UK Recession: Ètò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ́ Gẹ̀ẹ́sì ti dẹnukọlẹ̀ fún ìgbà akọ́kọ́ láti ọdún 2009: wo bí ipa tí yóò ní lórí rẹ̀

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ aláwọ̀ dúdú nílẹ̀ gẹ́ẹ̀sì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Fún ìgbà àkọ́kọ́ ní ǹkan bi ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn orílẹ̀-èdè United Kingdom ti kédé pé ètò ọ̀rọ̀ ajé rẹ̀ ti dẹnukọlẹ̀.

Èyí sì túmọ̀ sí onírúurú ǹkan to lágbára fun ọ̀pọ̀ èniyàn nílé àti nílẹ̀ òkèèrè.

Ètò ọ̀rọ̀ ajé náà ti ti dẹnukọlẹ̀ láti ìdá ogún o lé díẹ̀ yàtọ̀ sí bí ó ṣe wà ni oṣù mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ọdún yìí.

Owó ti àwọn ẹbi máa ń lò láti ràn ǹka sínú ilé kò tó mọ́, nígbà tí ilé ìtajà àti àwọn ilé iṣẹ́ to ń ṣe ǹkan èlò gbogbo kò fi bẹẹ ṣe ọ̀ps mọ́ nígbà ti ọ̀ps sì n gbé ilé iṣẹ́ wọ́n tà.

Ilé iṣẹ́ tó ń mójú to iye ènìyàn to wà nínú ìlú sàlàyé pé àwọn ilé-ìwé, ilé ìtajà, àti gbogbo ilé iṣk tó ti wà ní títì pa lásìkò Covid-19 náà ba ńkan jẹ́.

Èyí ló ti ilẹ̀ gẹ̀ẹ́sì sí ipò ti wan wà yìí ńitori kò fi kátàkára fún oṣù mẹ́fa láti ọdún 2009.

Ètò ọ̀rọ̀ ajé ilẹ́ gẹ̀ẹ́sì ti dẹnukọlẹ̀ fún ìgbà akọ́kọ́ láti ọdún 2009
Àkọlé àwòrán, Alàyé lórí àwọn ènìyàn to ti pàdánù iṣk wọ́n láàrin oṣù kẹrin si oṣù kẹfa jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà okòólénígba ènìyàn.

Ọ̀nà wo ni ìdẹnukọlẹ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé UK yìí yóò gbà láti kan ìwọ náà

Iṣẹ́/Owó

Ọ̀pọ̀ ènìyàn le pàdánù iṣẹ́ wọ́n, tàbi kí wan tni kò ní sí ìgbéga tàbi afówókún owó oṣù wọ́n kò ni wayé.

Ó tún ṣe é ṣe kí (Kódà àdínkù tún lè báa).

Fún àwọn ẹ̀yà aláwọ̀ dúdú tó ni ẹbi ni ilẹ̀ òkèèrè, èyí le jẹ́ ìpalára fún wọ́n nítorí, bi iná bá ń jóni, tó ń jó ọmọ ẹni... nítorí náà an yóò kọ́kọ́ gbọ́ ti ará ìlú kí wọ́n tó r'aàyé ti àwọn alejò.

Àkọlé fídíò, Sextuplet: Àdúrà Ìbùkún ló kú lẹ́yìn ọmọ mẹ́fà yìí- Ifeoma Thelma àti Onyemaechi Chiaka

Etò Ẹkọ / Awọn to ti kàwé tán

Àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ ti wọ́n fẹ̀ lọ sí ilẹ̀ òkèrè láti kàwé, kò ni sí owó ìrànwọ́ tàbi ètò ẹkọ ọfẹ́ nílùú òkèrè bi ti tẹ́lẹ̀ mọ́

Owó ilé-ìwé le wọ́n síi

Nítolrí ìdí èyí, ọ̀ps àwọn tó ti kàwé gboyè le ri pé yóò nira fún wọ́n ki wọ́n tó rí iṣẹ́ àkọkọ́ wọ́n.

Fún àwọn to sì fẹ wọ́ ilé Ẹ̀kọ́ gíga, ìdẹnukọlẹ ọ̀rọ̀ ajé yìí le jẹ́ ki wọ́n sún ìwọlé síwájú, nítori kò si owó ti wọ́n yóò fi ṣètò náà.

Iwé ìrìnà

Oríṣun àwòrán, Nigeria Immigration Service

Fisà

Kò sí ẹni tó yé, iye ti owó ìwé ìrìnnà yóò jẹ́ yálà kí o wọ́n síi tàbi kó tún wálẹ̀. Ó sì tún ṣe é ṣe kí o nira láti ri ìwé ìrìnà lọ si ilẹ Gẹ̀ẹ́sì.

Jíjogún ìṣẹ́

Àwọn onímọ̀ ti sàlàyé pé, iṣẹ́ àti òṣì ti ìdẹnukọlẹ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé yìí yóò dá fún ẹbi míràn, ìran wọ́n kò ni lè san tán.

Ìdí ni pé, nígbà míràn, ó máa n nira láti bori àsìkò yìí tí ìṣk náà yóò tún ran àwọn ọmọ.

Ohun ìní

Àwọn ǹkan ìní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yóò wálẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló nílò owó, èyí yóò si jẹ́ ànfàni fún àwọn to ṣe idókodòwò ilẹ̀ okeèrè, to fi mọ́ àwọn to wá láti ilẹ̀ Afíríkà.

Àwọ onímọ̀ fi kún un pé, àwọn tó bá ni ié tàbi ill lé maa tàa. nítorí náà bákan méjì lọ́rọ̀ ọ̀hún.

Grey line wey dey

Ọ̀rọ̀ ajẹe tó dẹnukọlẹ̀ lọ́dún 2009 kíló ṣẹlẹ̀ nigba naa?

Ìjàmbá tó ń bá ètò ọ̀rọ̀ aje to dẹnukọlẹ̀ rìn kò rí bákan náà fún gbogbo ènìyàn.

Èyí túmọ̀ sí pé, bí yóò ṣe kan olúkúlùkù kìí ṣe bákan náà, ó ṣe é ṣe kí ẹlòmíràn má tilẹ̀ mọ̀ ọ́ lára rárá.

Bí àpẹ̀rẹ ni ọdún 2009, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ni ilé ara wọ́n, ti wọ́n si tún ni iṣẹ́ lọ́wọ́ pada gbádùn nígbà ti ǹkan pada bọ̀ sípò.

Bákan náà ni ni àwọn tó ń sanwó èlé lórí ilé, ìyẹ náà dínkù dáradára, èyí si fún àwọn ènìyàn ni ànfàni láti lówó lọ́wọ́ ti wọ́n le ná.

Sùgbọ́n àwọn tọ jẹ́ pé, olá ìjọba ni wọ́n fi n mí, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, ìdẹnukọlẹ̀ ètò ọ̀rọ̀ ajé pa wọ́n lára gidi ni.

Àkọlé fídíò, Alaafin: Olori Aanu Adeyemi ṣàlàyé ìdí tó ṣe gẹ́ Oba Lamidi Adeyemi ti ìlú Oyo