Gbogbo Olórí ẹlẹ́sìn ló ń wá 'Customer' Ọlọ́run kan ló wà- Alayo Melody singer

Àkọlé fídíò, Mo máa n gba kéú lọ́dọ̀ Alfa mi kí ń tó kọrín nígbà míì- Alayo
Alayo

Sé ẹ ranti akọrin ẹ̀mi Kristieni tó máa n ṣe 'Ramadan Lecture' fáwọn mùsùlùmí ni Abeokuta? BBC Yoruba ti wa Michael Alayo Melody kan

O ṣalaye ipa ti ọrọ awọn Chibog girls ti Boko Haram ji gbe sẹyin ni lori ipinnu oun lati maa ṣe papọ pẹlu awọn musulumi ki alaafia le jọba ni Naijiria.

Dokita Akinola Ayoola Michael sọ pe Olorun kan lo wa, olori ẹsin lo n ṣì awa eniyan lọna.

Michael Alayo sọ pe idile Onigbagbọ ni won ti bi oun ati pe kristiẹni pọnbele ni oun.

O ni pe lọdun 1999 ni oun di akórin ẹmi ni pẹrẹwu. pẹlu orin gospel juju tungba ti oun n kọ.

O mẹnuba pataki irẹpọ laarin gbogbo ijọ ẹlẹsin Kristieni ati ati laarin awọn ẹya ninu Islam naa.

Bakan naa lo ṣalyue oun to fa wahala laarin oun ati Pasuma to n kọrin fuji tẹlẹ ati bi wọn ṣe yanju aawọ naa.

Alayo