Taiwo Bamidele Ondo Dwarf Judge: Ọlọ́run kò ṣe àṣìṣe pé ó dá mi ní aràrá
“Gbogbo awọn ti wọn bi ṣiwaju mi lo ga to sin gbọnlẹ!”.
“Ẹni to jẹ ọkọ fun mi leni, Ọlọrun lo yan an fun mi bo tilẹ jẹ pe gbogbo ẹbi mi lo yari pe mi o le fẹ arara”. Iyawo Bamidele lo sọ eyi fun BBC Yoruba.
Adajọ ni Taiwo Bamidele Ezekiel ni ile ẹjọ Majisireeti ipinlẹ Ondo.
O ni ọpọlọpọ igba ti oun ba n rin laarin igboro ni oun maa n ri idẹyẹsi ti ko ṣee ka.
“Ọpọlọpọ igba ti wọn ba ni ẹ wo baba kukuru yii, emi naa a ni ẹ wo baba giga yii, a kan ma sọ ọ di awada tori naa mi o jẹ ki gbogbo iyẹn mu irẹwẹsi de ba mi”
Koda, oluṣọ aguntan ni pẹlu ni ijọ Redeem Church.
Nigba ti wọn bi i, ọrọ o ba di nigbo lo ti gbe oyun wa fun mi too fi bi arara lọmọ, ṣugbọn o ni tori pe baba oun gbagbọ pe iya oun kii ṣe oniṣekuṣe lo ṣe gba pe sababi ni.
Ni kekere nigba ti ko tii ni oye iru eeyan to lee da lọjọ iwaju lai wo ti ipo rẹ, o maa n bi Ọlọrun leere pe ki lo de to fi da oun ni arara.
“Ninu idile mi, a fẹrẹẹ pe ogun ti baba mi bi ṣugbọn emi nikan ni arara”.
Ẹ wo bi Taiwo ṣe ja fita fita lati borii ainigbagbọ ninu ara ẹni.