Yaba Left: Awon àṣírí ìkọkọ to jẹyọ nínú ìwádii

Oríṣun àwòrán, Cable
Fisayo Soyombo, tún ti ṣe àbẹwò si ajọ ijọba míràn láti wádiìí àwọn kudiẹ̀kudíẹ̀ to n ṣẹ̀lẹ̀ níbẹ̀.
Tí ẹ kò ba gbàgbé, akọròyìn yìí náà lo ṣe àbẹ̀wò si ọgbà ẹwọn Ikoyi àti àgọ ọlọpàá to díbọ́n bíi ọ̀daràn láti tú àṣiri àwọn ìwà ìbàjẹ́ to n ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.
Ní sáà yìí, ilé ìwòsàn to wà fún ìtọ́jú àwọn alárùn ọpọlọ ní ìpińlẹ̀ Eko Federal Neuropsychiatric Hospital ti gbogbo ènìyàn mọ si YabaLeft lo ṣe àbẹ̀wò si láti le mọ ǹkan ti ó ń sẹ̀lẹ̀ níbẹ̀.
- Oxford English Dictionary: Ọ̀rọ̀ 28 túntun ti wọ́n fi kún-un lọ́dun 2020
- Amotekun: Ọ̀rọ̀ Tinubu kò ní ohun àrígbámú kankan- Afẹ́nifẹ́re
- Tinubu kò ṣékú, kò ṣé ẹyẹ, o n dibọn ní lórí ọ̀rọ̀ ikọ̀ Amotekun - Fani Kayode
- Mọ̀ síi nípa ǹkan tí o lè ṣe láti dènà ibà Lassa
- Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump
Soyombo to ti kọ́kọ gba ẹkọ nípa bi ẹni to ni ààrun ọpọlọ nípasẹ òògun olóró ko to wọ ibẹ lọ ṣàlàye pé, ogun ki alaisan to ri àaye bẹẹdi ni ilé iwosan náà, gẹ́gẹ́ bi o ṣe ṣàlaye, lẹyin ọ̀sẹ̀ mẹta to ti lọ ni wọn to ri ààye bẹẹdi fún un ti wọ́n si san ẹgbẹ̀run meje naira gẹ́gẹ́ bi owo àbẹtẹlẹ ki o to ri ààye lati gba bẹẹdi.
Ilé ìwòsàn ọhun ti wọ́n da silẹ̀ ni inú oṣù kẹwàá ọdun 1907 láti maa ko ènìyàn mejìdinláàdọta si ti di èyi ti wọ́n ń ko ènìyàn ojílelẹẹdẹgbẹtà o din máàrun (535) lọdun 2020.

O tu aṣiri pe ẹba àti ọbẹ̀ ẹgusi olomi làrò ni wọn n fún àwọn ènìyàn to wà níbẹ̀ lẹ́yìn ti wọn gba ẹgbẹ̀run lọna ọgọfa naira gẹ́gẹ bi owo òunjẹ ati ogun.
Oṣẹ kan ṣááju ìgba ti Soyombo de ibẹ ni o ni wọn fi ofin de ki àwọn ẹbi maa gbe ounjẹ wá lẹyin ti ẹni kan gbe oogun oloro (igbo) wọle nipa lilo oṣìṣẹ́ Dundu nation.
Gẹ́gẹ́ bi ṣẹṣẹ de Soyombo ni wọ́n gba ẹgbẹ̀run lọ́na ogun náira fun aṣọ oorun, miliki, tea, towẹẹli àti awon nkan miran ti apapọ owo rẹ̀ ko le ju ẹgbẹrun mẹẹdogun naira lọ.

Oríṣun àwòrán, cable
Ní ti Ekúté ńkọ? Soyombo ròyìn o fi ti, o ni ǹkan ti ẹni kan kò ba ti fẹ́ ki ekúte fẹnu kan ki olúwà rẹ o ma wulẹ̀ gbe e silẹ̀.
O ní àwọn ekute náa le wọ́ ènìyàn fun ara rẹ̀ lọ, síbẹ̀ ko si ètò kankan láti mu atuṣe wa, nitori gbogbo igbo ayika ibẹ lo kún fọ́fọ́.

Oríṣun àwòrán, @thecableng













