Birth tourism: Ẹ̀yin obìnrin tẹ́ẹ fẹ́ wá bímọ ní America, ọ̀nà ti tì pa látònì! - Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilẹ Amẹrika ti ṣipaya awọn ofin mii lati bẹgi dina irinajo awọn obinrin aboyun lọ si Amẹrika lati lọ bimọ.
Loni ọjọ ẹti ọjọ kẹrinlelogun ni igbesẹ yii yoo gberasọ yoo si jẹ ohun ti yoo mu opin wa si ohun ti ọpọ eeyan mọ si "birth tourism" iyẹn gbigba iwe aṣẹ irina ati lọ bimọ
Labẹ ofin yii, awọn aboyun to fẹ gba iwe aṣẹ irina olubẹwo si US yoo ni lati sọ idi pataki ti wọn fi fẹ lọ yatọ si pe wn fẹ lọ bimọ sori ilẹ Amẹrika.
Eyi ọpọ gbagbọ pe wọn maa n ṣe e ki ọmọ ti wọn bi sọhun lee di ọmọ ilẹ Amẹrika nipa ibi nikan eyi ti ofin fi aye gba tẹlẹ bẹẹ si ni aarẹ Donald Trump bu ẹnu atẹ lu eyi.
Iṣejọba aarẹ Trump ni aato irina tuntun yii ṣe pataki fun abo ati eto ilera ilẹ Amẹrika.
Fun idi eyi aarẹ Trump ti fẹ bẹgi dina irinajo wọ ilẹ Amẹrika, bakan naa o ti pe fun atunṣe iwe ofin eyi to n sọ ni di ọmọ ilu Amẹrika fun gbogbo ọmọ ti wọn ba bi si Amẹrika.
Ki lo wa ninu ofin tuntun naa?
- Ofin tuntun yii kan awọn arinrinajo to fẹ gba iwe aṣẹ irina 'B' eleyi ti wọn maa n fun awọn awọn arinrinajo.
- Yoo faye gba awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ to n ri si irina lati kọ iwe irina awọn eeyan to jẹ wi pe idi ti wọn fi n lọ ni lati lọ bimọ.
- Lakotan ofin naa yoo ṣeranwọ fun abo orilẹede yoo si ri si igbesẹ ọdaran kankan to ba su yọ latari ẹka to n gba awọn eeyan laye lati lọ bimọ ni Amẹrika.
Ofin naa fi kun aato to ti gbigba awọn eeyan laye lati lọ bimọ lẹyin pe yoo boju to iwa ọdaran labẹle tabi tayọ orilẹede.
Bakan naa o ṣe afikun ofin lori awọn to fẹ lati lọ si US fun ilera wọn.
Ọmọ melo ni awọn ara orilẹede mii rinrinajo lọ bi si ilẹ Amẹrika?
Ko si akọsilẹ ọlọdọọdun fun iye ọmọ ti awọn ajoji si ilẹ Amẹrika bi ṣugbọn oniruuru ajọ lo ni iṣiro tiwọn.
Lọdun 2017 nikan, nkan bii ẹgbẹrun mẹwaa ni ọmọ ti awọn ajoji bi si Amẹrika bẹẹ si ni bi ajọ ilẹ Amẹrika to n ri si idena aisan ni lati ẹgbẹrun mẹjọ din nigba ti ọdun 2007 lo ti goke si ẹgbẹrun mẹwaa.
Ni lọọlọ yii, alaboyun lee wọ ilẹ Amẹrika koda titi di ọjọ ibimọ gẹgẹ bi ajọ aṣọbode ilẹ Amẹrika ṣe sọ ọ ṣugbọn irina ẹni to ti fẹẹ di abiyamọ kan le ri idiwọ ni bi wọn ba ri idi pe o ṣi fẹ duro si Amẹrika kọja iye akoko ti wọn fun un lori iwe aṣẹ irina rẹ tabi igbiyanju lati jẹ ki awọn to n san owo ori ni ilẹ Amẹrika ba a san owo ile iwosan to ti bimọ rẹ.













