Ondo Election: Akeredolu f'ògún ikọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn Ondo gbárí fún ìdìbò tó ń bọ̀

"A o ni faaye gba lilo janduku tabi iwa ọdaran lasiko idibo to n bọ lọna..."
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu (SAN) ti fi da awọn eniyan ipinlẹ Ondo loju wipe ko ni si aaye fun oniwa ọdaran kankan lati da omi alafia ti wọn n gbadun nipinlẹ naa ru.
Akeredolu n sọ eyi gẹgẹ bi ikọ alaabo ẹya Yoruba nipinlẹ naa Amotekun ṣe bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹwu.
Gomina tẹnu mọ ọ pe pẹlu ajọṣepọ to dan mọran laarin awọn adari ikọ alaabo to ku pẹlu ti Amotekun, aridaju wa pe ọwọ yoo bẹrẹ si ni tẹ awọn ọdaran koda, ṣaaju ki wọn to pinṣẹ fun awọn ikọ naa.
Arakunrin Akeredolu kede eyi nibi ayẹyẹ yiyan bii ologun lati bẹrẹ iṣẹ eyi ti ikọ Amotekun ṣe ni ipinlẹ naa to waye ni gbagede Fawehinmi Freedom Arcade lagbegbe Igbatoro, Akure, olu ilu naa.

Gomina naa mu wa si iranti pe ọpọlọpọ n ro pe tori ati wọle gomina lẹẹkan sii lo n san ọna nigba ti o darapọ mọ awọn gomina ti wọn jọ wa nibi ifilọlẹ ikọ Amotekun nilu Ibadan ninu oṣu kinni ọdun yii.
"Mo si sọ fun wọn nigba naa lọhun pe ifẹ inu mi ko ṣe pataki to ipenija aabo tawọn eeyan wa n koju to bẹẹ to di igba kan ti ẹru n ba awọn eeyan lati rinrinajo".
"Ni ti Amotekun, a ti fẹnuko wi pe ohun to ba gba la o fun un a o si ni jẹ ki ẹnikẹni ti wa gbọọn gbọọn".
Akeredolu ṣalaye pe ọrọ bibẹrẹ iṣẹ awọn Amotekun yii ti di rangbọndọn lẹnu awọn eeyan torinaa awọn gbudọ gbe igbesẹ ati wipe "gẹgẹ bii Yoruba, a o ki n ṣe ọmọ lọle lọ gb'esi wa, nigba ti awọn aṣaaju wa
o tilẹ ṣe bẹẹ loju ọta".
Ondo Election: Akeredolu f'ògún ikọ̀ Amotekun Ondo gbárí fún ìdìbò tó ń bọ̀.
O ni ikọ Amotekun ti ni atilẹyin ofin bayii bẹẹ si ni ko di iṣẹ awọn oṣiṣẹ alaabo to ku lọwọ bikoṣe ko tun fi kun akitiyan riran iṣẹ wọn lọwọ fun aabo ilu eyi ti yoo tilẹ tun le fun awọn oludokoowo ilẹ okeere lalafia ati wa dokoowo.

Bakan naa, niwaju awọn lọba lọba ipinlẹ Ondo nikalẹ, atawọn lọga lọga ikọ alaabo, gomina Akeredolu fi da awọn eeyan loju pe idibo to n bọ lọna yoo waye ni irọwọrọsẹ ati pe ipinlẹ naa ko ni faaye gba lilo janduku tabi iwa ọdaran lasiko idibo.
- Ọkọ Risikat ní ojú búlúù tí ìyàwó òun ní gan an lòun ṣe fẹ́ ẹ
- Ọwọ́ ikọ̀ aláàbò STF tẹ afurasí mẹ́jọ tó lọ́wọ́ nínú ìpànìyàn lemọ́-lemọ́ọ Gúúsù Kaduna
- Diezani gan an ní Hushmummy tó ń bú àwọn Yahoo boys- Àwọn Ọmọ Naijiria lórí Twitter
- Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ọ̀rọ̀ ibojì òkú, àti àwọn ipò òṣèlú mìíràn tó jẹ́ kàyééfì ní Nàìjíríà
- Asojú ìjọba orílẹ̀-èdè Lebanon ti kọ̀wé fipò silẹ̀ nítorí ìbágbàmù tó gbẹ̀mi ènìyàn 200

Amotekun: Ẹ lọ gba fọ́ọ̀mù ìgbanisíṣẹ́ ikọ̀ Amotekun - Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo
Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe awọn eeyan to ba nifẹ lati darapọ mọ ikọ aalabo Amotekun ipinlẹ naa le lọ gba fọọmu.
Agbẹnusọ gomina ipinlẹ ọhun, Segun Ajiboye to fi idi ọrọ naa mulẹ fun BBC sọ pe ọfẹ ni fọọmu ọhun.
Adari ikọ naa ni ipinlẹ Ondo, Adetunji Olu-Adeleye ni wọn bẹrẹ igbesẹ lati maa gba awọn eeyan naa siṣẹ lẹyin ti gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu fọwọ si agbekalẹ ikọ alabo ọhun.
Olu-Adeleye kilọ fun awọn to ba nifẹ si iṣẹ naa lati sọ otitọ nipa ara wọn ninu fọọmu ọhun.
O fi kun pe awọn to jẹ ẹni ọdun mejidinlogunn si aadọrin ọdun nikan lo lọ gba fọọmu ọhun.
Lẹyin naa lo sọ pe awọn eeyan le lọ gba fọọmu naa lojo opo Amotekun to wa ni www.ondoamotekun.org.ng.
Igbakejì ààrẹ ṣèpàdé pẹ̀lu àwọn gómìnà ilẹ̀ Yorùbá

Oríṣun àwòrán, @toluogunlesi
Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ati awọn Gomina ipinlẹ lẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, to fi mọ agbẹjọro agba ati ọga agba ọlọpa ni Naijiria, ti fẹnuko lori ọrọ idasilẹ ikọ Amotekun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ó kéré tán ọkùnrin 15 ló ń bámi lòpọ̀ lójúmọ́, mo sì ti ní egbò lójú ara - Adeola tí wọn fi sòwò ẹrú
- Òfò lásán, tí kò ní ẹ̀rí ní àbọ̀ ìwádìí àjọ Transparency lórí ìwà ìbàjẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
- Ìbọn kọ́ ni wọn fi pa èèkàn ẹgbẹ́ APC n‘Ibadan, ọ̀bẹ ni wọ́n fi gé iṣan ọrùn, ọrùn ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ - Ọlọ́pàá
- Mo dúpẹ́ pé Ọlọ́run dá mi láre lórí ikú Sugar, tí adájọ́ sì tú mi silẹ̀ - Akinmoyede
- Ìṣọ̀rí Amotekun ta pè ní ‘Irúnmọlẹ̀’ ní yóò máa gun ọ̀kadà kiri láti pèsè ààbò - Àjọ Dawn
Ohun ta ri gbọ ree lati ẹnu agbẹnusọ fun igbakeji aarẹ Naijiria, Laolu Akande to fi ọrọ yi soju opo Twitter rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Bakan naa ni ijọba apapọ fi iroyin lede loju opo Twitter rẹ́ nipa abọ ipade wọn ọhun nibiti wọn ti fẹnuko pe ki awọn gomina to wa lẹkun iwọ oorun Naijiria, lọ gbe ofin kalẹ nipinlẹ koowa wọn lati se atilẹyin fun eto Amotekun labẹ ofin.

Wọn ni ilana agbekalẹ eto Amotekun gbọdọ wa nibamu pẹlu ilana sise isẹ ọlọpa agbegbe tijọba apapọ gbekalẹ nitori ojuse tolori tẹlẹmu ni lati ri si eto aabo orilẹede yii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Ìṣọ̀rí Amotekun táa pè ní 'Irúnmọlẹ̀' ní yóò máa gun ọ̀kadà kiri láti pèsè ààbò - Àjọ Dawn
Olori ajọ to n se akoso ikọ alaabo Amotekun fun ẹkun iwọ oorun guusu Naijiria, ti wọn n pe ni DAWN Commission ti salaye pe, kii se pe wọn gbẹsẹle isọwọsisẹ ikọ Amotekun lẹyin ti wọn sefilọlẹ rẹ tan, lo se lọ jai diẹ fawọn araalu lati kofiri rẹ nita gbangba.
Adetayo Adeleke-Adedoyin, ninu ifọrọwanilẹnu latọdọ awọn akọroyin salaye pe, ko si ẹnikẹni to fofin de tabi dawọ isẹ Amotekun duro, amọ ipalẹmọ fun ilana ti wọn yoo gba sisẹ lo mu ki idaduro ranpẹ wa, ki ikọ naa to bọ sita lati sisẹ.
Adedoyin tun fikun pe, ipinlẹ kọọkan ni yoo gba awọn ọmọ ikọ alaabo Amotekun sisẹ, kii se ajọ Dawn rara, amọ ajọ naa ti se agbekalẹ ilana tawọn gomina yoo tọ, nidi gbigba awọn eeyan ti yoo sisẹ bii ikọ Amotekun si ẹnu isẹ.

"Ipinlẹ kọọkan ni yoo gba awọn osisẹ Amotekun tiẹ si ẹnu isẹ lati ẹsẹkuku to wa lagbegbe koowa wọn, iyẹn awọn eeyan to kaato ninu ilana ibilẹ lati gbe eto aabo larugẹ pẹlu awọn ileesẹ agbofinro, laipẹ yii si ni ilana isọwọsisẹ Amotekun yoo bẹrẹ, lẹyin ta ba yọrọ rẹ tan, ti ikọ Amotekun yoo si bẹrẹ isẹ ni pẹrẹu."
Nigba to n sọrọ lori ipese owona fun ikọ Amotekun, Adedoyin ni ipinlẹ kọọkan lo ni apo asunwọn owo ti wọn ya sọtọ fun eto aabo, taa mọ si Security Fund, ipinlẹ kọọkan ti ikọ Amotekun ba si wa ni yoo maa pese owona wọn, kii si se ipese owona alajumọse rara.

"Ipese owona fun ikọ Amotekun lee gbe pẹẹli nipinlẹ kan ju ọkan lọ tabi ko dinkun si ara wọn, eyi to wa lọwọ bi ipinlẹ kọọkan se lowura si."
"Fun apẹrẹ, ipinlẹ Eko lee gbe owo kalẹ fun ikọ Amotekun nipinlẹ rẹ ju ipinlẹ Ọsun lọ, sugbọn gbedeke yoo wa lori iye to kere julọ ti ipinlẹ kọọkan gbọdọ gbe kalẹ. Bakan naa la tun n boju wo ipese eto adojutofo ati awọn nkan mii to jẹ mọọ, ti ọpọ osisẹ ikọ Amotekun si jẹ osisẹ to n sisẹ idabọ."

Adedoyin fikun pe " A ni awọn isọri Amotekun ta pe ni 'Irunmọlẹ', ti wọn yoo maa gun ọkada kiri lati agbegbe kan si omiran nibi ti ọkọ ayọkẹlẹ ko lee de, eyi ti yoo mu ki isẹ ipese abbo jẹ alatagba lati adugbo kan si omiran. Idi ni pe gbogbo wa ko lee maa sisẹ ọpọlọ ni asiko kannaa."
Olori ikọ Dawn commission fikun pe, wọn yoo se idanilẹkọ fun awọn osisẹ Amọtẹkun, paapa ọna ti wọn yoo tete maa gba fura ati lori eto ibaraẹnisọrọ, isẹ ọtẹlẹmuyẹ, sise idamọ awọn agbegbe ti iwa ọdaran sodo si julọ ati itati were si iwa ọdaran.
O fikun pe ikọ Amotekun ko ni gbe ibọn rara, isẹ gboogi ti wọn yoo maa se ni ifimufinlẹ, isẹ ọtẹlẹmuyẹ ati kiko iroyin iwa ọdaran jọ ati fifi iwa ọdaran to awọn agbofinro leti, to si wa fọwọ gbaya pe awọn ikọ Amotekun yii ko ni maa jẹ abẹsinkawọ fun awọn gomina ipinlẹ rara.
Awọn gomina awọn ipinlẹ to wa ni Iwọ-oorun Naijiria yoo ṣe ipade pọ pẹlu ileeṣẹ aarẹ loni, Ọjọbọ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/SEyi Makinde
Ipade naa gẹgẹ bi agbẹnusọ fun olori awọn gomina ilẹ Yoruba, Rotimi Akeredolu to tun jẹ gomina ipinlẹ Ondo, Smart Oyeyemi, yoo jẹ ijiroro lori ọrọ eto aabo Amọtẹkun ti awọn gomina naa gbe dide fun abo ẹkun Iwọ-oorun Naijiria.
Oriṣiriṣi awuye-wuye lo ti waye lori igbesẹ naa lati igba ti wọn ti ṣe ifilọlẹ rẹ, paapa lati ẹnu agbẹjọro agba Naijiria, to tun jẹ Minisita fun eto idajọ, Abubakar Malami to sọ pe idasilẹ rẹ ko ba ofin mu.
Bakan naa ni awọn ẹgbẹ bii awọn Fulani daran-daran naa ti sọrọ tako eto naa.

Ọ̀rọ̀ Tinubu kò ní ohun àrígbámú kankan
Ni ti asiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, o ti p ti awọn eeyan ti n duro de ọrọ ti yoo sọ ṣugbọn ko tete fọhun ayafi to di ọjọ kejilelogun oṣu kinni.
Ọ̀rọ́ náà ṣe ọtọọtọ láàrin àwọn Gomina Guusu- ìwọ-òòrùn Nàìjíríà àti ẹgbẹ to n soju ọmọ yoruba, Afẹnifẹre lórí àríwísí àsáju ẹgbẹ́ APC, Bola Ahme Tinubu,
lẹyin to fi èrò tirẹ̀ han lórí ìdásilẹ̀ ètò àabo Amotẹkun to ti n dá gbọn-mi-si i-omi-o-to silẹ̀ láàrin ìjọba apapọ àti ìjọba ìpinlẹ̀.
Bí àwọn Gomina ṣe ń gbé sàdánkata kare fun Asiwaju Ahmed Tinubu fun àwọn kókó ọ̀rọ̀ to fi síta àti pé àwọn yóò ṣe àmúlò àwọn ìmọràn to wà níbẹ̀, ẹgbẹ́ Afẹnifẹre ni ọ̀rọ̀ ti Asiwaju sọ ko ni ohun arígbámu kankan.
Lẹ́yìn bi ọ̀ṣẹ̀ mẹ́ta ti ọ̀pọ̀ ènìyàn ti n reti ki Asiwaju ẹgbẹ́ APC fèsi lóri ìdásílẹ̀ ètò àbò Amọtẹkun, ọjọru ọsẹ̀ yìí lo ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ààyè tó tò sí lórí ọ̀rọ̀ náà.
Sùgbọ́n Afẹnifẹre ni ẹgbẹ́ ẹnu méjèèjì ni Tinubu fi ń sọ̀rọ̀ àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ko ni arígbámu kankan nínú.

Ọlóyè ẹgbẹ́ Afẹnifere Ayo Adebanjo àti Sẹnatọ Femi okunronmu nínú iwé ìròyin Punch lọ́jọ Aiku ti kswé pe ki Tinubu sọ àyè to tò si lórí ọ̀rọ̀ Amọtẹkun lẹ́yin ti àgbẹjẹ́rò àgbà Naijiria ti sọ pé ìdásílẹ̀ rẹ̀ kò bá òfin mu.
Nínú ọ̀rọ̀ Tinubu, ó bẹnu àtẹ lu bi àwọn Gomina àti agbẹjọrò àgbà ṣe jẹ ki ọ̀rọ̀ náà dà.
Ṣùgbọ́n Afẹnifẹre ni ẹgbẹ́ ẹnu méjèèjì ni Tinubu fi ń sọ̀rọ̀ àti pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ko ni arígbámu kankan nínú.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ agbẹnusọ ẹgbẹ́ náà Yinka Odumakin nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwo rẹ̀ pẹlu ilé iṣẹ́ ìròyìn Punch ni kì ba sàn ki Tinubu pa ẹnu rẹ mọ" kìí ṣe àsìkò yìí lo yẹ ki eniyan maa fi orí ahọ́n sọ̀rọ̀ kíní ìdí? Ṣe ò ń bẹrù Buhari ní?''
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ Ayo Adebanjọ ni Tinubu kan dá si ọ̀rọ̀ náà nitori èròngbà rẹ̀ láti dupo ààrẹ ọdún 2023 ni.















