Human Trafficking: Wọ́n fun mi ni omí ìmùlẹ̀ kí wọ́n to sọ fun mi pé iṣẹ́ aṣẹwo ni mo wá ṣe- Adeola

Oríṣun àwòrán, others
Arabinrin Adeola,(Kii se orukọ abisọ rẹ gangan) ti sọ itan bi wọn ṣe ta oun si oko ẹru fun ọọdunrun owo ilẹ okeere Cefas ti ilẹ Côte d'Ivoire.
Lasiko to n kopa lori akanse eto BBC Yoruba, Adeola ni iṣẹ aserunlọsọ ni oun kọ nilu Abuja, ki wọn to sọ fun oun pe, awọn eniyan kan wa to lee gbe oun lọ silu oyinbo fun bii oṣu mẹta, lati le ri owo kojọ fun idasilẹ isẹ tara oun.
Akanse eto naa lori Facebook BBC Yoruba ree:
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Arabinrin naa gbera lati ilu Abuja wa si ilu Eko ni ibi ti wọn ti fi aworan awọn ọmọ Naijiria ti wọn n ṣiṣẹ pẹlu oyinbo lọhun han, eyi to mu ki ori rẹ wu lati tẹle wọn lọ silẹ Yuroopu.
- Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump
- Ìṣọ̀rí Amotekun táa pè ní ‘Irúnmọlẹ̀’ ní yóò máa gun ọ̀kadà kiri láti pèsè ààbò - Àjọ Dawn
- Ṣé lílo ìbòjú tàbí ìbòmú lèé dènà kíkó àjàkálẹ̀ àrùn?
- Yaba Left: Àṣírí tú! #7000 sí #10000 ni owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún bẹẹdi ní ilé àwọn aláìsàn ọpọlọ
Adeola ko ni iwe irinna kankan, amọ o ni awọn to mu ohun lọ sọ wi pe, Côte d'Ivoire ni wọn yoo ti se iwe irinna ọhun fun oun, ti wọ̀n si sekilọ fun pe ko gbọdọ fi ọrọ naa to ẹnikẹni leti, titi ti yoo fi lọ.

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Ọmọbinrin ti wọn fi ṣe owo ẹru naa kuro ni ile ni Osu Kẹwa ni ọdun 2017, ti oju rẹ si ri to loju ọna ko to de Cote D‘ivoire, ti ẹni to mu lọ si faa le obinrin kan lọwọ nibẹ.
Nigba ti wọn de Côte d'Ivoire, ni wọn mu Adeola lọ si ile obinrin ti o sọ wi pe ki oun bura pe oun ko ni salọ, to si gbe omi silẹ́ lati bura lẹyin to kede pe isẹ asẹwo ni oun yoo maa se fun oun.
Arabinrin ọmọ Côte d'Ivoire sọ fun Adeola pe ninu iṣẹ naa ni ẹni to ra a lẹru yoo fun un ni miliọnu meji Cefas, amọ o kọkọ kọ jalẹ, ko to di wi pe o gba lẹyin ti wọn ran an leti pe wọn ti mulẹ.
"Ọkunrin mẹta ni wọn kọkọ fi bẹrẹ owo naabi fun mi, ti maa si lọ kowo fun ọga lẹyin ti mo ba ti ṣiṣẹ tan. O si kere tan ọkunrin mẹẹdogun lo n ba mi lopọ ni ojoojumọ."

Oríṣun àwòrán, AFP
Adeola ni "ẹyin ni wọn fi n gba ibale obinrin ti wọn ba fẹ fi ṣowo nabi, a ko si ri ounjẹ asaara loore kankan jẹ nibẹ. Koda, ori ẹni ni wọn ko awa obinrin mẹrin si ninu yara kan, ti awọn ọkun yoo si wa lati ba wa lopọ lasiko kannaa"
Lẹyin ọpọlọpọ iya ati iṣẹ, ọga Adeola le e kuro pe o ti san owo oun tan, ti Adeola si di ẹni ti n sun ita, ki obinrin kan to jẹ ọmọ Naijiria to seranwọ lati gbaa sile, nibẹ si lo ti foju han si pe o ti ko aisan to nii se pẹlu nini egbo loju ara.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ Alaanu kan ti Arabinrin Motilola Adekunle n dari rẹ ni Adeola pade ni ori ẹrọ ikansiraẹni Instagram nibi ti o ti ke sita, ti wọn si seranwọ fun lati pada wa si orilẹede Naijiria ni Osu Kejila, Osu 2019.
Adeola wa n rọ awọn obi, alagbatọ ati ijọba lati dena iwa fifi ọmọ Naijiria sowo ẹru loke okun nitori ọpọ ewu to rọ mọ.














