn ikọ alabẹle ni Naijiria, NPFL, ti kede pe ki ikọ Kwara United san miliọnu meji naira fun bi awọn ololufẹ wọn ṣe ko iya fun awọn ababọọlu Rivers United.

Ajọ naa tun fofin de lilo papaluu isṣere Rashidi Yekini to wa ni Ilorin fun ikọ Kwara United.

Eyi waye latari ohun ti wọn pe ni riru ofin ati iwa jagidijagan to sẹle ni ibi ifẹsẹwọnsẹ ẹlẹẹkejilelogun laarin ikọ naa ati Rivers United.

Isẹlẹ naa waye lọjọ kejidinlogun, osu Keji yii lori papa iṣere Rashidi Yekini to wa ni ilu Ilorin ni ipinlẹ Kwara, nibi ti ikọ Kwara United ati Rivers United ti waako, ti wọn si ta ọmi goolu kọọkan.

Ki ni NPFL sọ?

Ninu atẹjade ti ajọ NPFL fi lede sori itakun Facebook, wọn sọ pe Kwara United kuna lati pese eto aabo to peye, to si jasi bi awọn eeyan ṣe kọja si ibi ti ko yẹ ki wọn de.

Atẹjade naa sọ pe Kwara United jẹbi kikuna lati boju to ihuwasi awọn ololufẹ rẹ to jasi bi wọn se sekọlu si awọn abẹnugan ifẹsẹwọnsẹ naa ati ti Rivers United.

NPFL ni "awọn ololufẹ Kwara United ya wọ ibi ti ko yẹ ki wọn wọ wọn, ko iya fun awọn abẹnugan ifẹsẹwọnsẹ naa ati ti Rivers United to si ja si ifarapa awọn kan.

"Awọn ololufẹ ikọ naa mu iwa ibajẹ ba ere bọọlu alafẹsẹgba nipa iwa jagidijagan yii"

Owó ìtanràn tí NPFL ní kí wọ́n san

Ajọ naa ni ki ikọ Kwara United san owo miliọnu meji naira fun kikuna lati pese eto aabo to peye, milliọnu kan naira fun aibojuto ihuwasi awọn ololufẹ wọn.

Wọn tun ni ki wọn san milliọnu meji naira mii fun lilu awọn abẹnugan ifẹsẹwọnsẹ naa ati ti ikọ Rivers United pẹlu milliọnu kan naira (N1m) fun mimu iwa ibajẹ ba ere bọọlu alafẹsẹgba.

‎Kwara United yoo tun san milliọnu kan naira fun dida awọn abẹnugan ifẹsẹwọnsẹ naa ati ti ikọ Rivers United duro fun ọpọlọpọ wakati ati milliọnu méjì mii gẹgẹ bi owo gba mabinu ati owo itọju fun awọn ti wọn farapa.

Gbogbo owo itanran yii wa jẹ milliọnu mẹsan-an naira lapapọ.

NPFL fòfin de pápá ìṣeré Ilorin fún Kwara-United

Yatọ si awọn owo itanran wọn yii, ajọ naa tun yọ mẹta lara koko ti wọn ni nilẹ, eleyi to jẹ ifasẹyin nla fun wọn nibi idije naa.

Lafikun, wọn fofin de lilo papa iṣere ilu Ilorin fun ikọ Kwara United, wọn wa dari wọn lati lọ máa gba gbogbo ifẹsẹwọnsẹ to ku ni papa isere MKO Abiola to wa ni Abeokuta titi saa yii yoo fi pari.

Wọn tun ni o di ọranyan fun wọn lati wa awọn ololufẹ wọn ti wọn hu iwa yii jade fun ijiya to tọ.

Ajọ NPFL wa fun wọn ni ọjọ meji lati pe ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn ba fẹ.

Ṣé lóòótọ́ ni ìjìyà yìí pọ̀ ju ẹ̀sẹ̀ Kwara United lọ?

Ni bayii, ọpọ awọn eeyan to mọ nipa ere bọọlu ati awọn akọroyin, papaa julọ ẹgbẹ awọn to n kọ iroyin nipa ere idaraya, SWAN ti sọ pe ijiya ti NPFL gbe kalẹ yii pọ ju ẹsẹ lọ

Wọn sọ pe nigba ti wọn ti ni ki wọn san owo, ko yẹ ki wọn tun yọ koko wọn mọ yatọ si pe wọn tun fofin de papa iṣere Ilorin.

Wọn ni irufẹ ẹsẹ ti awọn ololufẹ Kwara United ṣẹ ni awọn ti ikọ Kano Pillars ati ti Wikki Tourist naa ṣẹ ni bii ọsẹ diẹ sẹyin ti ijiya wọn si jẹ sisan owo itanran nìkan.

Wọn wa n bi ajọ NPFL leere wi pe, bawo lọbọ ṣe ṣori ti inaki naa ko se?

Àwọn olólùfẹ́ Kwara-United kó ìyà fún Rẹfiírí, akọ́nimọ̀ọ́gbá àti àwọn míì lẹ́yìn tí ta ọ̀mì pẹ̀lú Rivers-United ní Ilorin

Awon ero iworan lori papa iṣere Kwara Stadium
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Rogbodiyan bẹ silẹ ni ilu Ilorin ni papa isere George Innih Agbasika to wa ni ilu Ilorin, Ipinlẹ Kwara nibi idije NPFL ṣáá tọdun yii ti n lọ lọwọ.

E yi waye lẹyin ti ikọ agbabọọlu Kwara United ta ọọmi goolu kọọkan pẹlu alejo wọn tii se ikọ agbabọọlu Rivers United lanaa ọjọ kejidinlogun, osu keji, ọdun 2026.

Ṣe ni awọn ololufẹ ikọ Kwara United din dundu iya fun Rẹfiri, akọnimọọgba ati agbabọọlu Rivers United to fi mọ awọn mii ti wọn jẹ aworan.

Kí ló sokùnfa rògbòdìyàn gan-an

BBC Yoruba ba o sojumi koro kan to ni ka forukọ bo oun lasiri sọrọ, o sọ pe ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni ago mẹrin irọlẹ.

"Ikọ Kwara United gba goolu kan wọle ni ọgbọn isẹju le ni meji latọwọ Samsudeen Mohammed.

"Lẹyin igba naa ni Rẹfiri ifẹsanwọnsẹ naa ti n fi awọn ohun to yẹ ko jẹ anfaani fun ikọ Kwara United dun wọn.

"Lara awọn anfani yi ni" goli-kọju-si-mi-n-gba-si-ọ" ti a mọ si pẹnariti, ti Rẹfiri kọ lati fun ikọ naa.

"Ati igba naa ni awọn ololufẹ Kwara United ti n binu, ti wọn si ti n gbaradi.

"Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa pe isẹju aadọrun un to yẹ ko pari, Rẹfiri tun fi isẹju marun-un mii kun un.

"Ninu isẹju marun-un yi ni ikọ Rivers United ti da goolu eyọ kan naa pada lati ọwọ David Sholumade, ni ifẹsẹwọnsẹ naa ba di ọmi goolu kọọkan.

Kini wọn tun sọ nipa ti awọn ololufẹ Kwara United ṣe pada?

O ṣoju mi yii tun salaye pe: "Kete ti Rẹfiri fọn fere ipari ifẹsẹwọnsẹ naa ni awọn eeyan ti a furasi pe wọn jẹ ololufẹ Kwara United ya wọ ori papa, wọn si bẹrẹ si n lu awọn eeyan.

"Wọn n sọ okuta, ike, ijoko ati awọn nnkan mii mọ awọn eeyan.

"Wọn lu Rẹfiri, wọn lu ọkan lara awọn akọnimọọgba Kwara United ati agbabọọlu ikọ naa.

"Awọn kan farapa, wọn ba ọpọlọpọ nnkan jẹ ninu papa isere naa. Koda wọn tun lu awọn aworan ti ọwọ wọn ba.

"Ọpẹlọpẹ awọn agbofinro ti wọn sare doola awọn eeyan yi, nnkan o ba bajẹ jina.

"Ohun ti wọn sọ ni pe, ko yẹ ki Rẹfiri fi isẹju marun-un kun-un mọ lẹyin igba ti akoko ti pe.

"Wọn ni Rẹfiri naa sisẹ tako Kwara United bibẹẹ kọ, wọn o ba gbe goolu kan naa lọ.

Atejade ti ẹgbẹ agbabọọlu Kwara United fi sita lori iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, @Kwara United

Àwọn akòròyìn sá pamọ́ sínú yàrá wọn fún o lé ní wákàtí kan

Akọroyin kan fi to wa leti pe, Ọrọ naa le debi pe, awọn ẹgbẹ akọroyin ko lee jade, o ni se ni awọn ki mọ inu yara awọn nitori awọn janduku yii ti wa ni gbogbo ibi ti awọn le gba jade.

O fi kun-un pe awọn alaawẹ gan-an ko raye jade lọ sinu.

Kí ni ìdí tí àwọn olólùfẹ́ Kwara United fi fẹ́ kí ikọ̀ wọ́n borí ní tipátipá

Iwadii BBC fihan pe, lọwọ lọwọ bayii, Kwara United wa ni ipo kẹrindinlogun lori tabili NPFL saa yii, to si jẹ pe ti wọn ba pari bẹẹ, wọn yoo ja lọlẹ si idije NNL to tun kere si NPFL.

E yi ni awọn ololufẹ Kwara United ko fẹ ko sẹlẹ ti wọn fẹ ki ikọ wọn bori ni tipatipa.

Ifimufinlẹ tun jẹ ko ye wa pe lati ọjọ kẹrinla osu yii ni iwa janduku yii ti n rugbo bọ, lẹyin ti ikọ agbabọọlu Kano Pillars tun bawọn ta ọọmi mọle.

Ni ṣe ni wọn din dundu iya fun akọroyin kan, ti wọn ro pe rẹfiri ni.

Ohun tí àwọn aláṣẹ Kwara United sọ:-

Wayi o, Awọn alasẹ ikọ Kwara United ti wa bẹnu atẹ lu iwa janduku naa.

Wọn sọ eyi ninu atẹjade ti wọn fi lede ni anaa, ọjọ kejidinlogun bakan naa.

Iwe naa ka pe, erufẹ iwa bẹẹ kii se iwa ikọ ẹgbẹ naa nitori awọn mọ riri dida aabo bo awọn eleto ere idaraya.

Wọn sọ pe ikọ agbabọọlu naa setan lati sowọpọ pẹlu awọn agbofinro lati rii pe awọn to wu iwa yii di mimu fun ijiya to tọ.

Wọn wa rọ awọn ololufẹ wọn lati se suuru nitori awọn yoo gbe eto kalẹ lati ran awọn eeyan lọwọ ninu ihuwasi wọn ati lati jẹki ibasepọ pipe wa laarin wọn ati awọn.