Unilag VC: Folasade Ogunsola ni obìnrin àkọ́kọ́ tó jẹ ọ̀gá àgbà fún ibùdó ẹ̀kọ́ṣẹ́ ìṣègùn Fáṣítì Eko

Folasade Tolulope Ogunsola

Oríṣun àwòrán, @Anisformat

Ọdun 1958 ni wọn bi Ọjọgbọn Folasade Tolulope Ogunsola, ọmọ Mabogunje sile aye.

Kekere si ni Folasade ti nifẹ lati maa ṣe bii dokita, ti yoo si maa tọju bebi to n ṣe aisan.

Laarin ọdun 1974 si 1982, Folasade kẹkọ dokita nile ẹkọ fasiti Ile Ife to si gba oye imọ ijinlẹ akọkọ nigba to gba oye imọ ijinlẹ keji nile ẹkọ fasiti Eko.

Lẹyin naa lo tẹ ọkọ leti lọ si ilẹ Gẹẹsi, to si tun kọ ẹkọ si ni fasiti Wales laarin ọdun 1992 si 1997.

Lẹyin to pada wale, Folasade bẹrẹ iṣẹ ni ile ẹkọ ẹkọṣẹ imọ isegun ni fasiti Eko, to si ni igbega de ipo ọga agba ibudo naa.

Folasade Tolulope Ogunsola

Oríṣun àwòrán, @TheICIR

Ọga agba tuntun fun fasiti Eko yii lo ti jẹ oniwadii agba lori kokoro arun HIV, to si tun jẹ alaga igbimọ to n ka ọwọja arun to n ran ko.

Bakan naa ni o jẹ igbakeji ọga agba fasiti Eko lọdun 2017, ẹka iṣẹ idagbasoke, ipo yii si lo wa ti wọn fi kede rẹ bii ọga agba fasiti naa.

Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?

Wọ́n ti yan adarí tuntun míì fún fásitì Unilag

UNILAG VC: Ilé iṣẹ́ tó ri si ètò ẹ̀kọ́ l'Abuja kò tí rànsẹ́ pé Unilag ti ni Giwa tuntun

Oríṣun àwòrán, Others

Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pe awọn alaṣẹ ile iwe giga fasiti Eko, Unilag ti yan giwa tuntun mii lati maa tukọ ile iwe naa.

Ọjọgbọn Folashade Ogunsola lo gbegba oroke ninu gbogbo awọn ti wọn dibo yan eyi to waye larin awọn ile igbimọ aṣofin fasiti naa ti wọn fi yan adele.

Folashade ni igbakeji ẹka idagbasoke fun giwa to wa nibẹ tẹlẹ, Oluwatoyin Ogundipe.

Gẹg bi iroyin ti a gbọ, ninu ibo mẹtadinlaadọsan, Folashade nikan ni ibo marunlelaadoje.

Ẹnikeji ti wọn tun foju sun fun ipo kan naa, Ọjọgbọn Ben Ogbojafor ni tirẹ ni ibo mọkanlelọgbọn.

Nibi ipade ijoko ile igbimọ aṣofin fasiti naa to waye lọjọ Aje ni wọn ti yan Folashade.

Àkọlé fídíò, 'Ìgbà tí mo máa fi lajú sáyé padà, ọ̀fọ̀ ikú mi ní wọ́n ń kígbe'

Ohun to ṣẹlẹ̀ tẹlẹ

Ṣaaju, ọga Agba ileewe fasiti ipinlẹ Eko ti wọn yọ nipo, Oluwatoyin Ogundipe ti gba ileẹjọ lọ lẹyin ti Ajọ amuṣẹya fasiti naa yọ ọkuro nipo.

Asiko ipade awọn ajọ amuṣẹya ti wọn ṣe ni ileeṣẹ National Universities Commission ni ilu Abuja ni wọn ti yọ Ọjọgbọn Ogundipe nipo gẹgẹbi ọga agba fasiti ilu Eko.

Nibayii, Ọjọgbọn naa ti gba agbẹjọrọ agba ni Naijiria, Mike Ozekhome lati lọ ṣoju rẹ ni ileẹjọ.

Ninu atẹjade ti Ogundipe kọ si Ozekhome, O ni wọn yọ oun lai tẹlẹ ilana otitọ ati ododo to yẹ ki wọn tẹle lati yọ oun kuro ni ipo.

Ọjọgbọn Ogundipe ni oun ni atilẹyin awọn oṣiṣẹ ati olukọ fasiti naa, nitori wi pe ọna ti wọn gba fi yọ oun tako ofin to de fasiti lorilẹ-ede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America

Ninu ọrọ rẹ, Ozekhome ni iditẹmọni ni ipade pajawiri ti wọn pe lati yọ Ogundipe kuro nipo.

Bakan naa ni Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipe saaju awọn to n fẹhọnu han lori bi wọn ṣe dede yọ kuro nipo.

Ogundipe ni o farahan pẹlu awọn ẹgbẹ oluko NASU, SSANU àti ASUU nibi ti wọn ti n ṣe ifẹhọnu han lati inu ọgba fasiti naa titi de ẹnu abawọle ileewe giga naa.

Lasiko ti Ọga agba ileewe naa ti wọn yọ nipo n sọrọ, o ni ọgbọn ọdun niyii ti oun ti n sisẹ ni ileewe naa ni ipo kan tabi omiran, nitori naa wọn ko le dede yọ oun bii jiga.

Bakan naa ni alaga ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ti ipinlẹ Eko, Dokita Dele Ashiru ni awọn tako bi wọn ṣe yọ Ọjọgbọn Ogundipe nipo, ti awọn si fi igboya tẹle gẹgẹ bi adari wọn.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Ilé iṣẹ́ tó ri si ètò ẹ̀kọ́ l'Abuja kò tí ì rànsẹ́ pé UNILAG ti ni Giwa tuntun

Ó ti tó bi ọja mẹ́ta tí awuyewuye ti ń wáye lóri yíyọ giwa Fásitì Eko

Tí ọ̀rọ̀ nááà sì ti dí gbọ́nmísi-omi ò tóo nípa oníruuru ìròyìn tó ń jáde láti ilé iwé ọhun.

UNILAG VC: Ilé iṣẹ́ tó ri si ètò ẹ̀kọ́ l'Abuja kò tí rànsẹ́ pé Unilag ti ni Giwa tuntun

Oríṣun àwòrán, Others

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Folashade Tolulopẹ Ogunsola sàlàye fún BBC pé, wàhálà yìí kìí ṣe ǹkan ti ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni àná bíkòṣe láti ọjọ́ tó ti pẹ́.

Ogunṣola ní láti ọdún tó kọjá ní ọ̀rọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ láti igba ti Omowe Babalakin to jẹ́ alága ìgbìmọ̀ Kánsù tó ń mójútó ọ̀rọ̀ Fásítì náà ]ati Ogundipe ti n ni kudiẹ-kudié.

Koda, eyi wa lara idi ti wọn fi wọgile ṣiṣe eto ayẹyẹ ikẹkọọjade fawọn akẹkọọ ni oṣu kẹta ọdun yii.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Kini Fasiti UNILAG ri si eto iyọninipo Ogundipe?

Ọ̀jọ̀gbọn Ogunṣola ni ọna iyọni nipo naa kudiẹ kaato nitoripe wọn ko téle ilana ofin bi o ṣe yẹ.

O ni wọn ko fún Ogundipe láàyè láti sọ tẹnu rẹ̀, bákan náà ni wan ko láti tẹ̀lé ìlànà tí o yẹ kí wọ́n tó gbé irú ìgbẹ́sẹ̀ bẹ́ẹ̀ niru iṣẹlẹ fasiti nla bii ti Eko yii.

Ó ní àti yíyọ àti kíkéde ẹlòmíràn kò bá ìlànà tó tọ́ mu.

Ati pe yiyan tabi kikede Ojogbon Soyombo ko tẹle ilana to yẹ gẹgẹ bii adele Giwa fasiti Eko.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo

Kini o wa n ṣẹlẹ bayii ni fasiti Eko UNILAG?

Ní báyìí à ń dúró de ilé iṣẹ ijọba apapọ tó n ri sí ètò ẹ̀ka gíga ni Nàìjíríà lati kede ohun to kan.

Ogunṣola ni Awọn ẹgbẹ olukọ ati awọn ti kii ṣe ti olukọ ti kọwe atilẹyin pe iṣẹ Ogundipọ tẹ awọn lọrun ranṣẹ si oke bi o ṣe yẹ lẹyin ọpọlọpọ ipade lati ana.

Ati pe, ohun to ṣe pataki julọ ni pe: à ń reti ki ileeṣẹ ijọba apapọ eto ẹkọ ati ẹgbẹ fasiti Naijiria (NUC) sọrọ lori ohun to n kan laiṣegbe fẹnikan bikoṣe pẹlu ootọ inu.

O fi idi ẹ mulẹ pe agbara wa lọwọ awọn mejeeji ati pe awọn nikan lo le sọ ǹkan ti wọ́n fẹ́, àti pé àwọn níkan ló lé pasẹ ibi ti ọ̀rọ̀ yóò dúró lé.

Ní ti NASU àti ASUU, à ti díbo káre máa bá iṣẹ́ rẹ lọ fún gíwá tó wà níbẹ̀ yìí, nítori náà ẹ̀yìn Ogundipe ni a wà.

Adéle gíwá ti wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn ko ti i bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. títí di isinyi ti iroyin yii n jade

Ọjọgbọn Oluwatoyin Ogundipe

Oríṣun àwòrán, Joshua Adetunji

Kini o kọkọ ṣẹlẹ?

UNILAG VC: Ọ̀jọ̀gbọ́n Ogundipe ní òun sì ni gíwá UNILAG

Giwa fasiti ijọba apapọ to wa niluu Eko, UNILAG, Ọjọgbọn Olawatoyin Ogundipe ti sọ pe iroyin ofege ni iroyin to tan kalẹ kaakiri pe wọn ti yọ oun nipo.

Akọwe agba fasiti naa, Ọgbẹni Oladejo Azeez lo fi atẹjade kan sita pe igbimọ alaṣẹ fasiti UNILAG ti yẹ aga mọ Ọjọgbọn Ogundipe nidi.

Ṣugbọn ninu esi rẹ si atẹjade ọhun, Ọjọgbọn Ogundipe sọ pe Ọgbẹni Azeez lo mọ ibi ti o ti ri iroyin to n gbe kaakiri.

O ni gidigba loun duro ati wi pe mimi kan lo le mi oun.

Ninu atẹjade ti Ọjọgbọn Ogundipe fi ọwọ si fun ra rẹ, o ṣalaye pe ki gbogbo awọn ti ọrọ fasiti UNILAG kan kọ eti ikun si iroyin ofege ọhun.

Ọjọgbọn Ogundipe fikun ọrọ rẹ pe alakalẹ wa lati yọ giwa fasiti nipo eleyi ti igbimọ alaṣẹ UNILAG ko tẹle to ba tiẹ jẹ pe lootọ ni wọn ti yọ ọ nipo.

Other

Oríṣun àwòrán, Other

Ìgbìmọ̀ aláṣẹ UNILAG yọ gíwá iléewé náà nípò

Igbimọ alaṣẹ fasiti ijọba apapọ to wa niluu Eko, UNILAG ti da giwa fasiti naa, Ọjọgbọn Olawatoyin Ogundipe duro lẹnu iṣẹ.

Igbimọ naa kede idaduro Ọjọgbọn Ogundipe nibi ipade wọn to waye ọfiisi igbimọ to n mojuto ọrọ awọn fasiti ni Naijiria, NUC niluu Abuja.

Ọmọ igbimọ meje dibo pe ki wọn yọ Ọjọgbọn Ogundipe nipo, nigba tawọn mẹrin dibo pe ki wọn fi i silẹ.

Ọmọ igbimọ daba ni tirẹ pe ki wọn ja ewe gbele ẹ fun Ọjọgbọn naa fun igba diẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe fasiti naa, Ọgbẹni Oladejo Azeez fi sita, ṣalaye pe igbimọ naa yọ ọ nipo lori ẹsun aṣẹmaṣe ati iṣowo ileewe kumọkumọ.

Oluwatoyin Ogundipe

Oríṣun àwòrán, Facebook/Oluwatoyin Ogundipe

O ni ẹsun aṣilo ọfiisi ni ẹsun mii ti wọn fi kan Ọjọgbọn Ogundipe eyi to jẹ ki wọn da a duro.

Atẹjade fasiti UNILAG

Oríṣun àwòrán, Other

Ọgbẹni Azeez ṣalaye siwaju sii pe igbesẹ igbimọ alaṣẹ naa wa ni ibamu pẹlu ofin to gbe e kalẹ.

Alaga igbimọ naa, Ọmọwe Wale Babalakin lo dari ipade ọhun l'Abuja.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka