Yoruba Language: Akomolede ati Asa Yoruba tọ̀sẹ̀ yí rèé lẹ́nu olùkọ́ wa

Àkọlé fídíò, Bí ẹ ṣe mọ̀wé tó, ẹ wá dánrawò níbí pẹ̀lú "Àpólà Ọ̀rọ̀ Orúkọ - Noun Phrase

Imọ ede Yoruba ko yọ ẹnikẹni silẹ. Atọmọde atagba lo gbudọ maa gbe aṣa Yoruba larugẹ nibikibi ti a ba wa yala nile ni tabi lẹyin odi.

Eto Akọmọlede ati Aṣa Yoruba, ti yoo maa waye lẹẹkan lọsẹ loju opo ikanni BBC Yoruba, yoo maa kọ wa ni ede ati asa wa, ko maa ba parun.

Akori ọ̀rọ̀ fun agbeyẹwo loni ni "Apola Ọrọ Orukọ" eyi ti ẹ mọ loyinbo si "Noun Phrase" ati awọn isọri rẹ.

Olukọ wa fun toni ni Iyaafin Idowu Peters lati Ogba Junior Grammar School.

Ẹ o ni le yin in kuro loju fidio to wu ni lori pẹlu ẹkọ ede Yoruba.