Akomolede Yoruba: Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílùú òyìnbó rèé

Àkọlé fídíò, Ìtàn ọ̀rẹ́ tó fi ògùn gba ọkọ ọ̀rẹ́ rẹ̀ ni Akomolede BBC Yorùbá fẹ́ kọ́ wa lònìí

Arabinrin Olaitan Zainab ni olukọ wa lonii, o ṣalaye iru oju ti ọrẹ meji fi wo ọkunrin kan ti wọn pade ti ọkan fi oju tẹmbẹlu rẹ amọ oun gan lo pada n wa lati fa oju rẹ mọra tori owo

Ṣe ẹ ranti bi inu kilaasi yin ṣe maa n ri lasiko ti ẹ ba fẹ ka awọn iwe ayọka Yoruba nigba ti ẹ ṣi wa nileewe girama?

Bẹẹ gẹlẹ ni Kilaasi Akomolede Yoruba wa yoo ṣe ri lonii ki ẹ lọ wo fidio naa loke fun itan aladun ati akọniloye yii.

Iwe ti ajọ eleto idanwo aṣekagba WAEC yan fun awọn akẹkọ aṣedanwo ni Akomolede Yoruba gbe yẹwo lonii ti Akọle rẹ jẹ "Ọ̀rẹ́ mi".

Ṣe ẹ mọ pe ẹnu awọn olukọ Yoruba maa n dun fun itan sisọ, bẹẹ gẹlẹ ni olukọ wa Zainab Olaitan ko ṣe ja wa kulẹ rara lonii pẹlu awọn ọrọ afiwe, ọrọ apọnle to n jẹyọ.

Koda, ẹkọ ti wọn mu jade nibẹ ko lakawe rara.